Owe 3:1-10
Owe 3:1-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
ỌMỌ mi, máṣe gbagbe ofin mi; si jẹ ki aiya rẹ ki o pa ofin mi mọ́. Nitori ọjọ gigùn, ati ẹmi gigùn, ati alafia ni nwọn o fi kún u fun ọ. Máṣe jẹ ki ãnu ati otitọ ki o fi ọ silẹ: so wọn mọ ọrùn rẹ; kọ wọn si walã aiya rẹ: Bẹ̃ni iwọ o ri ojurere, ati ọ̀na rere loju Ọlọrun ati enia. Fi gbogbo aiya rẹ gbẹkẹle Oluwa; ma si ṣe tẹ̀ si ìmọ ara rẹ. Mọ̀ ọ ni gbogbo ọ̀na rẹ: on o si ma tọ́ ipa-ọna rẹ. Máṣe ọlọgbọ́n li oju ara rẹ; bẹ̀ru Oluwa, ki o si kuro ninu ibi. On o ṣe ilera si idodo rẹ, ati itura si egungun rẹ. Fi ohun-ini rẹ bọ̀wọ fun Oluwa, ati lati inu gbogbo akọbi ibisi-oko rẹ: Bẹ̃ni aká rẹ yio kún fun ọ̀pọlọpọ, ati agbá rẹ yio si kún fun ọti-waini titun.
Owe 3:1-10 Yoruba Bible (YCE)
Ọmọ mi, má ṣe gbàgbé ẹ̀kọ́ tí mo kọ́ ọ, sì pa òfin mi mọ́ lọ́kàn rẹ, nítorí wọn óo fún ọ ní ẹ̀mí gígùn ati ọpọlọpọ alaafia. Má jẹ́ kí ìwà ìṣòótọ́ kí ó fi ọ́ sílẹ̀, so àánú ati òtítọ́ mọ́ ọrùn rẹ, kọ wọ́n sí oókan àyà rẹ. Nípa bẹ́ẹ̀, o óo rí ojurere ati iyì lọ́dọ̀ Ọlọrun ati eniyan. Fi tọkàntọkàn gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, má sì tẹ̀lé ìmọ̀ ara rẹ. Mọ Ọlọrun ní gbogbo ọ̀nà rẹ, yóo sì mú kí ọ̀nà rẹ tọ́. Má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n lójú ara rẹ, bẹ̀rù OLUWA, kí o sì yẹra fún ibi. Tí o bá ṣe bẹ́ẹ̀, yóo jẹ́ ìwòsàn fún ara rẹ, ati ìtura fún egungun rẹ. Fi ohun ìní rẹ bọ̀wọ̀ fún OLUWA pẹlu gbogbo àkọ́so oko rẹ. Nígbà náà ni àká rẹ yóo kún bámúbámú, ìkòkò waini rẹ yóo sì kún àkúnya.
Owe 3:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọmọ mi, má ṣe gbàgbé ẹ̀kọ́ mi. Ṣùgbọ́n pa òfin mi mọ́ sí ọkàn rẹ. Nítorí ọjọ́ gígùn, ẹ̀mí gígùn, àti àlàáfíà, ni wọn yóò fi kùn un fún ọ. Má ṣe jẹ́ kí ìfẹ́ àti òtítọ́ ṣíṣe fi ọ́ sílẹ̀ láéláé so wọ́n mọ́ ọrùn rẹ, kọ wọ́n sí wàláà àyà rẹ. Nígbà náà ni ìwọ yóò rí ojúrere àti orúkọ rere ní ojú Ọlọ́run àti lójú ènìyàn. Gbẹ́kẹ̀lé OLúWA pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ má ṣe sinmi lé òye ara à rẹ; Mọ̀ ọ́n ní gbogbo ọ̀nà rẹ òun yóò sì máa tọ́ ipa ọ̀nà rẹ. Má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n lójú ara à rẹ bẹ̀rù OLúWA kí o sì kórìíra ibi. Èyí yóò mú ìlera fún ara rẹ àti okun fún àwọn egungun rẹ. Fi ọrọ̀ rẹ bọ̀wọ̀ fún OLúWA, pẹ̀lú àkọ́so oko rẹ Nígbà náà ni àká rẹ yóò kún àkúnya àgbá rẹ yóò kún àkúnwọ́sílẹ̀ fún wáìnì tuntun.