ÌWÉ ÒWE 12:15-28

ÌWÉ ÒWE 12:15-28 YCE

Ọ̀nà òmùgọ̀ níí dára lójú tirẹ̀, ṣugbọn ọlọ́gbọ́n a máa fetí sí ìmọ̀ràn. Bí inú bá ń bí òmùgọ̀, kíá ni gbogbo eniyan yóo mọ̀, ṣugbọn ọlọ́gbọ́n kìí ka ọ̀rọ̀ àbùkù sí. Ẹni tí ó bá ń sọ òtítọ́ a máa jẹ́rìí òdodo, ṣugbọn irọ́ ni ẹlẹ́rìí èké máa ń pa. Ẹni tí í bá máa ń sọ̀rọ̀ jàbùjàbù láìronú, ọ̀rọ̀ rẹ̀ dàbí kí á fi idà gún eniyan, ṣugbọn ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n dàbí ẹni wo ọgbẹ́ sàn. Ọ̀rọ̀ òtítọ́ yóo máa wà títí ayé ṣugbọn irọ́, fún ìgbà díẹ̀ ni. Ẹ̀tàn ń bẹ lọ́kàn àwọn tí ń pète ibi, ṣugbọn àwọn tí ń gbèrò rere ní ayọ̀. Nǹkan burúkú kò ní ṣẹlẹ̀ sí olódodo, ṣugbọn eniyan burúkú yóo kún fún ìyọnu. OLUWA kórìíra ẹni tí ń parọ́, ṣugbọn inú rẹ̀ dùn sí olóòótọ́. Ọlọ́gbọ́n a máa fi ìmọ̀ rẹ̀ pamọ́, ṣugbọn àwọn òmùgọ̀ a máa kéde agọ̀ wọn. Ẹni tí ń fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ ni yóo máa jẹ́ olórí, ṣugbọn ọ̀lẹ ni a óo máa mú ṣiṣẹ́ tipátipá. Ọ̀pọ̀ ìpayà máa ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá eniyan, ṣugbọn ọ̀rọ̀ rere a máa mú inú eniyan dùn. Olódodo a máa yipada kúrò ninu ibi, ṣugbọn ìwà ẹni ibi a máa mú un ṣìnà. Ọwọ́ ọ̀lẹ kò lè tẹ ohun tí ó ń lé, ṣugbọn ẹni tí ń fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ yóo ní ọpọlọpọ ọrọ̀. Ní ọ̀nà òdodo ni ìyè wà, kò sí ikú ní ojú ọ̀nà rẹ̀.