Matiu 3:1-9

Matiu 3:1-9 YCB

Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, Johanu onítẹ̀bọmi wá, ó ń wàásù ní aginjù Judea. Ó ń wí pé, “Ẹ ronúpìwàdà, nítorí ìjọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀.” Èyí ni ẹni náà ti wòlíì Isaiah sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ pé: “Ohùn ẹni ti ń kígbe ní ijù, ‘Ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe, ẹ ṣe ojú ọ̀nà rẹ̀ kí ó tọ́.’ ” Aṣọ Johanu náà sì jẹ́ ti irun ìbákasẹ, ó sì di àmùrè awọ sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Eṣú àti oyin ìgàn sì ni oúnjẹ rẹ̀. Àwọn ènìyàn jáde lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ láti Jerusalẹmu àti gbogbo Judea àti àwọn ènìyàn láti gbogbo ìhà Jordani. Wọ́n ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn, a sì ń bamitiisi wọn ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní odò Jordani. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó rí ọ̀pọ̀ àwọn Farisi àti Sadusi tí wọ́n ń wá ṣe ìtẹ̀bọmi, ó wí fún wọn pé: “Ẹ̀yin ọmọ paramọ́lẹ̀! Ta ni ó kìlọ̀ fún yín pé kí ẹ́ sá kúrò nínú ìbínú tí ń bọ̀? Ẹ so èso tí ó yẹ fún ìrònúpìwàdà. Kí ẹ má sì ṣe rò nínú ara yin pé, ‘Àwa ní Abrahamu ní baba.’ Èmi wí fún yín, Ọlọ́run lè mu àwọn ọmọ jáde láti inú àwọn òkúta wọ̀nyí wá fún Abrahamu.

Àwọn fídíò fún Matiu 3:1-9