Owe 12:12-14

Owe 12:12-14 YBCV

Enia buburu fẹ ilu-odi awọn enia buburu: ṣugbọn gbòngbo olododo so eso. Irekọja ète enia buburu li a fi idẹkùn rẹ̀: ṣugbọn olododo yio yọ kuro ninu ipọnju. Nipa ère ẹnu enia li a o fi ohun rere tẹ ẹ lọrun: ère-iṣẹ ọwọ enia li a o si san fun u.