MATIU 22

22
Òwe Àsè Igbeyawo
(Luk 14:15-24)
1Jesu tún fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀. Ó ní, 2“Ìjọba ọ̀run dàbí ọba kan, tí ó ń gbeyawo fún ọmọ rẹ̀. 3Ó rán àwọn ẹrú rẹ̀ lọ pe àwọn tí ó dájọ́ igbeyawo náà fún, ṣugbọn wọn kò fẹ́ wá. 4Ó tún rán àwọn ẹrú mìíràn, kí wọ́n sọ fún àwọn tí a ti pè pé, ‘Mo ti se àsè tán; mo ti pa mààlúù ati àwọn ẹran ọlọ́ràá; mo ti ṣe ètò gbogbo tán. Ẹ wá sí ibi igbeyawo.’ 5Ṣugbọn wọn kò bìkítà. Ọ̀kan lọ sí oko rẹ̀, òmíràn lọ sí ìdí òwò rẹ̀. 6Àwọn ìyókù ki àwọn ẹrú mọ́lẹ̀, wọ́n lù wọ́n pa. 7Inú wá bí ọba náà, ó bá rán àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ kí wọ́n pa àwọn apànìyàn wọ̀n-ọn-nì run, kí wọ́n sì dáná sun ìlú wọn. 8Ó bá sọ fún àwọn ẹrú rẹ̀ pé, ‘A ti parí gbogbo ètò igbeyawo, ṣugbọn àwọn tí a ti pè kò yẹ. 9Ẹ wá lọ sí gbogbo oríta ìlú, ẹ pe gbogbo ẹni tí ẹ bá rí wá sí ibi igbeyawo.’ 10Àwọn ẹrú náà bá lọ sí ìgboro, wọ́n kó gbogbo àwọn tí wọ́n rí wá, ati àwọn eniyan rere, ati àwọn eniyan burúkú. Oniruuru eniyan bá kún ibi àsè igbeyawo.
11“Nígbà tí ọba wọlé láti wo àwọn tí wọn ń jẹun, ó rí ọkunrin kan níbẹ̀ tí kò wọ aṣọ igbeyawo. 12Ọba bi í pé, ‘Arakunrin, báwo ni o ti ṣe wọ ìhín láì ní aṣọ igbeyawo?’ Ṣugbọn kẹ́kẹ́ pamọ́ ọkunrin náà lẹ́nu. 13Ọba bá pàṣẹ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, ‘Ẹ dì í tọwọ́-tẹsẹ̀, kí ẹ sọ ọ́ sinu òkùnkùn biribiri. Níbẹ̀ ni ẹkún ati ìpayínkeke yóo wà.’#Mat 8:12; 25:30; Luk 13:28
14“Nítorí ọpọlọpọ ni a pè, ṣugbọn àwọn díẹ̀ ni a yàn.”
Ọ̀rọ̀ Jesu nípa Sísan Owó-orí fún Kesari
(Mak 12:13-17; Luk 20:20-26)
15Àwọn Farisi bá lọ forí-korí wọ́n ń wá ọ̀nà tí wọn yóo fi ká ọ̀rọ̀ mọ́ Jesu lẹ́nu. 16Wọ́n bá rán àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wọn pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Hẹrọdu láti bi í pé, “Olùkọ́ni, a mọ̀ pé olóòótọ́ ni ọ́, ati pé pẹlu òtítọ́ ni o fi ń kọ́ eniyan ní ọ̀nà Ọlọrun; o kì í ṣe ojuṣaaju fún ẹnikẹ́ni nítorí o kì í wojú eniyan kí o tó sọ̀rọ̀. 17Nítorí náà sọ ohun tí o rò fún wa. Ó tọ̀nà láti san owó-orí fún Kesari ni, àbí kò tọ̀nà?”
18Ṣugbọn Jesu mọ èrò ibi tí ó wà lọ́kàn wọn. Ó ní, “Kí ló dé tí ẹ fi ń dẹ mí ẹ̀yin alárèékérekè yìí? 19Ẹ fi owó tí ẹ fi ń san owó-orí hàn mí.”
Wọ́n bá mú owó fadaka kan fún un. 20Ó wá bi wọ́n pé, “Àwòrán ati àkọlé ta ni èyí?”
21Wọ́n dá a lóhùn pé, “Ti Kesari ni.”
Ó bá sọ fún wọn pé, “Tí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ fi ohun tí ó jẹ́ ti Kesari fún Kesari, kí ẹ sì fi ohun tíí ṣe ti Ọlọrun fún Ọlọrun.”
22Nígbà tí wọ́n gbọ́ báyìí, ẹnu yà wọ́n, wọ́n bá fi í sílẹ̀, wọ́n sì bá tiwọn lọ.
Ìjiyàn lórí Ajinde Àwọn Òkú
(Mak 12:18-27; Luk 20:27-40)
23Ní ọjọ́ náà, àwọn Sadusi kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀. (Àwọn Sadusi ni wọ́n sọ pé kò sí ajinde.) Wọ́n bi í pé,#A. Apo 23:8 24“Olùkọ́ni, Mose sọ pé bí ẹnìkan bá kú láì ní ọmọ, kí àbúrò rẹ̀ fẹ́ aya rẹ̀ kí ó lè bí ọmọ fún ẹ̀gbọ́n rẹ̀.#Diut 25:5 25Àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò meje kan wà lọ́dọ̀ wa. Ekinni gbé iyawo, láìpẹ́ ó kú. Nígbà tí kò bí ọmọ, ó fi iyawo rẹ̀ sílẹ̀ fún àbúrò rẹ̀. 26Ekeji náà kú, ati ẹkẹta, títí tí àwọn mejeeje fi kú. 27Ní ìkẹyìn gbogbo wọn, obinrin náà wá kú. 28Tí ó bá di àkókò ajinde, ninu àwọn mejeeje, iyawo ta ni obinrin náà yóo jẹ́, nígbà tí ó jẹ́ pé gbogbo wọn ni wọ́n ti fi ṣe aya?”
29Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ ṣìnà, nítorí pé ẹ kò mọ Ìwé Mímọ́ ati agbára Ọlọrun. 30Nítorí pé ní àkókò ajinde kò ní sí pé à ń gbé iyawo, tabi pé à ń fi ọmọ fún ọkọ; nítorí bí àwọn angẹli ti rí ní ọ̀run ni wọn yóo rí.#Ọgb 5:5 31Nípa ti ajinde àwọn òkú, ẹ kò ì tíì ka ọ̀rọ̀ tí Ọlọrun sọ fun yín pé, 32‘Èmi ni Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki ati Ọlọrun Jakọbu.’ Ọlọrun kì í ṣe Ọlọrun àwọn òkú, Ọlọrun àwọn alààyè ni.”#Eks 3:6
33Nígbà tí àwọn eniyan gbọ́, ẹnu yà wọ́n sí ẹ̀kọ́ rẹ̀.
Òfin tí Ó Ṣe Pataki Jùlọ
(Mak 12:28-34; Luk 10:25-28)
34Nígbà tí àwọn Farisi gbọ́ pé ó ti pa àwọn Sadusi lẹ́nu mọ́, wọ́n kó ara wọn jọ. 35Ọ̀kan ninu wọn tí ó jẹ́ amòfin, bi í ní ìbéèrè kan láti fi dẹ ẹ́, pé, 36“Olùkọ́ni, òfin wo ni ó ṣe pataki jùlọ ninu Ìwé Òfin?”
37Jesu dá a lóhùn pé, “ ‘Fẹ́ Oluwa Ọlọrun rẹ pẹlu gbogbo ọkàn rẹ, ati gbogbo ẹ̀mí rẹ, ati ní gbogbo èrò rẹ.’#Diut 6:5 38Èyí ni òfin tí ó ga jùlọ, òun sì ni ekinni. 39Ekeji fi ara jọ ọ́: ‘Fẹ́ràn ọmọnikeji rẹ bí o ti fẹ́ ara rẹ.’#Lef 19:18 40Òfin mejeeji wọnyi ni gbogbo òfin ìyókù ati ọ̀rọ̀ inú ìwé àwọn wolii rọ̀ mọ́.”
Ọ̀rọ̀ Iyàn lórí Ẹni tí Í Ṣe Ọmọ Dafidi
(Mak 12:35-37; Luk 20:41-44)#Luk 10:25-28
41Nígbà tí àwọn Farisi péjọ pọ̀, Jesu bi wọ́n pé, 42“Kí ni ẹ rò nípa Mesaya, ọmọ ta ni?”
Wọ́n dá a lóhùn pé, “Ọmọ Dafidi ni.”
43Ó bá tún bi wọ́n pé, “Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, báwo ni Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe darí Dafidi tí Dafidi fi pe Mesaya ní ‘Oluwa’? Dafidi sọ pé,
44‘OLUWA sọ fún Oluwa mi pé:
Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi
títí n óo fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ di ohun ìtìsẹ̀ rẹ.’#O. Daf 110:1
45Bí Dafidi bá pè é ní ‘OLUWA’, báwo ni Mesaya ti ṣe jẹ́ ọmọ rẹ̀?”
46Kò sí ẹnìkan tí ó lè dá a lóhùn ọ̀rọ̀ yìí. Láti ọjọ́ náà, ẹnikẹ́ni kò ní ìgboyà láti tún bi í ní ohunkohun mọ́.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

MATIU 22: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

Videos for MATIU 22