Owe 3

3
Ìmọ̀ràn fún Àwọn Ọ̀dọ́
1ỌMỌ mi, máṣe gbagbe ofin mi; si jẹ ki aiya rẹ ki o pa ofin mi mọ́.
2Nitori ọjọ gigùn, ati ẹmi gigùn, ati alafia ni nwọn o fi kún u fun ọ.
3Máṣe jẹ ki ãnu ati otitọ ki o fi ọ silẹ: so wọn mọ ọrùn rẹ; kọ wọn si walã aiya rẹ:
4Bẹ̃ni iwọ o ri ojurere, ati ọ̀na rere loju Ọlọrun ati enia.
5Fi gbogbo aiya rẹ gbẹkẹle Oluwa; ma si ṣe tẹ̀ si ìmọ ara rẹ.
6Mọ̀ ọ ni gbogbo ọ̀na rẹ: on o si ma tọ́ ipa-ọna rẹ.
7Máṣe ọlọgbọ́n li oju ara rẹ; bẹ̀ru Oluwa, ki o si kuro ninu ibi.
8On o ṣe ilera si idodo rẹ, ati itura si egungun rẹ.
9Fi ohun-ini rẹ bọ̀wọ fun Oluwa, ati lati inu gbogbo akọbi ibisi-oko rẹ:
10Bẹ̃ni aká rẹ yio kún fun ọ̀pọlọpọ, ati agbá rẹ yio si kún fun ọti-waini titun.
11Ọmọ mi, máṣe kọ̀ ibawi Oluwa; bẹ̃ni ki agara itọ́ni rẹ̀ ki o máṣe dá ọ:
12Nitoripe ẹniti Oluwa fẹ on ni itọ́, gẹgẹ bi baba ti itọ́ ọmọ ti inu rẹ̀ dùn si.
13Ibukún ni fun ọkunrin na ti o wá ọgbọ́n ri, ati ọkunrin na ti o gbà oye.
14Nitori ti òwo rẹ̀ ju òwo fadaka lọ, ère rẹ̀ si jù ti wura daradara lọ.
15O ṣe iyebiye jù iyùn lọ: ati ohun gbogbo ti iwọ le fẹ, kò si eyi ti a le fi we e.
16Ọjọ gigùn mbẹ li ọwọ ọtún rẹ̀; ati li ọwọ osì rẹ̀, ọrọ̀ ati ọlá.
17Ọ̀na rẹ̀, ọ̀na didùn ni, ati gbogbo ipa-ọ̀na rẹ̀, alafia.
18Igi ìye ni iṣe fun gbogbo awọn ti o dì i mu: ibukún si ni fun ẹniti o dì i mu ṣinṣin.
19Ọgbọ́n li Oluwa fi fi idi aiye sọlẹ, oye li o si fi pese awọn ọrun.
20Nipa ìmọ rẹ̀ ni ibú ya soke, ti awọsanma si nsẹ̀ ìri rẹ̀ silẹ.
21Ọmọ mi, máṣe jẹ ki nwọn ki o lọ kuro li oju rẹ: pa ọgbọ́n ti o yè, ati imoye mọ́:
22Bẹ̃ni nwọn o ma jẹ ìye si ọkàn rẹ, ati ore-ọfẹ si ọrùn rẹ.
23Nigbana ni iwọ o ma rìn ọ̀na rẹ lailewu, iwọ ki yio si fi ẹsẹ̀ kọ.
24Nigbati iwọ dubulẹ, iwọ kì yio bẹ̀ru: nitõtọ, iwọ o dubulẹ, orun rẹ yio si dùn.
25Máṣe fòya ẹ̀ru ojijì, tabi idahoro awọn enia buburu, nigbati o de.
26Nitori Oluwa ni yio ṣe igbẹkẹle rẹ, yio si pa ẹsẹ rẹ mọ́ kuro ninu atimu.
27Máṣe fawọ ire sẹhin kuro lọdọ ẹniti iṣe tirẹ̀, bi o ba wà li agbara ọwọ rẹ lati ṣe e.
28Máṣe wi fun ẹnikeji rẹ pe, Lọ, ki o si pada wá, bi o ba si di ọla, emi o fi fun ọ; nigbati iwọ ni i li ọwọ rẹ.
29Máṣe gbìro buburu si ọmọnikeji rẹ, bi on ti joko laibẹ̀ru lẹba ọdọ rẹ.
30Máṣe ba enia jà lainidi, bi on kò ba ṣe ọ ni ibi.
31Máṣe ilara aninilara, má si ṣe yàn ọkan ninu gbogbo ọ̀na rẹ̀.
32Nitoripe irira li ẹlẹgan loju Oluwa; ṣugbọn aṣiri rẹ̀ wà pẹlu awọn olododo.
33Egún Oluwa mbẹ ni ile awọn enia buburu: ṣugbọn o bukún ibujoko awọn olõtọ.
34Nitõtọ o ṣe ẹ̀ya si awọn ẹlẹya: ṣugbọn o fi ore-ọfẹ fun awọn onirẹlẹ.
35Awọn ọlọgbọ́n ni yio jogun ogo: ṣugbọn awọn aṣiwere ni yio ru itiju wọn.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Owe 3: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa