ÌWÉ ÒWE 12

12
1Ẹni tí ó fẹ́ ìtọ́sọ́nà, ó fẹ́ ìmọ̀,#Sir 21:6
ṣugbọn ẹni tí ó kórìíra ìbáwí òmùgọ̀ ni.
2Eniyan rere a máa ní ojurere lọ́dọ̀ OLUWA,
ṣugbọn ẹni tí ń pète ìkà ni yóo dá lẹ́bi.
3Kò sí ẹni tí ó lè ti ipa ìwà ìkà fi ìdí múlẹ̀,
ṣugbọn gbòǹgbò olódodo kò ní fà tu.
4Obinrin oníwàrere ni adé orí ọkọ rẹ̀,
ṣugbọn obinrin tí ń dójúti ọkọ dàbí ọyún inú egungun.
5Èrò ọkàn olódodo dára,
ṣugbọn ẹ̀tàn ni ìmọ̀ràn àwọn eniyan burúkú.
6Ọ̀rọ̀ àwọn eniyan burúkú dàbí ẹni tí ó lúgọ láti pa eniyan,
ṣugbọn ọ̀rọ̀ ẹnu olódodo a máa gbani là.
7A bi àwọn eniyan burúkú lulẹ̀, wọ́n sì parun,
ṣugbọn ìdílé olódodo yóo dúró gbọningbọnin.
8À máa ń yin eniyan gẹ́gẹ́ bí ó bá ṣe gbọ́n tó,
ṣugbọn ọlọ́kàn àgàbàgebè yóo di ẹni ẹ̀gàn.
9Mẹ̀kúnnù tí ó ní iṣẹ́, tí ó tún gba ọmọ-ọ̀dọ̀
ó sàn ju ẹni tí ó ń ṣe bí eniyan pataki, ṣugbọn tí kò rí oúnjẹ jẹ lọ.
10Olódodo a máa ka ẹ̀mí ẹran ọ̀sìn rẹ̀ sí,
ṣugbọn eniyan burúkú rorò sí tirẹ̀.
11Ẹni tí ó bá ń dáko yóo ní ọ̀pọ̀ oúnjẹ,
ṣugbọn ẹni tí ó bá ń lo àkókò rẹ̀ lórí ohun tí kò lérè, kò lọ́gbọ́n lórí.
12Ilé ìṣọ́ àwọn eniyan burúkú yóo di òkítì àlàpà,
ṣugbọn gbòǹgbò eniyan rere a máa fìdí múlẹ̀ sí i.
13Ọ̀rọ̀ ẹnu eniyan burúkú a máa mú un bíi tàkúté,
ṣugbọn olódodo a máa bọ́ ninu ìyọnu.
14Ọ̀rọ̀ ẹnu ọlọ́gbọ́n a máa mú ìtẹ́lọ́rùn bá a,
a sì máa jèrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.
15Ọ̀nà òmùgọ̀ níí dára lójú tirẹ̀,
ṣugbọn ọlọ́gbọ́n a máa fetí sí ìmọ̀ràn.
16Bí inú bá ń bí òmùgọ̀, kíá ni gbogbo eniyan yóo mọ̀,
ṣugbọn ọlọ́gbọ́n kìí ka ọ̀rọ̀ àbùkù sí.
17Ẹni tí ó bá ń sọ òtítọ́ a máa jẹ́rìí òdodo,
ṣugbọn irọ́ ni ẹlẹ́rìí èké máa ń pa.
18Ẹni tí í bá máa ń sọ̀rọ̀ jàbùjàbù láìronú,
ọ̀rọ̀ rẹ̀ dàbí kí á fi idà gún eniyan,
ṣugbọn ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n dàbí ẹni wo ọgbẹ́ sàn.
19Ọ̀rọ̀ òtítọ́ yóo máa wà títí ayé
ṣugbọn irọ́, fún ìgbà díẹ̀ ni.
20Ẹ̀tàn ń bẹ lọ́kàn àwọn tí ń pète ibi,
ṣugbọn àwọn tí ń gbèrò rere ní ayọ̀.
21Nǹkan burúkú kò ní ṣẹlẹ̀ sí olódodo,
ṣugbọn eniyan burúkú yóo kún fún ìyọnu.
22OLUWA kórìíra ẹni tí ń parọ́,
ṣugbọn inú rẹ̀ dùn sí olóòótọ́.
23Ọlọ́gbọ́n a máa fi ìmọ̀ rẹ̀ pamọ́,
ṣugbọn àwọn òmùgọ̀ a máa kéde agọ̀ wọn.
24Ẹni tí ń fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ ni yóo máa jẹ́ olórí,
ṣugbọn ọ̀lẹ ni a óo máa mú ṣiṣẹ́ tipátipá.
25Ọ̀pọ̀ ìpayà máa ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá eniyan,
ṣugbọn ọ̀rọ̀ rere a máa mú inú eniyan dùn.
26Olódodo a máa yipada kúrò ninu ibi,
ṣugbọn ìwà ẹni ibi a máa mú un ṣìnà.
27Ọwọ́ ọ̀lẹ kò lè tẹ ohun tí ó ń lé,
ṣugbọn ẹni tí ń fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ yóo ní ọpọlọpọ ọrọ̀.
28Ní ọ̀nà òdodo ni ìyè wà,
kò sí ikú ní ojú ọ̀nà rẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ÌWÉ ÒWE 12: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀