Joṣ 6:16-17
Joṣ 6:16-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si ṣe ni ìgba keje, nigbati awọn alufa fọn ipè, ni Joṣua wi fun awọn enia pe, Ẹ hó; nitoriti OLUWA ti fun nyin ni ilu na. Ilu na yio si jẹ́ ìyasọtọ si OLUWA, on ati gbogbo ohun ti mbẹ ninu rẹ̀: kìki Rahabu panṣaga ni yio là, on ati gbogbo awọn ti mbẹ ni ile pẹlu rẹ̀, nitoriti o pa awọn onṣẹ ti a rán mọ́.
Joṣ 6:16-17 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ó di ẹẹkeje, lẹ́yìn tí àwọn alufaa fọn fèrè wọn, Joṣua pàṣẹ fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ hó yèè! Nítorí OLUWA ti fi ìlú yìí le yín lọ́wọ́. OLUWA ti yà á sọ́tọ̀ fún ìparun, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀, àfi Rahabu, aṣẹ́wó, ati àwọn tí wọ́n wà ninu ilé pẹlu rẹ̀, ni yóo wà láàyè; nítorí òun ni ó gbé àwọn amí tí a rán pamọ́.
Joṣ 6:16-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ìgbà keje, nígbà tí àwọn àlùfáà fọn fèrè, Joṣua pàṣẹ fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ hó! Nítorí pé OLúWA ti fún un yín ní ìlú náà. Ìlú náà àti gbogbo ohun tí ó wà níbẹ̀ ni yóò jẹ́ ìyàsọ́tọ̀ fún OLúWA. Rahabu tí ó jẹ́ panṣágà nìkan àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú u rẹ̀ ni a ó dá sí; nítorí tí ó pa àwọn ayọ́lẹ̀wò tí á rán mọ́.