MATIU 3

3
Iwaasu Johanu Onítẹ̀bọmi
(Mak 1:1-8; Luk 3:1-9, 15-17; Joh 1:19-28)
1Nígbà tí ó yá, Johanu Onítẹ̀bọmi dé, ó ń waasu ní aṣálẹ̀ Judia. 2Ó ní, “Ẹ ronupiwada, nítorí ìjọba Ọlọrun fẹ́rẹ̀ dé.” #Mat 4:17; Mak 1:15 3Nítorí òun ni wolii Aisaya sọ nípa rẹ̀ pé, #Ais 40:3
“Ohùn ẹnìkan tí ó ń kígbe ninu aṣálẹ̀ pé,
‘Ẹ la ọ̀nà tí OLUWA yóo gbà,
ẹ ṣe é kí ó tọ́ fún un láti rìn.’ ”
4Johanu yìí wọ aṣọ tí a fi irun ràkúnmí hun, ọ̀já ìgbànú aláwọ ni ó gbà mọ́ ìdí. Oúnjẹ rẹ̀ ni ẹṣú ati oyin ìgàn. #2 A. Ọba 1:8 5Nígbà náà ni àwọn eniyan láti Jerusalẹmu ati gbogbo ilẹ̀ Judia ati ní gbogbo ìgbèríko odò Jọdani ń jáde tọ̀ ọ́ lọ. 6Wọ́n ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn, ó sì ń ṣe ìrìbọmi fún wọn ninu odò Jọdani.
7Ṣugbọn nígbà tí ó rí ọ̀pọ̀ ninu àwọn Farisi ati Sadusi tí wọ́n wá sọ́dọ̀ rẹ̀ pé kí ó ṣe ìrìbọmi fún wọn, ó bi wọ́n pé, “Ẹ̀yin ìran paramọ́lẹ̀, ta ni ó kìlọ̀ fun yín láti sá fún ibinu tí ń bọ̀? #Mat 12:34; 23:33 8Ẹ fihàn ninu ìwà yín pé ẹ ti ronupiwada. 9Ẹ má ṣe rò lọ́kàn yín pé, ‘A ní Abrahamu ní baba.’ Nítorí mo ń sọ fun yín pé Ọlọrun lè gbé ọmọ dìde fún Abrahamu láti inú òkúta wọnyi. #Joh 8:33 10A sì ti fi àáké lé gbòǹgbò igi báyìí, nítorí náà, igikígi tí kò bá so èso rere ni a óo gé lulẹ̀, tí a óo fi dáná. #Mat 7:19 11Ìrìbọmi ni èmi fi ń wẹ̀ yín mọ́ nítorí ìrònúpìwàdà. Ṣugbọn ẹni tí ó ń bọ̀ lẹ́yìn mi jù mí lọ; èmi kò tó ẹni tí ó lè kó bàtà rẹ̀. Ẹ̀mí Mímọ́ ati iná ni òun yóo fi wẹ̀ yín mọ́. 12Àtẹ ìfẹ́kà rẹ̀ ń bẹ lọ́wọ́ rẹ̀. Yóo gbá ilẹ̀ ìpakà rẹ̀ mọ́ tótó. Yóo kó ọkà rẹ̀ jọ sinu abà, ṣugbọn sísun ni yóo sun fùlùfúlù ninu iná àjóòkú.” #Ọgb 5:14,23
Jesu Ṣe Ìrìbọmi
(Mak 1:9-11; Luk 3:21-22)
13Nígbà náà ni Jesu lọ láti ilẹ̀ Galili, sọ́dọ̀ Johanu ní odò Jọdani, kí Johanu lè ṣe ìrìbọmi fún un. 14Ṣugbọn Johanu fẹ́ kọ̀ fún un, ó ní, “Èmi gan-an ni mo nílò pé kí o ṣe ìrìbọmi fún mi; ìwọ ni ó tún tọ̀ mí wá?”
15Jesu dá a lóhùn pé, “Jẹ́ kí á ṣe é bẹ́ẹ̀ ná, nítorí báyìí ni ó yẹ fún wa bí a bá fẹ́ ṣe ẹ̀tọ́ láṣepé.” Nígbà náà ni Johanu gbà fún un.
16Bí Jesu ti ṣe ìrìbọmi tán, tí ó gòkè jáde kúrò ninu omi, ọ̀run pínyà lẹsẹkẹsẹ. Jesu wá rí Ẹ̀mí Ọlọrun tí ó sọ̀kalẹ̀ bí àdàbà, tí ó ń bà lé e. 17Ohùn kan láti ọ̀run wá sọ pé, “Àyànfẹ́ ọmọ mi nìyí, inú mi dùn sí i gidigidi.” #Jẹn 22:2; O. Daf 2:7; Ais 42:1; Mat 12:18; 17:5; Mak 1:11; Luk 9:35

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

MATIU 3: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀