MIKA 7

7
Ìwà Ìbàjẹ́ Israẹli
1Mo gbé! Nítorí pé, mo dàbí ìgbà tí wọn ti kórè èso àkókò ẹ̀ẹ̀rùn tán, tí wọ́n ti ká èso àjàrà tán; tí kò sí èso àjàrà mọ́ fún jíjẹ, tí kò sì sí àkọ́so èso ọ̀pọ̀tọ́ tí mo fẹ́ràn mọ́. 2Olóòótọ́ ti tán lórí ilẹ̀ ayé, kò sí olódodo mọ́ láàrin àwọn eniyan; gbogbo wọn ń wá ọ̀nà ìpànìyàn, olukuluku ń fi àwọ̀n dọdẹ arakunrin rẹ̀. 3Wọ́n mọ iṣẹ́ ibi í ṣe dáradára; àwọn ìjòyè ati àwọn onídàájọ́ wọn ń bèèrè àbẹ̀tẹ́lẹ̀, àwọn eniyan ńlá ń sọ èrò burúkú tí ó wà lọ́kàn wọn jáde; wọ́n sì ń pa ìmọ̀ wọn pọ̀. 4Ẹni tí ó sàn jùlọ ninu wọn dàbí ẹ̀gún, ẹni tí ó jẹ́ olódodo jùlọ láàrin wọn sì dàbí ẹ̀gún ọ̀gàn.
Ọjọ́ ìjìyà tí àwọn wolii wọn kéde ti dé; ìdàrúdàpọ̀ wọn sì ti kù sí dẹ̀dẹ̀. 5Má gbára lé aládùúgbò rẹ, má sì ṣe gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rẹ́; ṣọ́ra nípa ohun tí o óo máa bá iyawo rẹ sọ. 6Nítorí ọmọkunrin ń tàbùkù baba rẹ̀, ọmọbinrin sì ń dìde sí ìyá rẹ̀, iyawo ń gbógun ti ìyá ọkọ rẹ̀; àwọn ará ilé ẹni sì ni ọ̀tá ẹni.
7Ṣugbọn ní tèmi, n óo máa wo ojú OLUWA, n óo dúró de Ọlọrun ìgbàlà mi; Ọlọrun mi yóo sì gbọ́ tèmi.
OLUWA Mú Ìgbàlà Wá
8Má yọ̀ mí, ìwọ ọ̀tá mi; bí mo bá ṣubú, n óo dìde; bí mo bá sì wà ninu òkùnkùn, OLUWA yóo jẹ́ ìmọ́lẹ̀ mi. 9N óo fara da ìyà tí OLUWA bá fi jẹ mí Nítorí pé mo ti ṣẹ̀ ẹ́, títí tí yóo fi gbèjà mi, tí yóo sì dá mi láre. Yóo mú mi wá sinu ìmọ́lẹ̀; ojú mi yóo sì rí ìdáǹdè rẹ̀. 10Nígbà náà ni àwọn ọ̀tá mi yóo rí i, ojú yóo sì ti ẹni tí ń pẹ̀gàn mi pé, níbo ni OLUWA Ọlọrun mi wà? N óo fi ojú mi rí i; òun náà yóo wá di àtẹ̀mọ́lẹ̀ bí ẹrẹ̀ ní ìta gbangba.
11Ní ọjọ́ tí a óo bá mọ odi ìlú yín, ẹ̀yin ará Jerusalẹmu, ọjọ́ náà ni a óo sún ààlà yín siwaju. 12Ní ọjọ́ náà, àwọn eniyan yóo wá sọ́dọ̀ yín láti ilẹ̀ Asiria títí dé ilẹ̀ Ijipti, láti ilẹ̀ Ijipti títí dé bèbè odò Yufurate, láti òkun dé òkun, ati láti òkè ńlá dé òkè ńlá. 13Ṣugbọn ayé yóo di ahoro nítorí ìwàkiwà àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀; àní nítorí iṣẹ́kíṣẹ́ ọwọ́ wọn.
Àánú OLUWA Lórí Israẹli
14OLUWA, fi ọ̀pá rẹ tọ́ àwọn eniyan rẹ, àní agbo aguntan ìní rẹ, tí wọn ń dá gbé ninu igbó, láàrin ilẹ̀ ọgbà; jẹ́ kí wọ́n máa jẹko ní Baṣani ati ní Gileadi bí ìgbà àtijọ́.
15N óo fi ohun ìyanu hàn wọ́n gẹ́gẹ́ bíi ti ìgbà tí ẹ jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti. 16Àwọn orílẹ̀-èdè yóo rí i, ojú agbára wọn yóo tì wọ́n; wọn óo pa ẹnu wọn mọ́; etí wọn óo sì di; 17wọn óo fi ẹnu gbo ilẹ̀ bí ìgbín, pẹlu ìbẹ̀rù ati ìwárìrì ni wọn yóo jáde bí ejò, láti ibi ààbò wọn; ninu ìbẹ̀rù, wọn óo pada tọ OLUWA Ọlọrun wá, ẹ̀rù rẹ yóo sì máa bà wọ́n.
18Ta ló dàbí rẹ, Ọlọrun, tí ó ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji eniyan, tí ó sì ń fojú fo ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan ìní rẹ̀ yòókù, ibinu rẹ kì í wà títí lae, nítorí pé a máa dùn mọ́ ọ láti fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn. 19O óo tún ṣàánú wa, o óo sì fẹsẹ̀ tẹ ẹ̀ṣẹ̀ wa ní àtẹ̀parẹ́. O óo sọ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa sí ìsàlẹ̀ òkun. 20O óo fi òtítọ́ inú hàn sí Jakọbu, o óo sì fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí Abrahamu, gẹ́gẹ́ bí o ti búra fún àwọn baba wa láti ìgbà àtijọ́.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

MIKA 7: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀