MATIU 3:1-9

MATIU 3:1-9 YCE

Nígbà tí ó yá, Johanu Onítẹ̀bọmi dé, ó ń waasu ní aṣálẹ̀ Judia. Ó ní, “Ẹ ronupiwada, nítorí ìjọba Ọlọrun fẹ́rẹ̀ dé.” Nítorí òun ni wolii Aisaya sọ nípa rẹ̀ pé, “Ohùn ẹnìkan tí ó ń kígbe ninu aṣálẹ̀ pé, ‘Ẹ la ọ̀nà tí OLUWA yóo gbà, ẹ ṣe é kí ó tọ́ fún un láti rìn.’ ” Johanu yìí wọ aṣọ tí a fi irun ràkúnmí hun, ọ̀já ìgbànú aláwọ ni ó gbà mọ́ ìdí. Oúnjẹ rẹ̀ ni ẹṣú ati oyin ìgàn. Nígbà náà ni àwọn eniyan láti Jerusalẹmu ati gbogbo ilẹ̀ Judia ati ní gbogbo ìgbèríko odò Jọdani ń jáde tọ̀ ọ́ lọ. Wọ́n ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn, ó sì ń ṣe ìrìbọmi fún wọn ninu odò Jọdani. Ṣugbọn nígbà tí ó rí ọ̀pọ̀ ninu àwọn Farisi ati Sadusi tí wọ́n wá sọ́dọ̀ rẹ̀ pé kí ó ṣe ìrìbọmi fún wọn, ó bi wọ́n pé, “Ẹ̀yin ìran paramọ́lẹ̀, ta ni ó kìlọ̀ fun yín láti sá fún ibinu tí ń bọ̀? Ẹ fihàn ninu ìwà yín pé ẹ ti ronupiwada. Ẹ má ṣe rò lọ́kàn yín pé, ‘A ní Abrahamu ní baba.’ Nítorí mo ń sọ fun yín pé Ọlọrun lè gbé ọmọ dìde fún Abrahamu láti inú òkúta wọnyi.

Àwọn fídíò fún MATIU 3:1-9