Owe 12:15-28
Owe 12:15-28 Yoruba Bible (YCE)
Ọ̀nà òmùgọ̀ níí dára lójú tirẹ̀, ṣugbọn ọlọ́gbọ́n a máa fetí sí ìmọ̀ràn. Bí inú bá ń bí òmùgọ̀, kíá ni gbogbo eniyan yóo mọ̀, ṣugbọn ọlọ́gbọ́n kìí ka ọ̀rọ̀ àbùkù sí. Ẹni tí ó bá ń sọ òtítọ́ a máa jẹ́rìí òdodo, ṣugbọn irọ́ ni ẹlẹ́rìí èké máa ń pa. Ẹni tí í bá máa ń sọ̀rọ̀ jàbùjàbù láìronú, ọ̀rọ̀ rẹ̀ dàbí kí á fi idà gún eniyan, ṣugbọn ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n dàbí ẹni wo ọgbẹ́ sàn. Ọ̀rọ̀ òtítọ́ yóo máa wà títí ayé ṣugbọn irọ́, fún ìgbà díẹ̀ ni. Ẹ̀tàn ń bẹ lọ́kàn àwọn tí ń pète ibi, ṣugbọn àwọn tí ń gbèrò rere ní ayọ̀. Nǹkan burúkú kò ní ṣẹlẹ̀ sí olódodo, ṣugbọn eniyan burúkú yóo kún fún ìyọnu. OLUWA kórìíra ẹni tí ń parọ́, ṣugbọn inú rẹ̀ dùn sí olóòótọ́. Ọlọ́gbọ́n a máa fi ìmọ̀ rẹ̀ pamọ́, ṣugbọn àwọn òmùgọ̀ a máa kéde agọ̀ wọn. Ẹni tí ń fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ ni yóo máa jẹ́ olórí, ṣugbọn ọ̀lẹ ni a óo máa mú ṣiṣẹ́ tipátipá. Ọ̀pọ̀ ìpayà máa ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá eniyan, ṣugbọn ọ̀rọ̀ rere a máa mú inú eniyan dùn. Olódodo a máa yipada kúrò ninu ibi, ṣugbọn ìwà ẹni ibi a máa mú un ṣìnà. Ọwọ́ ọ̀lẹ kò lè tẹ ohun tí ó ń lé, ṣugbọn ẹni tí ń fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ yóo ní ọpọlọpọ ọrọ̀. Ní ọ̀nà òdodo ni ìyè wà, kò sí ikú ní ojú ọ̀nà rẹ̀.
Owe 12:15-28 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọ̀na aṣiwere tọ li oju ara rẹ̀: ṣugbọn ẹniti o fetisi ìgbimọ li ọlọgbọ́n. Ibinu aṣiwere kò pẹ imọ̀: ṣugbọn amoye enia bò itiju mọlẹ. Ẹniti o sọ otitọ, o fi ododo hàn jade; ṣugbọn ẹlẹri eke, ẹ̀tan. Awọn kan mbẹ ti nyara sọ̀rọ lasan bi igunni idà; ṣugbọn ahọn ọlọgbọ́n, ilera ni. Ete otitọ li a o mu duro lailai; ṣugbọn ahọn eke, ìgba diẹ ni. Ẹtan wà li aiya awọn ti nrò ibi: ṣugbọn fun awọn ìgbimọ alafia, ayọ̀ ni. Kò si ibi kan ti yio ba olododo; ṣugbọn awọn enia buburu ni yio kún fun ibi. Irira loju Oluwa li ahọn eke; ṣugbọn awọn ti nṣe rere ni didùn-inu rẹ̀. Ọlọgbọ́n enia pa ìmọ mọ; ṣugbọn aiya awọn aṣiwere nkede iwere. Ọwọ alãpọn ni yio ṣe akoso; ṣugbọn ọlẹ ni yio wà labẹ irú-sisìn. Ibinujẹ li aiya enia ni idori rẹ̀ kọ odò; ṣugbọn ọ̀rọ rere ni imu u yọ̀. Olododo tọ́ aladugbo rẹ̀ si ọ̀na; ṣugbọn ọ̀na awọn enia buburu tàn wọn jẹ. Ọlẹ enia kò mu ohun ọdẹ rẹ̀; ṣugbọn lati jẹ alãpọn enia, ọrọ̀ iyebiye ni. Li ọ̀na olododo ni ìye; ikú kò si loju ọ̀na otitọ.
Owe 12:15-28 Yoruba Bible (YCE)
Ọ̀nà òmùgọ̀ níí dára lójú tirẹ̀, ṣugbọn ọlọ́gbọ́n a máa fetí sí ìmọ̀ràn. Bí inú bá ń bí òmùgọ̀, kíá ni gbogbo eniyan yóo mọ̀, ṣugbọn ọlọ́gbọ́n kìí ka ọ̀rọ̀ àbùkù sí. Ẹni tí ó bá ń sọ òtítọ́ a máa jẹ́rìí òdodo, ṣugbọn irọ́ ni ẹlẹ́rìí èké máa ń pa. Ẹni tí í bá máa ń sọ̀rọ̀ jàbùjàbù láìronú, ọ̀rọ̀ rẹ̀ dàbí kí á fi idà gún eniyan, ṣugbọn ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n dàbí ẹni wo ọgbẹ́ sàn. Ọ̀rọ̀ òtítọ́ yóo máa wà títí ayé ṣugbọn irọ́, fún ìgbà díẹ̀ ni. Ẹ̀tàn ń bẹ lọ́kàn àwọn tí ń pète ibi, ṣugbọn àwọn tí ń gbèrò rere ní ayọ̀. Nǹkan burúkú kò ní ṣẹlẹ̀ sí olódodo, ṣugbọn eniyan burúkú yóo kún fún ìyọnu. OLUWA kórìíra ẹni tí ń parọ́, ṣugbọn inú rẹ̀ dùn sí olóòótọ́. Ọlọ́gbọ́n a máa fi ìmọ̀ rẹ̀ pamọ́, ṣugbọn àwọn òmùgọ̀ a máa kéde agọ̀ wọn. Ẹni tí ń fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ ni yóo máa jẹ́ olórí, ṣugbọn ọ̀lẹ ni a óo máa mú ṣiṣẹ́ tipátipá. Ọ̀pọ̀ ìpayà máa ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá eniyan, ṣugbọn ọ̀rọ̀ rere a máa mú inú eniyan dùn. Olódodo a máa yipada kúrò ninu ibi, ṣugbọn ìwà ẹni ibi a máa mú un ṣìnà. Ọwọ́ ọ̀lẹ kò lè tẹ ohun tí ó ń lé, ṣugbọn ẹni tí ń fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ yóo ní ọpọlọpọ ọrọ̀. Ní ọ̀nà òdodo ni ìyè wà, kò sí ikú ní ojú ọ̀nà rẹ̀.
Owe 12:15-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọ̀nà aláìgbọ́n dára lójú ara rẹ̀ ṣùgbọ́n ọlọ́gbọ́n ènìyàn a máa gba ìmọ̀ràn. Aláìgbọ́n ènìyàn fi ìbínú un rẹ̀ hàn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ṣùgbọ́n olóye ènìyàn fojú fo ìyànjẹ. Ẹni tí ó jẹ́ ajẹ́rìí òtítọ́ jẹ́rìí ohun tí ojú rẹ̀ rí ṣùgbọ́n ajẹ́rìí èké máa ń parọ́. Ọ̀rọ̀ tí a kò rò jinlẹ̀ máa ń gún ni bí ọ̀kọ̀ ṣùgbọ́n ahọ́n ọlọ́gbọ́n ń mú ìwòsàn wá. Ètè tí ń ṣọ òtítọ́ yóò wà láéláé ṣùgbọ́n ahọ́n tí ń parọ́ kì í tọ́jọ́. Ẹ̀tàn wà nínú ọkàn àwọn tí ń pète búburú ṣùgbọ́n ayọ̀ wà fún àwọn tí ń mú kí àlàáfíà gbilẹ̀. Ibi kì í ṣubú lu olódodo rárá ṣùgbọ́n ènìyàn búburú gba ìpín ìyọnu tiwọn. OLúWA kórìíra ètè tí ń parọ́ ṣùgbọ́n ó ní inú dídùn sí àwọn olóòtítọ́. Ènìyàn olóye fi ìmọ̀ rẹ̀ pamọ́ sínú ara rẹ̀ ṣùgbọ́n ọkàn ènìyàn búburú ń gbé ìwà òmùgọ̀ jáde. Ọwọ́ àìṣọ̀lẹ yóò jẹ ọba ṣùgbọ́n ọ̀lẹ ṣíṣe a máa yọrí sí ẹrú ṣíṣe. Ìbànújẹ́ ní ọkàn ènìyàn ní dorí rẹ̀ kodò ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ rere a máa mú kó yọ̀. Olódodo ènìyàn máa ń ṣọ́ra láti dọ́rẹ̀ẹ́ ṣùgbọ́n ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú ń mú wọn ṣìnà. Ọ̀lẹ ènìyàn kò sun ẹran tí ó pa lóko ọdẹ ṣùgbọ́n ẹni tí kì í ṣe ọ̀lẹ máa ń díwọ̀n ohun ìní rẹ̀. Ní ọ̀nà àwọn olódodo ni ìyè wà ní ọ̀nà náà ni àìkú wà.