Ẹk. Jer 3:1-36

Ẹk. Jer 3:1-36 Yoruba Bible (YCE)

Èmi ni mo mọ bí eniyan tií rí ìpọ́njú, tí mo mọ bí Ọlọrun tií fi ibinu na eniyan ní pàṣán. Ó lé mi wọ inú òkùnkùn biribiri. Dájúdájú, ó ti dojú kọ mí, ó sì bá mi jà léraléra tọ̀sán-tòru. Ó ti jẹ́ kí n rù kan egungun, ó sì ti fọ́ egungun mi. Ó dótì mí, ó fi ìbànújẹ́ ati ìṣẹ́ yí mi káàkiri. Ó fi mí sinu òkùnkùn bí òkú tí ó ti kú láti ọjọ́ pípẹ́. Ó mọ odi yí mi ká, ó sì fi ẹ̀wọ̀n wúwo dè mí, kí n má baà lè sálọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ké pè é fún ìrànlọ́wọ́, sibẹsibẹ kò gbọ́ adura mi. Ó to òkúta gbígbẹ́ dí ọ̀nà mi, ó mú kí ọ̀nà mí wọ́. Ó ba dè mí bí ẹranko ìjàkùmọ̀, ó lúgọ bíi kinniun, Ó wọ́ mi kúrò lójú ọ̀nà mi, ó fà mí ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, ó sì ti sọ mí di alailẹnikan. Ó kẹ́ ọfà, ó fa ọrun rẹ̀, ó sì fi mí ṣe ohun ìtafàsí. Ó mú gbogbo ọfà tí ó wà ninu apó rẹ̀ ó ta wọ́n mọ́ mi lọ́kàn. Mo wá di ẹni yẹ̀yẹ́ lọ́dọ̀ gbogbo eniyan, ẹni tí wọ́n fi ń kọrin tọ̀sán-tòru. Ó mú kí ọkàn mi kún fún ìbànújẹ́, ó fún mi ní iwọ mu ní àmuyó. Ó fẹnu mi gbolẹ̀, títí yangí fi ká mi léyín; ó gún mi mọ́lẹ̀ ninu eruku Ọkàn mi kò ní alaafia, mo ti gbàgbé ohun tí ń jẹ́ ayọ̀. Nítorí náà, mo wí pé, “Ògo mi ti tán, ati gbogbo ohun tí mò ń retí lọ́dọ̀ OLUWA.” Ranti ìyà ati ìbànújẹ́ mi, ati ìrora ọkàn mi! Mò ń ranti nígbà gbogbo, ọkàn mi sì ń rẹ̀wẹ̀sì. Ṣugbọn mo tún ń ranti nǹkankan, mo sì ní ìrètí. Nítorí pé Ìfẹ́ OLUWA tí kì í yẹ̀ kò nípẹ̀kun, àánú rẹ̀ kò sì lópin; ọ̀tun ni wọ́n láràárọ̀, òtítọ́ rẹ̀ pọ̀. Ọkàn mi wí pé, “OLUWA ni ìpín mi, nítorí náà lọ́dọ̀ rẹ̀ ni ìrètí mi wà.” OLUWA a máa ṣe oore fún àwọn tí wọn dúró dè é, tí wọn sì ń wá ojurere rẹ̀. Ó dára kí eniyan dúró jẹ́ẹ́, de ìgbàlà OLUWA. Ó dára kí eniyan foríti àjàgà ìtọ́sọ́nà ní ìgbà èwe. Kí ó fi ọwọ́ lẹ́rán, kí ó dákẹ́, kí ó sì máa wòye, nítorí Ọlọrun ni ó gbé àjàgà náà kọ́ ọ lọ́rùn. Kí ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, bóyá ìrètí lè tún wà fún un. Kí ó kọ etí rẹ̀ sí ẹni tí ó fẹ́ gbá a létí, kí wọ́n sì fi àbùkù kàn án. Nítorí OLUWA kò ní ta wá nù títí lae. Bí ó tilẹ̀ mú kí ìbànújẹ́ dé bá wa, yóo ṣàánú wa, yóo tù wá ninu, gẹ́gẹ́ bí ọpọlọpọ ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀. Nítorí pé kì í kàn déédé ni eniyan lára tabi kí ó mú ìbànújẹ́ dé bá eniyan láìní ìdí. OLUWA kò faramọ́ pé kí á máa ni àwọn ẹlẹ́wọ̀n lára lórí ilẹ̀ ayé, kí á máa já ẹ̀tọ́ olódodo gbà lọ́wọ́ rẹ̀ níwájú Ọ̀gá Ògo, tabi kí á du eniyan ní ìdájọ́ òdodo.

Ẹk. Jer 3:1-36 Bibeli Mimọ (YBCV)

EMI ni ọkunrin na ti o ti ri wàhala nipa ọpa ibinu rẹ̀. O ti fà mi, o si mu mi wá sinu òkunkun, kì si iṣe sinu imọlẹ. Lõtọ, o yi ọwọ rẹ̀ pada si mi siwaju ati siwaju li ọjọ gbogbo. O ti sọ ẹran-ara mi ati àwọ mi di ogbó, o ti fọ́ egungun mi. O ti mọdi tì mi, o fi orõrò ati ãrẹ̀ yi mi ka. O ti fi mi si ibi òkunkun, bi awọn ti o ti kú pẹ. O ti sọgba yi mi ka, ti emi kò le jade; o ti ṣe ẹ̀wọn mi wuwo. Bi emi ti kigbe pẹlu, ti emi si npariwo, o sé adura mi mọ. O ti fi okuta gbigbẹ sọgba yi ọ̀na mi ka, o ti yi ipa ọ̀na mi po. On jẹ bi ẹranko beari ti o ba dè mi, bi kiniun ni ibi ìkọkọ. O ti mu mi ṣina li ọ̀na mi, o si fà mi ya pẹrẹpẹrẹ: o ti sọ mi di ahoro. O ti fà ọrun rẹ̀, o si fi mi ṣe itasi fun ọfa rẹ̀. O ti mu ki ọfà apó rẹ̀ wọ inu-ẹdọ mi lọ. Emi jẹ ẹni ẹsin fun gbogbo enia mi; orin wọn ni gbogbo ọjọ. O ti fi ìkoro mu mi yo, o ti mu mi mu omi wahala. O ti fi ọta ṣẹ́ ehín mi, o tẹ̀ mi mọlẹ ninu ẽru. Iwọ si ti mu ọkàn mi jina réré si alafia; emi gbagbe rere. Emi si wipe, Agbara mi ati ireti mi ṣègbe kuro lọdọ Oluwa. Ranti wahala mi ati inilara mi, ani ìkoro ati orõro. Lõtọ, nigbati ọkàn mi nṣe iranti wọn, o si tẹriba ninu mi. Eyi ni emi o rò li ọkàn mi, nitorina emi o ma reti. Ãnu Oluwa ni, ti awa kò parun tan, nitori irọnu-ãnu rẹ kò li opin. Ọtun ni li orowurọ; titobi ni otitọ rẹ. Oluwa ni ipin mi, bẹ̃li ọkàn mi wi; nitorina ni emi ṣe reti ninu rẹ̀. Oluwa ṣe rere fun gbogbo ẹniti o duro dè e, fun ọkàn ti o ṣafẹri rẹ̀. O dara ti a ba mã reti ni idakẹjẹ fun igbala Oluwa. O dara fun ọkunrin, ki o gbe àjaga ni igba-ewe rẹ̀. Ki o joko on nikan, ki o si dakẹ, nitori Ọlọrun ti gbe e le ori rẹ̀. Ki o fi ẹnu rẹ̀ sinu ẽkuru; pe bọya ireti le wà: Ki o fi ẹ̀rẹkẹ fun ẹniti o lù u; ki o kún fun ẹ̀gan patapata. Nitoriti Oluwa kì yio ṣá ni tì lailai: Bi o tilẹ mu ibanujẹ wá, sibẹ on o ni irọnu gẹgẹ bi ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ̀. Nitori on kì ifẹ ipọn-ni-loju lati ọkàn rẹ̀ wá, bẹ̃ni kì ibà ọmọ enia ninu jẹ. Lati tẹ̀ gbogbo ara-tubu ilẹ-aiye mọlẹ li abẹ ẹsẹ rẹ̀. Lati yi ẹ̀tọ enia sapakan niwaju Ọga-ogo julọ. Lati yi ọ̀ran idajọ enia pada, Oluwa kò fẹ ri i?

Ẹk. Jer 3:1-36 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Èmi ni ọkùnrin tí ó rí ìpọ́njú pẹ̀lú ọ̀pá ìbínú rẹ. Ó ti lé mi jáde ó sì mú mi rìn nínú òkùnkùn ju ti ìmọ́lẹ̀; Nítòótọ́, ó ti yí ọwọ́ padà sí mi síwájú àti síwájú sí i ní gbogbo ọjọ́. Ó jẹ́ kí àwọ̀ mi àti ẹran-ara mi gbó ó sì tún ṣẹ́ egungun mi. Ó ti fi mí sí ìgbèkùn, ó sì ti yí mi ká pẹ̀lú ìkorò àti làálàá. Ó mú mi gbé nínú òkùnkùn, bí ti àwọn tó ti kú fún ìgbà pípẹ́. Ó ti tì mí mọ́ ilé, nítorí náà n kò le è sálọ; ó ti fi ẹ̀wọ̀n mú mi mọ́lẹ̀. Pàápàá nígbà tí mo ké fún ìrànlọ́wọ́, ó kọ àdúrà mi. Ó fi ògiri òkúta dí ọ̀nà mi; ó sì mú ọ̀nà mi wọ́. Bí i beari tí ó dùbúlẹ̀, bí i kìnnìún tí ó sápamọ́. Ó wọ́ mi kúrò ní ọ̀nà, ó tẹ̀ mí mọ́lẹ̀ ó fi mi sílẹ̀ láìsí ìrànlọ́wọ́. Ó fa ọfà rẹ̀ yọ ó sì fi mí ṣe ohun ìtafàsí. Ó fa ọkàn mí ya pẹ̀lú ọfà nínú àkọ̀ rẹ̀. Mo di ẹni yẹ̀yẹ́ láàrín àwọn ènìyàn mi; wọn yẹ̀yẹ́ mi pẹ̀lú orin ní gbogbo ọjọ́. Ó ti kún mi pẹ̀lú ewé kíkorò àti ìdààmú bí omi. Ó ti fi òkúta kán eyín mi; ó ti tẹ̀ mí mọ́lẹ̀ nínú eruku. Mo ti jìnnà sí àlàáfíà; mo ti gbàgbé ohun tí àṣeyege ń ṣe. Nítorí náà mo wí pé, “Ògo mi ti lọ àti ìrètí mi nínú OLúWA.” Mo ṣe ìrántí ìpọ́njú àti ìdààmú mi, ìkorò àti ìbànújẹ́. Mo ṣèrántí wọn, ọkàn mi sì gbọgbẹ́ nínú mi. Síbẹ̀, èyí ni mo ní ní ọkàn àti nítorí náà ní mo nírètí. Nítorí ìfẹ́ OLúWA tí ó lágbára ni àwa kò fi ṣègbé, nítorí ti àánú rẹ kì í kùnà. Wọ́n jẹ́ ọ̀tún ní àárọ̀; títóbi ni òdodo rẹ̀. Mo wí fún ara mi, ìpín mi ni OLúWA; nítorí náà èmi yóò dúró dè ọ́. Dídára ni OLúWA fún àwọn tí ó ní ìrètí nínú rẹ̀, sí àwọn tí ó ń wá a. Ó dára kí a ní sùúrù fún ìgbàlà OLúWA. Ó dára fún ènìyàn láti gbé àjàgà nígbà tí ó wà ní èwe. Jẹ́ kí ó jókòó ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́, nítorí OLúWA ti fi fún un. Jẹ́ kí ó bo ojú rẹ̀ sínú eruku— ìrètí sì lè wà. Jẹ́ kí ó fi ẹ̀rẹ̀kẹ́ fún àwọn tí yóò gbá a, sì jẹ́ kí ó wà ní ìdójútì. Ènìyàn kò di ìtanù lọ́dọ̀ Olúwa títí láé. Lóòtítọ́ ó mú ìbànújẹ́ wá, yóò fi àánú hàn, nítorí títóbi ni ìfẹ́ rẹ̀. Nítorí kò mọ̀ ọ́n mọ̀ mú ìpọ́njú wá tàbí ìrora wá fún ọmọ ènìyàn. Láti tẹ mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ gbogbo àwọn ẹlẹ́wọ̀n ní ilẹ̀ náà. Láti ṣẹ́ ọmọ ènìyàn fún ẹ̀tọ́ rẹ̀ níwájú Ọ̀gá-ògo jùlọ. Láti yí ìdájọ́ ènìyàn padà, Ǹjẹ́ Olúwa kò rí ohun bẹ́ẹ̀.