1
ÌWÉ ÒWE 12:25
Yoruba Bible
Ọ̀pọ̀ ìpayà máa ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá eniyan, ṣugbọn ọ̀rọ̀ rere a máa mú inú eniyan dùn.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 12:25
2
ÌWÉ ÒWE 12:1
Ẹni tí ó fẹ́ ìtọ́sọ́nà, ó fẹ́ ìmọ̀, ṣugbọn ẹni tí ó kórìíra ìbáwí òmùgọ̀ ni.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 12:1
3
ÌWÉ ÒWE 12:18
Ẹni tí í bá máa ń sọ̀rọ̀ jàbùjàbù láìronú, ọ̀rọ̀ rẹ̀ dàbí kí á fi idà gún eniyan, ṣugbọn ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n dàbí ẹni wo ọgbẹ́ sàn.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 12:18
4
ÌWÉ ÒWE 12:15
Ọ̀nà òmùgọ̀ níí dára lójú tirẹ̀, ṣugbọn ọlọ́gbọ́n a máa fetí sí ìmọ̀ràn.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 12:15
5
ÌWÉ ÒWE 12:16
Bí inú bá ń bí òmùgọ̀, kíá ni gbogbo eniyan yóo mọ̀, ṣugbọn ọlọ́gbọ́n kìí ka ọ̀rọ̀ àbùkù sí.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 12:16
6
ÌWÉ ÒWE 12:4
Obinrin oníwàrere ni adé orí ọkọ rẹ̀, ṣugbọn obinrin tí ń dójúti ọkọ dàbí ọyún inú egungun.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 12:4
7
ÌWÉ ÒWE 12:22
OLUWA kórìíra ẹni tí ń parọ́, ṣugbọn inú rẹ̀ dùn sí olóòótọ́.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 12:22
8
ÌWÉ ÒWE 12:26
Olódodo a máa yipada kúrò ninu ibi, ṣugbọn ìwà ẹni ibi a máa mú un ṣìnà.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 12:26
9
ÌWÉ ÒWE 12:19
Ọ̀rọ̀ òtítọ́ yóo máa wà títí ayé ṣugbọn irọ́, fún ìgbà díẹ̀ ni.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 12:19
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò