MIKA 6

6
Ọlọrun bá Israẹli Rojọ́
1Ẹ gbọ́ ohun tí Ọlọrun sọ: Ẹ dìde, kí ẹ ro ẹjọ́ yín níwájú àwọn òkè ńlá, kí ẹ sì jẹ́ kí àwọn òkè kéékèèké gbọ́ ohùn yín.
2Ẹ̀yin òkè, ati ẹ̀yin ìpìlẹ̀ ayérayé, ẹ gbọ́ ẹjọ́ OLUWA, nítorí ó ń bá àwọn eniyan rẹ̀ rojọ́, yóo sì bá Israẹli jà.
3Ọlọrun ní, “Ẹ̀yin eniyan mi, kí ni mo fi ṣe yín? Kí ni mo ṣe tí ọ̀rọ̀ mi fi su yín? Ẹ dá mi lóhùn. 4Èmi ni mo sá mu yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti, tí mo rà yín pada kúrò lóko ẹrú; tí mo rán Mose, Aaroni ati Miriamu láti ṣáájú yín. 5Ẹ̀yin eniyan mi, ẹ ranti ète tí Balaki, ọba Moabu pa si yín, ati ìdáhùn tí Balaamu, ọmọ Beori, fún un. Ẹ ranti ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ninu ìrìn àjò yín láti Ṣitimu dé Giligali, kí ẹ lè mọ iṣẹ́ ìgbàlà tí OLUWA ṣe.”
Ohun Tí OLUWA Fẹ́ Kí Á Ṣe
6Kí ni n óo mú wá fún OLUWA, tí n óo fi rẹ ara mi sílẹ̀ níwájú Ọlọrun, ẹni gíga? Ṣé kí n wá siwaju rẹ̀ pẹlu ẹbọ sísun ni tabi pẹlu ọ̀dọ́ mààlúù ọlọ́dún kan? 7Ǹjẹ́ inú OLUWA yóo dùn bí mo bá mú ẹgbẹẹgbẹrun aguntan wá, pẹlu ẹgbẹgbaarun-un garawa òróró olifi? Ṣé kí n fi àkọ́bí mi ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ mi, àní kí n fi ọmọ tí mo bí rúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ mi? 8A ti fi ohun tí ó dára hàn ọ́, ìwọ eniyan. Kí ni OLUWA fẹ́ kí o ṣe, ju pé kí o jẹ́ olótìítọ́ lọ, kí o máa ṣàánú eniyan, kí o sì máa rìn ní ìrẹ̀lẹ̀ pẹlu Ọlọrun rẹ?
9Ẹ gbọ́ ẹ̀yin ará, ati àpéjọ gbogbo ìlú; ohun tí ó ti dára ni pé kí eniyan bẹ̀rù OLUWA; 10Ǹjẹ́ mo lè gbàgbé ìṣúra aiṣododo tí ó wà ninu ilé àwọn eniyan burúkú, ati òṣùnwọ̀n èké ó jẹ́ ohun ìfibú? 11Báwo ni mo ṣe lè dáríjì àwọn tí ń lo òṣùnwọ̀n èké; tí àpò wọn sì kún fún ìwọ̀n tí kò péye? 12Àwọn ọlọ́rọ̀ yín kún fún ìwà ipá; òpùrọ́ ni gbogbo àwọn ará ìlú, ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn sì kún ẹnu wọn. 13Nítorí náà, mo ti bẹ̀rẹ̀ sí pa yín run n óo sọ ìlú yín di ahoro nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín. 14Ẹ óo jẹun, ṣugbọn ẹ kò ní yó, ebi yóo sì túbọ̀ máa pa yín, ẹ óo kó ọrọ̀ jọ, ṣugbọn kò ní dúró lọ́wọ́ yín, ogun ni yóo sì kó ohun tí ẹ kó jọ lọ. 15Ẹ óo fúnrúgbìn, ṣugbọn ẹ kò ní kórè rẹ̀; ẹ óo ṣe òróró olifi, ṣugbọn ẹ kò ní rí i fi para; ẹ óo ṣe ọtí waini, ṣugbọn ẹ kò ní rí i mu. 16Nítorí pé ẹ̀ ń tẹ̀lé ìlànà ọba Omiri, ati ti ìdílé ọba Ahabu, ẹ sì ti tẹ̀lé ìmọ̀ràn wọn; kí n lè sọ ìlú yín di ahoro, kí àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀ sì di ohun ẹ̀gàn; kí àwọn eniyan sì máa fi yín ṣẹ̀sín.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

MIKA 6: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀