Èmi ni mo mọ bí eniyan tií rí ìpọ́njú,
tí mo mọ bí Ọlọrun tií fi ibinu na eniyan ní pàṣán.
Ó lé mi wọ inú òkùnkùn biribiri.
Dájúdájú, ó ti dojú kọ mí,
ó sì bá mi jà léraléra tọ̀sán-tòru.
Ó ti jẹ́ kí n rù kan egungun,
ó sì ti fọ́ egungun mi.
Ó dótì mí,
ó fi ìbànújẹ́ ati ìṣẹ́ yí mi káàkiri.
Ó fi mí sinu òkùnkùn
bí òkú tí ó ti kú láti ọjọ́ pípẹ́.
Ó mọ odi yí mi ká,
ó sì fi ẹ̀wọ̀n wúwo dè mí,
kí n má baà lè sálọ.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ké pè é fún ìrànlọ́wọ́,
sibẹsibẹ kò gbọ́ adura mi.
Ó to òkúta gbígbẹ́ dí ọ̀nà mi,
ó mú kí ọ̀nà mí wọ́.
Ó ba dè mí bí ẹranko ìjàkùmọ̀,
ó lúgọ bíi kinniun,
Ó wọ́ mi kúrò lójú ọ̀nà mi,
ó fà mí ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ,
ó sì ti sọ mí di alailẹnikan.
Ó kẹ́ ọfà, ó fa ọrun rẹ̀,
ó sì fi mí ṣe ohun ìtafàsí.
Ó mú gbogbo ọfà
tí ó wà ninu apó rẹ̀
ó ta wọ́n mọ́ mi lọ́kàn.
Mo wá di ẹni yẹ̀yẹ́
lọ́dọ̀ gbogbo eniyan,
ẹni tí wọ́n fi ń kọrin tọ̀sán-tòru.
Ó mú kí ọkàn mi kún fún ìbànújẹ́,
ó fún mi ní iwọ mu ní àmuyó.
Ó fẹnu mi gbolẹ̀,
títí yangí fi ká mi léyín;
ó gún mi mọ́lẹ̀ ninu eruku
Ọkàn mi kò ní alaafia,
mo ti gbàgbé ohun tí ń jẹ́ ayọ̀.
Nítorí náà, mo wí pé,
“Ògo mi ti tán,
ati gbogbo ohun tí mò ń retí lọ́dọ̀ OLUWA.”
Ranti ìyà ati ìbànújẹ́ mi,
ati ìrora ọkàn mi!
Mò ń ranti nígbà gbogbo,
ọkàn mi sì ń rẹ̀wẹ̀sì.
Ṣugbọn mo tún ń ranti nǹkankan,
mo sì ní ìrètí.
Nítorí pé Ìfẹ́ OLUWA tí kì í yẹ̀ kò nípẹ̀kun,
àánú rẹ̀ kò sì lópin;
ọ̀tun ni wọ́n láràárọ̀,
òtítọ́ rẹ̀ pọ̀.
Ọkàn mi wí pé, “OLUWA ni ìpín mi,
nítorí náà lọ́dọ̀ rẹ̀ ni ìrètí mi wà.”
OLUWA a máa ṣe oore fún àwọn tí wọn dúró dè é,
tí wọn sì ń wá ojurere rẹ̀.
Ó dára kí eniyan dúró jẹ́ẹ́, de ìgbàlà OLUWA.
Ó dára kí eniyan foríti àjàgà ìtọ́sọ́nà ní ìgbà èwe.
Kí ó fi ọwọ́ lẹ́rán, kí ó dákẹ́, kí ó sì máa wòye,
nítorí Ọlọrun ni ó gbé àjàgà náà kọ́ ọ lọ́rùn.
Kí ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀,
bóyá ìrètí lè tún wà fún un.
Kí ó kọ etí rẹ̀ sí ẹni tí ó fẹ́ gbá a létí,
kí wọ́n sì fi àbùkù kàn án.
Nítorí OLUWA kò ní ta wá nù títí lae.
Bí ó tilẹ̀ mú kí ìbànújẹ́ dé bá wa,
yóo ṣàánú wa, yóo tù wá ninu,
gẹ́gẹ́ bí ọpọlọpọ ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀.
Nítorí pé kì í kàn déédé ni eniyan lára
tabi kí ó mú ìbànújẹ́ dé bá eniyan láìní ìdí.
OLUWA kò faramọ́ pé kí á máa ni àwọn ẹlẹ́wọ̀n lára lórí ilẹ̀ ayé,
kí á máa já ẹ̀tọ́ olódodo gbà lọ́wọ́ rẹ̀ níwájú Ọ̀gá Ògo,
tabi kí á du eniyan ní ìdájọ́ òdodo.