Orísun omi ni ọkàn ọba lọ́wọ́ OLUWA, ibi tí ó bá wu Oluwa ni ó ń darí rẹ̀ sí. Gbogbo ọ̀nà eniyan ni ó dára lójú ara rẹ̀, ṣugbọn ọkàn ni OLUWA ń wò. Kí eniyan ṣe òdodo ati ẹ̀tọ́, sàn ju ẹbọ lọ lójú OLUWA. Bíi fìtílà ẹni ibi ni gbígbé ojú gangan ati ìgbéraga, ẹ̀ṣẹ̀ sì ni wọ́n. Dájúdájú èrò ẹni tí ó ṣiṣẹ́ tọkàntọkàn yóo yọrí sí ọ̀pọ̀, ṣugbọn ẹni tí ó bá ń kánjú jù kò ní ní ànító. Fífi èké kó ìṣúra jọ dàbí lílé ìkùukùu, ó sì jẹ́ tàkúté ikú. Ìwà ipá àwọn ẹni ibi ni yóo gbá wọn dànù, nítorí pé wọ́n kọ̀ láti ṣe òtítọ́. Ọ̀nà ẹlẹ́bi kì í gún, ṣugbọn ìrìn aláìlẹ́bi a máa tọ́. Ó sàn láti máa gbé kọ̀rọ̀ kan lókè àjà, ju pé kí eniyan máa bá oníjàngbọ̀n obinrin gbé ilé lọ. Ibi ni ọkàn eniyan burúkú máa ń fẹ́, àwọn aládùúgbò rẹ̀ kì í sìí rí ojurere rẹ̀. Ìjìyà ẹlẹ́yà a máa mú kí òpè gbọ́n, tí a bá ń kọ́ ọlọ́gbọ́n, yóo ní ìmọ̀ sí i. Olódodo ṣàkíyèsí ilé eniyan burúkú, eniyan burúkú sì bọ́ sinu ìparun. Ẹni tí ó kọ etí dídi sí igbe talaka, òun náà yóo kígbe, ṣugbọn kò ní rí ẹni dá a lóhùn. Ẹ̀bùn tí a fúnni ní kọ̀rọ̀ a máa paná ibinu, àbẹ̀tẹ́lẹ̀ tí a tì bọ abẹ́ aṣọ a máa paná ìjà. Tí a bá ṣe ìdájọ́ òtítọ́, inú olódodo a dùn, ṣugbọn ìfòyà ni fún àwọn aṣebi. Ẹni tí ó sá kúrò lọ́nà òye yóo sinmi láàrin àwọn òkú.
Kà ÌWÉ ÒWE 21
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ÌWÉ ÒWE 21:1-16
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò