JOṢUA 19

19
Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Ẹ̀yà Simeoni
1Ilẹ̀ keji tí wọ́n ṣẹ́ gègé lé lórí bọ́ sí ọwọ́ ẹ̀yà Simeoni, ilẹ̀ tiwọn bọ́ sí ààrin ìpín ti ẹ̀yà Juda. 2Àwọn ìlú tí ó wà ninu ilẹ̀ tí wọ́n pín fún wọn nìyí: Beeriṣeba, Ṣeba, Molada; 3Hasari Ṣuali, Bala, Esemu; 4Elitoladi, Betuli, Horima, 5Sikilagi, Beti Makabotu, ati Hasari Susa; 6Beti Lebaotu ati Ṣaruheni, gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mẹtala.
7Enrimoni, Eteri, ati Aṣani, gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mẹrin, 8pẹlu gbogbo àwọn ìletò tí ó yí àwọn ìlú ńláńlá wọnyi ká títí dé Baalati Beeri, (tí wọ́n ń pè ní Rama) tí ó wà ní Nẹgẹbu ní ìhà gúsù. Òun ni ìpín ti ẹ̀yà Simeoni, gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn. 9Apá kan ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Juda jẹ́ ìpín ti ẹ̀yà Simeoni. Ìpín ti ẹ̀yà Juda tóbi jù fún wọn, nítorí náà ni ẹ̀yà Simeoni ṣe mú ninu tiwọn.#1Kron 4:28-33
Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Ẹ̀yà Sebuluni
10Ilẹ̀ kẹta tí wọ́n ṣẹ́ gègé lé lórí bọ́ sí ọwọ́ ẹ̀yà Sebuluni. Agbègbè tí ó jẹ́ ìpín tiwọn lọ títí dé Saridi. 11Níbẹ̀ ni ààlà ilẹ̀ wọn ti yípo lọ sókè sí apá ìwọ̀ oòrùn, ó sì wá sí apá ìlà oòrùn Jokineamu. 12Láti Saridi, ààlà ilẹ̀ náà lọ sí òdìkejì, ní ìhà ìlà oòrùn, títí dé ààlà Kisiloti Tabori, láti ibẹ̀, ó lọ sí Daberati títí lọ sí Jafia; 13láti Jafia, ó lọ sí apá ìlà oòrùn títí dé Gati Heferi ati Etikasini, nígbà tí ó dé Rimoni, ó yípo lọ sí apá Nea. 14Ní apá ìhà àríwá, ààlà náà yípo lọ sí Hanatoni, ó sì pin sí àfonífojì Ifitaeli. 15Ara àwọn ìlú tí ó wà níbẹ̀ ni, Kata, Nahalali, Ṣimironi, Idala, ati Bẹtilẹhẹmu, gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mejila. 16Àwọn ni ìlú ati ìletò tí ó wà ninu ilẹ̀ tí ó kan ẹ̀yà Sebuluni gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn.
Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Ẹ̀yà Isakari
17Ilẹ̀ kẹrin tí wọ́n ṣẹ́ gègé lé lórí bọ́ sí ọwọ́ ẹ̀yà Isakari. 18Lórí ilẹ̀ náà ni àwọn ìlú wọnyi wà: Jesireeli, Kesuloti, Ṣunemu; 19Hafaraimu, Sihoni, Anaharati; 20Rabiti, Kiṣioni, Ebesi; 21Remeti, Enganimu, Enhada, ati Betipasesi. 22Ààlà ilẹ̀ náà lọ kan Tabori, Ṣahasuma ati Beti Ṣemeṣi, kí ó tó lọ pin sí odò Jọdani. Gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mẹrindinlogun. 23Àwọn ni ìlú ati ìletò náà tí ó wà ninu ilẹ̀ tí ó kan ẹ̀yà Isakari gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn.
Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Aṣeri
24Ilẹ̀ karun-un tí wọ́n ṣẹ́ gègé lé lórí bọ́ sí ọwọ́ ẹ̀yà Aṣeri. 25Ninu ilẹ̀ náà ni àwọn ìlú wọnyi wà: Helikati, Hali, Beteni, Akiṣafu. 26Alameleki, Amadi, ati Miṣali, ní apá ìwọ̀ oòrùn, ilẹ̀ náà dé Kamẹli ati Ṣihori Libinati. 27Ààlà rẹ̀ wá yípo lọ sí apá ìlà oòrùn, títí dé Beti Dagoni, títí dé Sebuluni ati àfonífojì Ifitaeli ní apá àríwá Betemeki ati Neieli. Lẹ́yìn náà ó tún lọ ní apá ìhà àríwá náà títí dé Kabulu, 28Eburoni, Rehobu, Hamoni, ati Kana, títí dé Sidoni Ńlá; 29Lẹ́yìn náà, ààlà náà yípo lọ sí Rama; ó dé ìlú olódi ti Tire, lẹ́yìn náà, ó yípo lọ sí Hosa, ó sì pin sí etíkun. Ninu ilẹ̀ wọn ni Mahalabu, Akisibu; 30Uma, Afeki, ati Rehobu wà, gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mejilelogun. 31Àwọn ni ìlú ati ìletò tí ó wà ninu ilẹ̀ tí ó kan ẹ̀yà Aṣeri gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn.
Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Nafutali
32Ilẹ̀ kẹfa tí wọ́n ṣẹ́ gègé lé lórí bọ́ sí ọwọ́ ẹ̀yà Nafutali, 33Ààlà ilẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀ ní Helefi, láti ibi igi oaku tí ó wà ní Saananimu, Adaminekebu, ati Jabineeli, títí dé Lakumu, ó sì pin sí odò Jọdani. 34Níbẹ̀ ni ààlà náà ti yipada lọ sí apá ìwọ̀ oòrùn sí Asinotu Tabori. Láti ibẹ̀, ó lọ títí dé Hukoku, ó lọ kan ilẹ̀ ẹ̀yà Sebuluni ní apá ìhà gúsù, ó sì kan ilẹ̀ ẹ̀yà Aṣeri lápá ìwọ̀ oòrùn, ati ti Juda ní apá ìlà oòrùn létí odò Jọdani. 35Àwọn ìlú olódi tí ó wà ní ilẹ̀ náà ni Sidimu, Seri, Hamati, Rakati, Kinereti; 36Adama, Rama, Hasori; 37Kedeṣi, Edirei, Enhasoru, 38Yironi, Migidalieli, Horemu, Betanati ati Beti Ṣemeṣi, gbogbo ìlú ati àwọn ìletò wọn jẹ́ mọkandinlogun. 39Àwọn ni ìlú ati ìletò tí ó wà ninu ilẹ̀ tí ó kan ẹ̀yà Nafutali gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn.
Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Dani
40Ilẹ̀ keje tí wọ́n ṣẹ́ gègé lé lórí bọ́ sí ọwọ́ ẹ̀yà Dani. 41Ninu ilẹ̀ náà ni àwọn ìlú wọnyi wà: Sora, Ẹṣitaolu, Iriṣemeṣi; 42Ṣaalibimu, Aijaloni, Itila, 43Eloni, Timna, Ekironi, 44Eliteke, Gibetoni, Baalati; 45Jehudi, Beneberaki, Gati Rimoni 46ati Mejakoni, ati Rakoni pẹlu agbègbè tí ó dojú kọ Jọpa. 47Nígbà tí ilẹ̀ ẹ̀yà Dani bọ́ mọ́ wọn lọ́wọ́, wọ́n bá lọ gbógun ti ìlú Leṣemu, wọ́n ṣẹgun wọn, wọ́n pa wọ́n, wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn. Wọ́n yí orúkọ Leṣemu pada sí Dani, tíí ṣe orúkọ baba ńlá wọn, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀. 48Àwọn ìlú ati àwọn ìletò wọnyi ni ìpín tí ó kan ẹ̀yà Dani gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn.#A. Ada 18:27-29.
Pípín Ilẹ̀ Tí Ó Kù
49Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli pín gbogbo agbègbè tí ó wà ninu ilẹ̀ náà ní ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan tán, wọ́n pín ilẹ̀ fún Joṣua ọmọ Nuni pẹlu. 50Wọ́n fún un ní ilẹ̀ tí ó bèèrè fún gẹ́gẹ́ bí àṣẹ OLUWA. Ìlú tí ó bèèrè fún ni Timnati Sera ní agbègbè olókè ti Efuraimu, ó tún ìlú náà kọ́, ó sì ń gbé ibẹ̀.
51Bẹ́ẹ̀ ni Eleasari alufaa ati Joṣua ọmọ Nuni ati àwọn àgbààgbà ninu ẹ̀yà àwọn eniyan Israẹli ṣe ṣẹ́ gègé láti pín ilẹ̀ náà ní Ṣilo níwájú OLUWA, ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé; wọ́n sì parí pípín ilẹ̀ náà.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

JOṢUA 19: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀