ÌWÉ ÒWE 12:12-14

ÌWÉ ÒWE 12:12-14 YCE

Ilé ìṣọ́ àwọn eniyan burúkú yóo di òkítì àlàpà, ṣugbọn gbòǹgbò eniyan rere a máa fìdí múlẹ̀ sí i. Ọ̀rọ̀ ẹnu eniyan burúkú a máa mú un bíi tàkúté, ṣugbọn olódodo a máa bọ́ ninu ìyọnu. Ọ̀rọ̀ ẹnu ọlọ́gbọ́n a máa mú ìtẹ́lọ́rùn bá a, a sì máa jèrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.