MATIU 22:15-46

MATIU 22:15-46 YCE

Àwọn Farisi bá lọ forí-korí wọ́n ń wá ọ̀nà tí wọn yóo fi ká ọ̀rọ̀ mọ́ Jesu lẹ́nu. Wọ́n bá rán àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wọn pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Hẹrọdu láti bi í pé, “Olùkọ́ni, a mọ̀ pé olóòótọ́ ni ọ́, ati pé pẹlu òtítọ́ ni o fi ń kọ́ eniyan ní ọ̀nà Ọlọrun; o kì í ṣe ojuṣaaju fún ẹnikẹ́ni nítorí o kì í wojú eniyan kí o tó sọ̀rọ̀. Nítorí náà sọ ohun tí o rò fún wa. Ó tọ̀nà láti san owó-orí fún Kesari ni, àbí kò tọ̀nà?” Ṣugbọn Jesu mọ èrò ibi tí ó wà lọ́kàn wọn. Ó ní, “Kí ló dé tí ẹ fi ń dẹ mí ẹ̀yin alárèékérekè yìí? Ẹ fi owó tí ẹ fi ń san owó-orí hàn mí.” Wọ́n bá mú owó fadaka kan fún un. Ó wá bi wọ́n pé, “Àwòrán ati àkọlé ta ni èyí?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Ti Kesari ni.” Ó bá sọ fún wọn pé, “Tí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ fi ohun tí ó jẹ́ ti Kesari fún Kesari, kí ẹ sì fi ohun tíí ṣe ti Ọlọrun fún Ọlọrun.” Nígbà tí wọ́n gbọ́ báyìí, ẹnu yà wọ́n, wọ́n bá fi í sílẹ̀, wọ́n sì bá tiwọn lọ. Ní ọjọ́ náà, àwọn Sadusi kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀. (Àwọn Sadusi ni wọ́n sọ pé kò sí ajinde.) Wọ́n bi í pé, “Olùkọ́ni, Mose sọ pé bí ẹnìkan bá kú láì ní ọmọ, kí àbúrò rẹ̀ fẹ́ aya rẹ̀ kí ó lè bí ọmọ fún ẹ̀gbọ́n rẹ̀. Àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò meje kan wà lọ́dọ̀ wa. Ekinni gbé iyawo, láìpẹ́ ó kú. Nígbà tí kò bí ọmọ, ó fi iyawo rẹ̀ sílẹ̀ fún àbúrò rẹ̀. Ekeji náà kú, ati ẹkẹta, títí tí àwọn mejeeje fi kú. Ní ìkẹyìn gbogbo wọn, obinrin náà wá kú. Tí ó bá di àkókò ajinde, ninu àwọn mejeeje, iyawo ta ni obinrin náà yóo jẹ́, nígbà tí ó jẹ́ pé gbogbo wọn ni wọ́n ti fi ṣe aya?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ ṣìnà, nítorí pé ẹ kò mọ Ìwé Mímọ́ ati agbára Ọlọrun. Nítorí pé ní àkókò ajinde kò ní sí pé à ń gbé iyawo, tabi pé à ń fi ọmọ fún ọkọ; nítorí bí àwọn angẹli ti rí ní ọ̀run ni wọn yóo rí. Nípa ti ajinde àwọn òkú, ẹ kò ì tíì ka ọ̀rọ̀ tí Ọlọrun sọ fun yín pé, ‘Èmi ni Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki ati Ọlọrun Jakọbu.’ Ọlọrun kì í ṣe Ọlọrun àwọn òkú, Ọlọrun àwọn alààyè ni.” Nígbà tí àwọn eniyan gbọ́, ẹnu yà wọ́n sí ẹ̀kọ́ rẹ̀. Nígbà tí àwọn Farisi gbọ́ pé ó ti pa àwọn Sadusi lẹ́nu mọ́, wọ́n kó ara wọn jọ. Ọ̀kan ninu wọn tí ó jẹ́ amòfin, bi í ní ìbéèrè kan láti fi dẹ ẹ́, pé, “Olùkọ́ni, òfin wo ni ó ṣe pataki jùlọ ninu Ìwé Òfin?” Jesu dá a lóhùn pé, “ ‘Fẹ́ Oluwa Ọlọrun rẹ pẹlu gbogbo ọkàn rẹ, ati gbogbo ẹ̀mí rẹ, ati ní gbogbo èrò rẹ.’ Èyí ni òfin tí ó ga jùlọ, òun sì ni ekinni. Ekeji fi ara jọ ọ́: ‘Fẹ́ràn ọmọnikeji rẹ bí o ti fẹ́ ara rẹ.’ Òfin mejeeji wọnyi ni gbogbo òfin ìyókù ati ọ̀rọ̀ inú ìwé àwọn wolii rọ̀ mọ́.” Nígbà tí àwọn Farisi péjọ pọ̀, Jesu bi wọ́n pé, “Kí ni ẹ rò nípa Mesaya, ọmọ ta ni?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Ọmọ Dafidi ni.” Ó bá tún bi wọ́n pé, “Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, báwo ni Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe darí Dafidi tí Dafidi fi pe Mesaya ní ‘Oluwa’? Dafidi sọ pé, ‘OLUWA sọ fún Oluwa mi pé: Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi títí n óo fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ di ohun ìtìsẹ̀ rẹ.’ Bí Dafidi bá pè é ní ‘OLUWA’, báwo ni Mesaya ti ṣe jẹ́ ọmọ rẹ̀?” Kò sí ẹnìkan tí ó lè dá a lóhùn ọ̀rọ̀ yìí. Láti ọjọ́ náà, ẹnikẹ́ni kò ní ìgboyà láti tún bi í ní ohunkohun mọ́.

Àwọn fídíò fún MATIU 22:15-46