ẸKÚN JEREMAYA 3:31-33

ẸKÚN JEREMAYA 3:31-33 YCE

Nítorí OLUWA kò ní ta wá nù títí lae. Bí ó tilẹ̀ mú kí ìbànújẹ́ dé bá wa, yóo ṣàánú wa, yóo tù wá ninu, gẹ́gẹ́ bí ọpọlọpọ ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀. Nítorí pé kì í kàn déédé ni eniyan lára tabi kí ó mú ìbànújẹ́ dé bá eniyan láìní ìdí.