ÌWÉ ÒWE 13

13
1Ọlọ́gbọ́n ọmọ a máa gba ẹ̀kọ́ baba rẹ̀,
ṣugbọn ẹlẹ́yà kì í gbọ́ ìbáwí.
2Eniyan rere a máa rí ire nítorí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀,
ṣugbọn ohun tí àwọn ẹlẹ́tàn ń fẹ́ ni ìwà jàgídíjàgan.
3Ẹni tí ó ń ṣọ́ ẹnu rẹ̀, ẹ̀mí ara rẹ̀ ni ó ń ṣọ́,#Sir 28:25-26
ẹni tí ń sọ̀rọ̀ àsọjù yóo parun.
4Ọkàn ọ̀lẹ ń fẹ́ nǹkan, ṣugbọn kò ní rí i,
ṣugbọn ẹni tí ń fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ yóo ní ọpọlọpọ nǹkan.
5Olóòótọ́ a máa kórìíra èké,
ṣugbọn eniyan burúkú a máa hùwà ìtìjú ati àbùkù.
6Òdodo a máa dáàbò bo ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ bá tọ́,
ṣugbọn ẹ̀ṣẹ̀ a máa bi eniyan burúkú ṣubú.
7Ẹnìkan ń ṣe bí ọlọ́rọ̀,
bẹ́ẹ̀ kò ní nǹkankan,
níbẹ̀ ni ẹlòmíràn ń ṣe bíi talaka,
ṣugbọn tí ó ní ọpọlọpọ ọrọ̀.
8Ọlọ́rọ̀ a máa fi ohun ìní rẹ̀ ra ẹ̀mí rẹ̀ pada,
ṣugbọn talaka kì í tilẹ̀ gbọ́ ìbáwí.
9Ìmọ́lẹ̀ olódodo a máa fi ayọ̀ tàn,
ṣugbọn fìtílà eniyan burúkú yóo kú.
10Ìjà ni ìgbéraga máa ń fà,
ṣugbọn àwọn tí wọ́n bá gba ìmọ̀ràn yóo ní ọgbọ́n.
11Ọrọ̀ tí a fi ìkánjú kójọ kì í pẹ́ dínkù,
ṣugbọn ẹni tí ó bá fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ kó ọrọ̀ jọ yóo máa ní àníkún.
12Bí ìrètí bá pẹ́ jù, a máa kó àárẹ̀ bá ọkàn,
ṣugbọn kí á tètè rí ohun tí à ń fẹ́ a máa mú ara yá gágá.
13Ẹni tí ó kẹ́gàn ìmọ̀ràn yóo parun,
ṣugbọn ẹni tí ó bá bẹ̀rù òfin yóo jèrè rẹ̀.
14Ìtọ́ni ọlọ́gbọ́n jẹ́ orísun ìyè
a máa yọni ninu tàkúté ikú.
15Ẹni tí ó ní òye yóo rí ojurere,
ṣugbọn ọ̀nà àwọn tí kò ṣe é gbẹ́kẹ̀lé ni ìparun wọn.
16Olóye eniyan a máa fi ìmọ̀ ṣe ohun gbogbo,
ṣugbọn òmùgọ̀ a máa fi agọ̀ rẹ̀ yangàn.
17Iranṣẹ burúkú a máa kó àwọn eniyan sinu wahala,
ṣugbọn ikọ̀ tí ó bá jẹ́ olóòótọ́ a máa mú ìrẹ́pọ̀ wá.
18Òṣì ati àbùkù ni yóo bá ẹni tí ó kọ ìmọ̀ràn,
ṣugbọn ẹni tó bá gba ìbáwí yóo gba iyì.
19Bí èrò ọkàn ẹni bá ṣẹ, a máa fúnni láyọ̀,
ṣugbọn àwọn òmùgọ̀ kórìíra ati kọ ibi sílẹ̀.
20Bí eniyan bá ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóo gbọ́n,#Sir 6:33-34
ṣugbọn ẹni tí ó bá ń bá òmùgọ̀ kẹ́gbẹ́ yóo ṣìnà.
21Àjálù kì í dẹ̀yìn lẹ́yìn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,
ṣugbọn olódodo yóo máa rí ire.
22Eniyan rere a máa fi ogún sílẹ̀ fún àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀,
ṣugbọn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ń kó ọrọ̀ jọ fún àwọn olóòótọ́.
23Oko tí talaka dá lè mú ọpọlọpọ oúnjẹ jáde,
ṣugbọn àwọn alaiṣootọ níí kó gbogbo rẹ̀ lọ.
24Ẹni tí kì í bá na ọmọ rẹ̀ kò fẹ́ràn rẹ̀,
ṣugbọn ẹni tí ó fẹ́ràn ọmọ rẹ̀ yóo máa bá a wí.
25Olódodo a máa jẹ àjẹtẹ́rùn,
ṣugbọn eniyan burúkú kì í yó.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ÌWÉ ÒWE 13: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀