JOṢUA 6:16-17

JOṢUA 6:16-17 YCE

Nígbà tí ó di ẹẹkeje, lẹ́yìn tí àwọn alufaa fọn fèrè wọn, Joṣua pàṣẹ fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ hó yèè! Nítorí OLUWA ti fi ìlú yìí le yín lọ́wọ́. OLUWA ti yà á sọ́tọ̀ fún ìparun, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀, àfi Rahabu, aṣẹ́wó, ati àwọn tí wọ́n wà ninu ilé pẹlu rẹ̀, ni yóo wà láàyè; nítorí òun ni ó gbé àwọn amí tí a rán pamọ́.