ÌWÉ ÒWE 3:1-10

ÌWÉ ÒWE 3:1-10 YCE

Ọmọ mi, má ṣe gbàgbé ẹ̀kọ́ tí mo kọ́ ọ, sì pa òfin mi mọ́ lọ́kàn rẹ, nítorí wọn óo fún ọ ní ẹ̀mí gígùn ati ọpọlọpọ alaafia. Má jẹ́ kí ìwà ìṣòótọ́ kí ó fi ọ́ sílẹ̀, so àánú ati òtítọ́ mọ́ ọrùn rẹ, kọ wọ́n sí oókan àyà rẹ. Nípa bẹ́ẹ̀, o óo rí ojurere ati iyì lọ́dọ̀ Ọlọrun ati eniyan. Fi tọkàntọkàn gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, má sì tẹ̀lé ìmọ̀ ara rẹ. Mọ Ọlọrun ní gbogbo ọ̀nà rẹ, yóo sì mú kí ọ̀nà rẹ tọ́. Má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n lójú ara rẹ, bẹ̀rù OLUWA, kí o sì yẹra fún ibi. Tí o bá ṣe bẹ́ẹ̀, yóo jẹ́ ìwòsàn fún ara rẹ, ati ìtura fún egungun rẹ. Fi ohun ìní rẹ bọ̀wọ̀ fún OLUWA pẹlu gbogbo àkọ́so oko rẹ. Nígbà náà ni àká rẹ yóo kún bámúbámú, ìkòkò waini rẹ yóo sì kún àkúnya.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú ÌWÉ ÒWE 3:1-10