JOṢUA 20
20
Àwọn Ìlú Ààbò
1Lẹ́yìn náà, OLUWA sọ fún Joṣua pé, 2“Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kí wọ́n yan àwọn ìlú ààbò tí mo bá Mose sọ nípa rẹ̀, pé kí ó sọ fun yín. 3Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣèèṣì pa eniyan lè sá lọ sibẹ. Ibẹ̀ ni yóo jẹ́ ibi ààbò fun yín tí ọwọ́ ẹni tí ń gbẹ̀san ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ kò fi ní máa tẹ̀ yín. 4Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣèèṣì pa eniyan sá lọ sí ọ̀kan ninu àwọn ìlú ọ̀hún, kí ó dúró ní ẹnubodè ìlú, kí ó sì ro ẹjọ́ fún àwọn àgbààgbà ibẹ̀. Wọn yóo mú un wọ inú ìlú lọ, wọn yóo fún un ní ibi tí yóo máa gbé, yóo sì wà ní ọ̀dọ̀ wọn. 5Bí ẹni tí ń gbẹ̀san ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ bá ń lé e bọ̀, wọn kò ní fi lé e lọ́wọ́, nítorí pé ó ṣèèṣì pa aládùúgbò rẹ̀ ni, kò sì ní ìkùnsínú sí i tẹ́lẹ̀. 6Ìlú yìí ni yóo máa gbé títí tí àwọn ìgbìmọ̀ yóo fi ṣe ìdájọ́ rẹ̀, yóo máa gbé ibẹ̀ títí tí ẹni tí ó jẹ́ olórí alufaa ní àkókò náà yóo fi kú, lẹ́yìn náà ẹni tí ó ṣèèṣì pa eniyan yìí lè pada lọ sí ilé rẹ̀ ati sí ìlú rẹ̀ níbi tí ó ti sá wá.”
7Wọ́n ya Kedeṣi sọ́tọ̀ ní Galili ní agbègbè olókè ti Nafutali, ati Ṣekemu ní agbègbè olókè ti Efuraimu, ati Kiriati Ariba (tí wọ́n ń pè ní Heburoni), ní agbègbè olókè ti Juda. 8Ní òdìkejì odò Jọdani, ní apá ìlà oòrùn Jẹriko, wọ́n ya Beseri tí ó wà ninu aṣálẹ̀ ní ilẹ̀ tí ó tẹ́jú sọ́tọ̀. Wọ́n ya Ramoti tí ó wà ní Gileadi sọ́tọ̀ ní agbègbè ti ẹ̀yà Gadi, ati Golani tí ó wà ní Baṣani, ní agbègbè ti ẹ̀yà Manase. 9Àwọn ìlú ọ̀hún ni ìlú ààbò tí wọ́n yàn fún àwọn ọmọ Israẹli, ati fún àwọn àlejò tí wọ́n ń gbé ààrin wọn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣèèṣì pa eniyan lè sá lọ sí èyíkéyìí ninu wọn, yóo sì bọ́ lọ́wọ́ ẹni tí ń gbẹ̀san ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ títí tí àwọn ìgbìmọ̀ yóo fi ṣe ìdájọ́ rẹ̀.#Nọm 35:9-34; Diut 4:41-43; 19:1-13.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
JOṢUA 20: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010