MIKA 4

4
Ìjọba Alaafia OLUWA Tí Ó Kárí Ayé
(Ais 2:1-4)
1Nígbà tí ó bá yá, a óo fìdí òkè ilé OLUWA múlẹ̀
bí òkè tí ó ga jùlọ,
a óo gbé e ga ju àwọn òkè yòókù lọ,
àwọn eniyan yóo sì máa wọ́ wá sibẹ.
2Ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè yóo wá, wọn yóo sì wí pé,
“Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á lọ sórí òkè OLUWA,
ẹ jẹ́ kí á lọ sí ilé Ọlọrun Jakọbu,
kí ó lè kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀,
kí á sì lè máa tọ̀ ọ́.”
Nítorí pé láti Sioni ni òfin yóo ti máa jáde,
ọ̀rọ̀ OLUWA yóo sì máa jáde láti Jerusalẹmu.
3Yóo ṣe ìdájọ́ láàrin ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè,
ati láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí ó lágbára ní ọ̀nà jíjìn réré;
wọn yóo fi idà wọn rọ ọkọ́,
wọn yóo sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ dòjé;
àwọn orílẹ̀-èdè kò ní yọ idà sí ara wọn mọ́,
wọn kò sì ní kọ́ ogun jíjà mọ́.
4Ṣugbọn olukuluku yóo jókòó lábẹ́ àjàrà rẹ̀,
ati lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, kò sì ní sí ẹni tí yóo dẹ́rùbà wọ́n;
nítorí pé OLUWA àwọn ọmọ ogun ni ó sọ bẹ́ẹ̀.
5Olukuluku orílẹ̀-èdè a máa rìn ní ọ̀nà tí oriṣa rẹ̀ là sílẹ̀, ṣugbọn ọ̀nà OLUWA tí Ọlọrun wa là sílẹ̀ ni àwa yóo máa tọ̀ títí laelae.
Israẹli Yóo Pada láti Oko Ẹrú
6OLUWA ní, “Nígbà tí ó bá yá, n óo kó gbogbo àwọn arọ jọ, n óo kó àwọn tí mo ti túká jọ, ati àwọn tí mo ti pọ́n lójú. 7N óo dá àwọn arọ sí, kí wọ́n lè wà lára àwọn eniyan Israẹli tí wọ́n ṣẹ́kù, àwọn tí a túká yóo sì di orílẹ̀-èdè ńlá; OLUWA yóo sì jọba lórí wọn ní òkè Sioni láti ìsinsìnyìí lọ ati títí laelae.”
8Jerusalẹmu, ìwọ ilé ìṣọ́ agbo aguntan Sioni, ilé ọba rẹ àtijọ́ yóo pada sọ́dọ̀ rẹ, a óo dá ìjọba pada sí Jerusalẹmu. 9Kí ló dé, tí ò ń pariwo bẹ́ẹ̀? Ṣé ẹ kò ní ọba ni? Tabi ẹ kò ní olùdámọ̀ràn mọ́, ni ìrora fi mu yín bí obinrin tí ń rọbí? 10Ẹ máa yí nílẹ̀, kí ẹ sì máa kérora bí obinrin tí ń rọbí, ẹ̀yin ará Jerusalẹmu; nítorí pé ẹ gbọdọ̀ jáde ní ìlú yín wàyí, ẹ óo lọ máa gbé inú pápá; ẹ óo lọ sí Babiloni. Ibẹ̀ ni a óo ti gbà yín là, níbẹ̀ ni OLUWA yóo ti rà yín pada kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá yín. 11Ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè dojú ìjà kọ yín nisinsinyii, wọ́n sì ń wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á sọ Sioni di aláìmọ́, kí á sì dójúlé e.” 12Ṣugbọn àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi kò mọ èrò OLUWA, ìpinnu rẹ̀ kò sì yé wọn, pé ó ti kó wọn jọ láti pa wọ́n bí ẹni pa ọkà ní ibi ìpakà.
13Ẹ dìde kí ẹ tẹ àwọn ọ̀tá yín mọ́lẹ̀, ẹ̀yin ará Jerusalẹmu! Nítorí n óo mú kí ìwo rẹ lágbára bí irin, pátákò ẹsẹ̀ rẹ yóo sì dàbí idẹ; o óo fọ́ ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè túútúú, o óo sì ya ọrọ̀ wọn sọ́tọ̀ fún OLUWA, nǹkan ìní wọn yóo jẹ́ ti OLUWA àgbáyé.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

MIKA 4: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀