JOṢUA 21

21
Ìlú Àwọn Ọmọ Lefi
1Lẹ́yìn náà àwọn olórí ìdílé ninu ẹ̀yà Lefi wá sí ọ̀dọ̀ Eleasari alufaa, ati sí ọ̀dọ̀ Joṣua ọmọ Nuni, ati àwọn olórí ìdílé ní gbogbo ẹ̀yà Israẹli, 2ní Ṣilo ní ilẹ̀ Kenaani, wọ́n sọ fún wọn pé, “OLUWA ti pàṣẹ láti ẹnu Mose pé kí wọ́n fún wa ní ìlú tí a óo máa gbé ati pápá oko fún àwọn ẹran ọ̀sìn wa.” 3Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ OLUWA, àwọn ọmọ Israẹli fún àwọn ọmọ Lefi ní àwọn ìlú ati pápá tí ó yí wọn ká, ninu ilẹ̀ ìní wọn.#Nọm 35:1-8.
4Ilẹ̀ kinni tí wọ́n kọ́kọ́ ṣẹ́ gègé lé lórí bọ́ sí ọwọ́ àwọn ọmọ Kohati. Nítorí náà, gbogbo àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n jẹ́ ìran Aaroni alufaa gba ìlú mẹtala lọ́wọ́ àwọn ẹ̀yà Juda, ẹ̀yà Simeoni, ati ẹ̀yà Bẹnjamini. 5Àwọn ọmọ Kohati yòókù sì gba ìlú mẹ́wàá lọ́wọ́ àwọn ẹ̀yà Efuraimu, ẹ̀yà Dani, ati ìdajì ẹ̀yà Manase.
6Àwọn ọmọ Geriṣoni gba ìlú mẹtala lọ́wọ́ àwọn ẹ̀yà Isakari, ẹ̀yà Aṣeri, ẹ̀yà Nafutali, ati ìdajì ẹ̀yà Manase tí wọ́n wà ní Baṣani.
7Àwọn ọmọ Merari gba ìlú mejila lọ́wọ́ àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ẹ̀yà Gadi ati ẹ̀yà Sebuluni.
8Àwọn ìlú náà ati pápá oko wọn ni àwọn ọmọ Israẹli fún àwọn ọmọ Lefi, lẹ́yìn tí wọ́n ti ṣẹ́ gègé lé wọn lórí, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ láti ẹnu Mose.
9Àwọn ẹ̀yà Juda ati ẹ̀yà Simeoni fi àwọn ìlú náà sílẹ̀ fún àwọn ọmọ Lefi, 10tí wọ́n jẹ́ ọmọ Kohati, tíí ṣe ìran Aaroni, nítorí pé àwọn ni gègé kọ́kọ́ mú. 11Àwọn ni wọ́n fún ní Kiriati Ariba tí wọ́n ń pè ní ìlú Heburoni lónìí, (Ariba yìí ni baba Anaki), ati àwọn pápá ìdaran tí wọ́n wà ní àyíká rẹ̀ ní agbègbè olókè ti Juda. 12Ṣugbọn àwọn oko tí wọ́n yí ìlú náà ká ati àwọn ìletò rẹ̀ ni wọ́n fi fún Kalebu ọmọ Jefune gẹ́gẹ́ bí ìpín tirẹ̀.
13Àwọn ọmọ Aaroni, alufaa, ni wọ́n fún ní ìlú Heburoni, tíí ṣe ìlú ààbò fún àwọn tí wọ́n bá ṣèèṣì pa eniyan, pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká rẹ̀, ati ìlú Libina pẹlu àwọn pápá ìdaran tí wọ́n wà ní àyíká rẹ̀. 14Ati àwọn ìlú wọnyi pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn: Jatiri, Eṣitemoa, 15Holoni, Debiri; 16Aini, Juta, ati Beti Ṣemeṣi, gbogbo wọn jẹ́ ìlú mẹsan-an ní ààrin ilẹ̀ àwọn ẹ̀yà mejeeji. 17Láàrin ilẹ̀ ẹ̀yà Bẹnjamini, wọ́n fún àwọn ọmọ Lefi ní àwọn ìlú wọnyi pẹlu pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn: Gibeoni, Geba, 18Anatoti ati Alimoni, gbogbo wọn jẹ́ ìlú mẹrin. 19Àwọn ìlú tí wọ́n fún àwọn ọmọ Aaroni, alufaa, jẹ́ mẹtala pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn.
20Láti inú ilẹ̀ ẹ̀yà Efuraimu ni wọ́n ti gba ìlú fún àwọn ọmọ Kohati yòókù, tí wọ́n jẹ́ ẹ̀yà Lefi. 21Àwọn ni wọ́n fún ní ìlú Ṣekemu, tí ó jẹ́ ìlú ààbò fún àwọn tí wọ́n bá ṣèèṣì pa eniyan, ati àwọn pápá ìdaran rẹ̀ tí ó wà ní agbègbè olókè ti Efuraimu. Wọ́n tún fún wọn ní àwọn ìlú wọnyi, pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn: Geseri, 22Kibusaimu ati Beti Horoni, gbogbo wọn jẹ́ ìlú mẹrin. 23Ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Dani, wọ́n fún wọn ní àwọn ìlú wọnyi pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn: Eliteke, Gibetoni. 24Aijaloni ati Gati Rimoni, gbogbo wọn jẹ́ ìlú mẹrin. 25Ninu ilẹ̀ ìdajì ẹ̀yà Manase, wọ́n fún wọn ní àwọn ìlú wọnyi pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn: Taanaki, ati Gati Rimoni, wọ́n jẹ́ ìlú meji. 26Ìlú àwọn ọmọ Kohati yòókù jẹ́ mẹ́wàá pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn.
27Ninu ilẹ̀ ìdajì ẹ̀yà Manase ni wọ́n ti fún àwọn ọmọ Geriṣoni ninu ìdílé Lefi ní àwọn ìlú wọnyi: Golani ní ilẹ̀ Baṣani pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká rẹ̀. Golani yìí jẹ́ ìlú ààbò fún àwọn tí wọ́n bá ṣèèṣì pa eniyan, ati Beeṣitera pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká rẹ̀, wọ́n jẹ́ ìlú meji. 28Ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Isakari, wọ́n fún wọn ní: Kiṣioni, Daberati, 29ati Jarimutu, Enganimu pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn, gbogbo wọn jẹ́ ìlú mẹrin. 30Ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Aṣeri, wọ́n fún wọn ní: Miṣali, Abidoni, 31Helikati, ati Rehobu pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn, gbogbo wọn jẹ́ ìlú mẹrin. 32Ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Nafutali, wọ́n fún wọn ní: Kedeṣi ní Galili. Kedeṣi yìí jẹ́ ìlú ààbò fún àwọn tí wọ́n bá ṣèèṣì pa eniyan, wọ́n tún fún wọn ní Hamoti Dori, Katani pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn, gbogbo wọn jẹ́ ìlú mẹta. 33Ìlú mẹtala ati pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn ni ilẹ̀ tí ó jẹ́ ti àwọn ọmọ Geriṣoni, gẹ́gẹ́ bi iye ìdílé wọn.
34Ìdílé tí ó ṣẹ́kù ninu ẹ̀yà Lefi ni ìdílé Merari. Ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Sebuluni, wọ́n fún wọn ní: Jokineamu, Kata, 35Dimna, Nahalali pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn, gbogbo wọn jẹ́ ìlú mẹrin. 36Ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Reubẹni, wọ́n fún wọn ní: Beseri, Jahasi, 37Kedemotu, ati Mefaati pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn, gbogbo wọn jẹ́ ìlú mẹrin. 38Ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Gadi, wọ́n fún wọn ní: Ramoti ní Gileadi. Ramoti yìí ni ìlú ààbò fún àwọn tí wọ́n bá ṣèèṣì pa eniyan. Wọ́n tún fún wọn ní Mahanaimu, 39Heṣiboni, ati Jaseri pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn, gbogbo wọn jẹ́ ìlú mẹrin. 40Ìlú mejila ni wọ́n fún àwọn ìdílé yòókù ninu ẹ̀yà Lefi tí à ń pè ní Merari gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn.
41Gbogbo ìlú tí wọ́n fún àwọn ọmọ Lefi ninu ilẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli jẹ́ mejidinlaadọta pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn. 42Olukuluku àwọn ìlú yìí ní pápá ìdaran tí ó yí i ká, bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo àwọn ìlú yòókù.
Israẹli Gba Ilẹ̀ náà
43Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ṣe fún àwọn ọmọ Israẹli ní ilẹ̀ tí ó ti búra fún àwọn baba wọn. Lẹ́yìn tí wọ́n gba ilẹ̀ náà tán, wọ́n ń gbé ibẹ̀. 44OLUWA fún wọn ní ìsinmi ní gbogbo àyíká wọn gẹ́gẹ́ bí ó ti búra fún àwọn baba wọn. Kò sì sí èyíkéyìí ninu àwọn ọ̀tá wọn tí ó lè ṣẹgun wọn, nítorí pé OLUWA ti fi gbogbo àwọn ọ̀tá wọn lé wọn lọ́wọ́. 45Ninu gbogbo ìlérí dáradára tí OLUWA ṣe fún ilé Israẹli kò sí èyí tí kò mú ṣẹ; gbogbo wọn patapata ni ó mú ṣẹ.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

JOṢUA 21: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa