ÌWÉ ÒWE 21

21
1Orísun omi ni ọkàn ọba lọ́wọ́ OLUWA,
ibi tí ó bá wu Oluwa ni ó ń darí rẹ̀ sí.
2Gbogbo ọ̀nà eniyan ni ó dára lójú ara rẹ̀,
ṣugbọn ọkàn ni OLUWA ń wò.
3Kí eniyan ṣe òdodo ati ẹ̀tọ́,
sàn ju ẹbọ lọ lójú OLUWA.
4Bíi fìtílà ẹni ibi ni gbígbé ojú gangan ati ìgbéraga,
ẹ̀ṣẹ̀ sì ni wọ́n.
5Dájúdájú èrò ẹni tí ó ṣiṣẹ́ tọkàntọkàn yóo yọrí sí ọ̀pọ̀,
ṣugbọn ẹni tí ó bá ń kánjú jù kò ní ní ànító.
6Fífi èké kó ìṣúra jọ
dàbí lílé ìkùukùu, ó sì jẹ́ tàkúté ikú.
7Ìwà ipá àwọn ẹni ibi ni yóo gbá wọn dànù,
nítorí pé wọ́n kọ̀ láti ṣe òtítọ́.
8Ọ̀nà ẹlẹ́bi kì í gún,
ṣugbọn ìrìn aláìlẹ́bi a máa tọ́.
9Ó sàn láti máa gbé kọ̀rọ̀ kan lókè àjà,#Sir 25:16
ju pé kí eniyan máa bá oníjàngbọ̀n obinrin gbé ilé lọ.
10Ibi ni ọkàn eniyan burúkú máa ń fẹ́,
àwọn aládùúgbò rẹ̀ kì í sìí rí ojurere rẹ̀.
11Ìjìyà ẹlẹ́yà a máa mú kí òpè gbọ́n,
tí a bá ń kọ́ ọlọ́gbọ́n, yóo ní ìmọ̀ sí i.
12Olódodo ṣàkíyèsí ilé eniyan burúkú,
eniyan burúkú sì bọ́ sinu ìparun.
13Ẹni tí ó kọ etí dídi sí igbe talaka,
òun náà yóo kígbe, ṣugbọn kò ní rí ẹni dá a lóhùn.
14Ẹ̀bùn tí a fúnni ní kọ̀rọ̀ a máa paná ibinu,
àbẹ̀tẹ́lẹ̀ tí a tì bọ abẹ́ aṣọ a máa paná ìjà.
15Tí a bá ṣe ìdájọ́ òtítọ́, inú olódodo a dùn,
ṣugbọn ìfòyà ni fún àwọn aṣebi.
16Ẹni tí ó sá kúrò lọ́nà òye
yóo sinmi láàrin àwọn òkú.
17Ẹni tí ó fẹ́ràn fàájì yóo di talaka,
ẹni tí ó fẹ́ràn ọtí waini ati òróró kò ní lówó lọ́wọ́.
18Eniyan burúkú ni yóo forí gba ibi
tíì bá dé bá olódodo.
Alaiṣootọ ni yóo fara gba ìyà tí ó tọ́ sí olóòótọ́ inú.
19Ó sàn láti máa gbé ààrin aṣálẹ̀,
ju kí eniyan máa bá oníjà ati oníkanra obinrin gbé lọ.
20Ní ilé ọlọ́gbọ́n ni à á tí ń bá nǹkan olówó iyebíye,
ṣugbọn òmùgọ̀ a máa ba tirẹ̀ jẹ́.
21Ẹni tí ń lépa òdodo ati àánú
yóo rí ìyè, òdodo, ati iyì.
22Ọlọ́gbọ́n a máa gba ìlú àwọn alágbára
a sì wó ibi ààbò tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé lulẹ̀.
23Ẹni tí ó pa ẹnu rẹ̀ mọ́
pa ara rẹ̀ mọ́ kúrò ninu ìyọnu.
24“Oníyẹ̀yẹ́” ni orúkọ ẹni tí ń gbéraga,
tí ó sì ń ṣe mo tó báyìí-dà báyìí.
25Ìrònú ohun tí ọ̀lẹ fẹ́ ni yóo pa á,
nítorí ọwọ́ rẹ̀ kọ̀ láti ṣiṣẹ́.
26Eniyan burúkú a máa ṣe ojúkòkòrò ní gbogbo ìgbà,
ṣugbọn olódodo ń fúnni láìdáwọ́dúró.
27Ohun ìríra ni ẹbọ eniyan burúkú,#Sir 7:9
pàápàá tí ó bá mú un wá pẹlu èrò ibi.
28Ọ̀rọ̀ ẹlẹ́rìí èké yóo di asán,
ṣugbọn ọ̀rọ̀ ẹni tí ó fetí sílẹ̀ ni a óo gbàgbọ́.
29Eniyan burúkú a máa lo ògbójú,
ṣugbọn olóòótọ́ máa ń yẹ ọ̀nà ara rẹ̀ wò.
30Kò sí ọgbọ́n, tabi òye, tabi ìmọ̀,
tí ó lè dojú kọ OLUWA kí ó mókè.
31Eniyan a máa tọ́jú ẹṣin sílẹ̀ de ọjọ́ ogun,
ṣugbọn OLUWA ló ni ìṣẹ́gun.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ÌWÉ ÒWE 21: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa