MIKA 3

3
Mika Bá Àwọn Olórí Israẹli Wí
1Ẹ gbọ́, ẹ̀yin olórí ilé Jakọbu, ati ẹ̀yin alákòóso ilé Israẹli! Ṣé kò yẹ kí ẹ mọ̀ nípa ìdájọ́ òtítọ́? 2Ẹ̀yin tí ẹ kórìíra ohun rere, tí ẹ sì fẹ́ràn ibi, ẹ̀yin tí ẹ bó awọ lára àwọn eniyan mi, tí ẹ sì ya ẹran ara egungun wọn; 3ẹ̀yin ni ẹ jẹ ẹran ara àwọn eniyan mi, ẹ bó awọ kúrò lára wọn, ẹ sì fọ́ egungun wọn sí wẹ́wẹ́, ẹ gé wọn lékìrí lékìrí bí ẹran inú ìsaasùn, àní, bí ẹran inú ìkòkò. 4Nígbà tí ó bá yá, wọn yóo ké pe OLUWA, ṣugbọn kò ní dá wọn lóhùn; yóo fi ojú pamọ́ fún wọn, nítorí nǹkan burúkú tí wọ́n ṣe.
5Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA sọ nípa àwọn wolii tí wọn ń ṣi àwọn eniyan mi lọ́nà, tí wọn ń kéde “Alaafia” níbi tí wọ́n bá ti ń rí oúnjẹ jẹ, ṣugbọn tí wọn ń kéde ogun níbi tí kò bá ti sí oúnjẹ. 6Nítorí náà, alẹ́ yín yóo lẹ́ ṣugbọn àwọn aríran yín kò ní rí nǹkankan, òkùnkùn yóo kùn, àwọn woṣẹ́woṣẹ́ yín kò ní rí iṣẹ́ wò. Ògo àwọn wolii yóo wọmi, òkùnkùn yóo sì bò wọ́n. 7A óo dójúti àwọn aríran, ojú yóo sì ti àwọn woṣẹ́woṣẹ́; gbogbo wọn yóo fi ọwọ́ bo ẹnu wọn, nítorí pé, Ọlọrun kò ní dá wọn lóhùn.
8Ṣugbọn ní tèmi, mo kún fún agbára, ati ẹ̀mí OLUWA, ati fún ìdájọ́ òdodo ati ipá, láti kéde ẹ̀ṣẹ̀ Jakọbu, ati láti sọ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli fún wọn. 9Ẹ gbọ́, ẹ̀yin olórí ilé Jakọbu, ati ẹ̀yin alákòóso ilé Israẹli, ẹ̀yin tí ẹ kórìíra ìdájọ́ òdodo, tí ẹ sì ń gbé ẹ̀bi fún aláre. 10Ẹ̀yin tí ẹ fi owó ẹ̀jẹ̀ kọ́ Sioni, tí ẹ sì fi èrè ìwà burúkú kọ́ Jerusalẹmu. 11Àwọn aláṣẹ ń gba owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ kí wọ́n tó ṣe ìdájọ́, àwọn alufaa ń gba owó iṣẹ́ wọn kí wọ́n tó kọ́ni, àwọn wolii ń gba owó kí wọ́n tó ríran; sibẹsibẹ, wọ́n gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, wọ́n ń wí pé, “Ṣebí OLUWA wà pẹlu wa? Nǹkan burúkú kò ní ṣẹlẹ̀ sí wa.”
12Nítorí náà, nítorí yín, a óo ro Sioni bí oko, Jerusalẹmu yóo di àlàpà, ahoro tẹmpili yóo sì di igbó kìjikìji.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

MIKA 3: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀