Mat 22:15-46

Mat 22:15-46 YBCV

Nigbana li awọn Farisi lọ, nwọn gbìmọ bi nwọn o ti ṣe ri ọ̀rọ gbámọ ọ li ẹnu. Nwọn si rán awọn ọmọ-ẹhin wọn pẹlu awọn ọmọ-ẹhin Herodu lọ sọdọ rẹ̀, wipe, Olukọni, awa mọ̀ pe olotitọ ni iwọ, iwọ̀ si nkọni li ọ̀na Ọlọrun li otitọ, bẹ̃ni iwọ ki iwoju ẹnikẹni: nitoriti iwọ kì iṣe ojuṣaju enia. Njẹ wi fun wa, Iwọ ti rò o si? Ó tọ́ lati mã san owode fun Kesari, tabi ko tọ́? Ṣugbọn Jesu mọ̀ ìro buburu wọn, o si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi ndán mi wò, ẹnyin agabagebe? Ẹ fi owodẹ kan hàn mi. Nwọn si mu owo idẹ kan tọ̀ ọ wá. O si bi wọn pe, Aworan ati akọle tali eyi? Nwọn wi fun u pe, Ti Kesari ni. Nigbana li o wi fun wọn pe, Njẹ ẹ fi ohun ti iṣe ti Kesari fun Kesari, ati ohun ti iṣe ti Ọlọrun fun Ọlọrun. Nigbati nwọn si ti gbọ́ ọ̀rọ wọnyi, ẹnu yà wọn, nwọn fi i silẹ, nwọn si ba tiwọn lọ. Ni ijọ kanna li awọn Sadusi tọ̀ ọ wá, awọn ti o wipe ajinde okú kò si, nwọn si bi i, Wipe, Olukọni, Mose wipe, Bi ẹnikan ba kú li ailọmọ, ki arakunrin rẹ̀ ki o ṣu aya rẹ̀ lopó, ki o le gbe irú dide fun arakunrin rẹ̀. Awọn arakunrin meje kan ti wà lọdọ wa: eyi ekini lẹhin igbati o gbé aya rẹ̀ ni iyawo, o kú, bi kò ti ni irúọmọ, o fi aya rẹ̀ silẹ fun arakunrin rẹ̀: Gẹgẹ bẹ̃li ekeji pẹlu, ati ẹkẹta titi o fi de ekeje. Nikẹhin gbogbo wọn, obinrin na kú pẹlu. Njẹ li ajinde oku, aya ti tani yio ha ṣe ninu awọn mejeje? nitori gbogbo wọn li o sá ni i. Jesu dahùn o si wi fun wọn pe, Ẹnyin ṣìna, nitori ẹnyin kò mọ̀ iwe-mimọ́, ẹ kò si mọ̀ agbara Ọlọrun. Nitoripe li ajinde okú, nwọn kì igbeyawo, a kì si fi wọn funni ni igbeyawo, ṣugbọn nwọn dabi awọn angẹli Ọlọrun li ọrun. Ṣugbọn niti ajinde okú, ẹnyin kò ti kà eyi ti a sọ fun nyin lati ọdọ Ọlọrun wá wipe, Emi li Ọlọrun Abrahamu, ati Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakọbu? Ọlọrun ki iṣe Ọlọrun awọn okú, bikoṣe ti awọn alãye. Nigbati awọn enia gbọ́ eyi, ẹnu yà wọn si ẹkọ́ rẹ̀. Ṣugbọn nigbati awọn Farisi gbọ́ pe, o pa awọn Sadusi li ẹnu mọ́, nwọn pè ara wọn jọ. Nigbana li ọkan ninu wọn, ti iṣe amofin, ndán a wò, o si bi i lẽre ọ̀rọ kan, wipe, Olukọni, ewo li aṣẹ nla ninu ofin? Jesu si wi fun u pe, Ki iwọ ki o fi gbogbo àiya rẹ, ati gbogbo ọkàn rẹ, ati gbogbo inu rẹ, fẹ́ Ọlọrun Oluwa rẹ. Eyi li ekini ati ofin nla. Ekeji si dabi rẹ̀, Iwọ fẹ ọmọnikeji rẹ bi ara rẹ. Ninu awọn ofin mejeji yi ni gbogbo ofin ati wolĩ rọ̀ mọ́. Bi awọn Farisi ti kó ara wọn jọ, Jesu bi wọn, Wipe, Ẹnyin ti rò ti Kristi si? ọmọ tani iṣe? Nwọn wi fun u pe, Ọmọ Dafidi ni. O wi fun wọn pe, Ẽha ti ṣe ti Dafidi nipa ẹmí fi npè e li Oluwa, wipe, OLUWA wi fun Oluwa mi pe, Iwọ joko li ọwọ́ ọtún mi, titi emi o fi sọ awọn ọtá rẹ di apoti itisẹ rẹ? Njẹ bi Dafidi ba npè e li Oluwa, ẽha ti ri ti o fi ṣe ọmọ rẹ̀? Kò si si ẹnikan ti o le da a li ohùn ọ̀rọ kan, bẹ̃ni kò si ẹniti o jẹ bi i lẽre ohun kan mọ́ lati ọjọ na lọ.

Àwọn fídíò fún Mat 22:15-46