Ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè yóo wá, wọn yóo sì wí pé,
“Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á lọ sórí òkè OLUWA,
ẹ jẹ́ kí á lọ sí ilé Ọlọrun Jakọbu,
kí ó lè kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀,
kí á sì lè máa tọ̀ ọ́.”
Nítorí pé láti Sioni ni òfin yóo ti máa jáde,
ọ̀rọ̀ OLUWA yóo sì máa jáde láti Jerusalẹmu.