JOṢUA 13

13
Ilẹ̀ Tí Ó kù láti Gbà
1Ní àkókò yìí, Joṣua ti di àgbàlagbà, ogbó sì ti dé sí i. OLUWA bá sọ fún un pé, “Ogbó ti dé sí ọ, ṣugbọn ilẹ̀ pupọ ni ó kù láti gbà. 2Ilẹ̀ tí ó kù nìwọ̀nyí: gbogbo agbègbè àwọn ará Filistia ati ti Geṣuri; 3láti odò Ṣihori, ní apá ìlà oòrùn ilẹ̀ Ijipti, títí lọ sí apá àríwá ní ààlà Ekironi tí ó jẹ́ ti àwọn ará Kenaani, (Marun-un ni ọba àwọn ará Filistia, àwọn nìwọ̀nyí: ọba Gasa, ti Aṣidodu, ti Aṣikeloni, ti Gati, ati ti Ekironi) ati ilẹ̀ àwọn Afimu ní ìhà gúsù. 4Lẹ́yìn náà, gbogbo ilẹ̀ àwọn ará Kenaani ati Meara, tíí ṣe ilẹ̀ àwọn ará Sidoni, títí dé Afeki ní ààlà ilẹ̀ àwọn ará Amori, 5ati ilẹ̀ àwọn ará Gebali, gbogbo Lẹbanoni ní apá ìlà oòrùn, láti Baaligadi tí ó wà ní ìsàlẹ̀ òkè Herimoni títí dé ibodè Hamati. 6Gbogbo àwọn tí wọ́n ń gbé àwọn ìlú tí ó wà ní orí òkè, láti Lẹbanoni, títí dé Misirefoti Maimu, ati gbogbo àwọn ará Sidoni ni n óo lé jáde kúrò níwájú àwọn ọmọ Israẹli. Ṣugbọn, ẹ pín ilẹ̀ náà láàrin àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn, bí mo ti pàṣẹ fun yín. 7Ẹ pín ilẹ̀ náà fún àwọn ẹ̀yà mẹsan-an yòókù ati ìdajì ẹ̀yà Manase.”#Nọm 33:54;
Pípín Agbègbè Tí Ó Wà ní Ìlà Oòrùn Odò Jọdani
8Ẹ̀yà Reubẹni, ẹ̀yà Gadi, ati ìdajì ẹ̀yà Manase gba ilẹ̀ tí Mose, iranṣẹ OLUWA, fún wọn, tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn, ní òdìkejì odò Jọdani; 9láti Aroeri tí ó wà ní etí àfonífojì Arinoni ati ìlú tí ó wà ní ààrin gbùngbùn àfonífojì náà, ati ilẹ̀ tí ó tẹ́jú ní Medeba títí dé Diboni; 10ati gbogbo ìlú Sihoni ọba àwọn ará Amori, tí ó jọba ní Heṣiboni, títí kan ààlà àwọn ará Amoni; 11ati Gileadi ati agbègbè Geṣuri ti Maakati, ati gbogbo òkè Herimoni ati gbogbo Baṣani títí dé Saleka; 12gbogbo ilẹ̀ ọba Ogu ti Baṣani, tí ó jọba ní Aṣitarotu ati Edirei. Ogu yìí nìkan ṣoṣo ni ó ṣẹ́kù ninu ìran Refaimu yòókù. Mose ti ṣẹgun gbogbo wọn, ó sì ti lé wọn jáde. 13Sibẹ àwọn ọmọ Israẹli kò lé àwọn ará Geṣuri ati àwọn ará Maakati jáde; wọ́n ń gbé ààrin àwọn ọmọ Israẹli títí di òní olónìí.#Nọm 32:33; Diut 3:12
14Ẹ̀yà Lefi nìkan ni Mose kò pín ilẹ̀ fún, ẹbọ tí àwọn ọmọ Israẹli bá rú sí OLUWA ni ìpín tiwọn. Bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.#Diut 18:1
Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Ẹ̀yà Reubẹni
15Mose fún àwọn ẹ̀yà Reubẹni ní ilẹ̀, gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn. 16Ilẹ̀ wọn bẹ̀rẹ̀ láti Aroeri tí ó wà ní etí àfonífojì Arinoni, ati ìlú tí ó wà ní ààrin gbùngbùn àfonífojì náà, ati gbogbo ilẹ̀ tí ó tẹ́jú ní Medeba. 17Pẹlu Heṣiboni ati àwọn ìlú agbègbè rẹ̀ ní ilẹ̀ tí ó tẹ́jú. Àwọn ìlú bíi Diboni, Bamoti Baali, ati Beti Baalimeoni; 18Jahasi, Kedemotu, ati Mefaati; 19Kiriataimu, Sibima, ati Sereti Ṣahari, tí ó wà ní orí òkè àfonífojì náà; 20Betipeori, gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Pisiga, ati Beti Jeṣimotu; 21àní, àwọn ìlú tí ó wà ní orí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú ati gbogbo ìjọba Sihoni ọba àwọn ará Amori, tí ó jọba ní Heṣiboni, tí Mose ṣẹgun, pẹlu gbogbo àwọn olórí ilẹ̀ Midiani. Àwọn bíi: Efi, Rekemu, Ṣuri, Huru, ati Reba, ọmọ ọba Sihoni, tí ń gbé ilẹ̀ náà. 22Ọ̀kan ninu àwọn tí àwọn ọmọ Israẹli fi idà pa lójú ogun ni Balaamu, aláfọ̀ṣẹ, ọmọ Beori. 23Odò Jọdani ni ààlà ilẹ̀ àwọn ẹ̀yà Reubẹni. Àwọn ìlú ńláńlá ati àwọn ìlú kéékèèké tí ó wà ninu ilẹ̀ náà jẹ́ ìpín ẹ̀yà Reubẹni gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn.
Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Ẹ̀yà Gadi
24Mose fún ẹ̀yà Gadi ní ìpín tiwọn, gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn. 25Ilẹ̀ tiwọn ni Jaseri ati gbogbo ìlú Gileadi, ati ìdajì ilẹ̀ àwọn ará Amoni, títí dé Aroeri tí ó wà ní ìlà oòrùn Raba; 26láti Heṣiboni, títí dé Ramati Misipe ati Betonimu; ati láti Mahanaimu títí dé agbègbè Debiri; 27àfonífojì Beti Nimra, Sukotu, ati Safoni, ìyókù ilẹ̀ ìjọba Sihoni, ọba Heṣiboni. Odò Jọdani ni ààlà ilẹ̀ wọn, ní apá ìsàlẹ̀ òkun Kinereti, lọ sí apá ìlà oòrùn, níkọjá odò Jọdani. 28Àwọn ìlú ńláńlá ati ìlú kéékèèké tí ó wà ninu ilẹ̀ yìí jẹ́ ìpín ẹ̀yà Gadi gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn.
Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Ẹ̀yà Manase ní ìlà Oòrùn
29Mose fún ìdajì ẹ̀yà Manase ní ìpín tiwọn gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn. 30Ilẹ̀ tiwọn bẹ̀rẹ̀ láti Mahanaimu, títí dé gbogbo ilẹ̀ Baṣani, gbogbo ilẹ̀ ìjọba Ogu, ọba Baṣani, ati gbogbo àwọn ìlú Jairi tí ó wà ní Baṣani, gbogbo ìlú wọn jẹ́ ọgọta. 31Ninu ilẹ̀ wọn ni ìdajì Gileadi wà ati Aṣitarotu ati Edirei, àwọn ìlú ńláńlá ilẹ̀ ìjọba Ogu, ọba Baṣani; Mose pín wọn fún àwọn ìdajì ìdílé Makiri, ọmọ Manase, gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn.
32Àkọsílẹ̀ bí Mose ṣe pín ilẹ̀ tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu ní òdìkejì Jọdani ní apá ìlà oòrùn Jẹriko nìyí. 33Ṣugbọn Mose kò pín ilẹ̀ fún àwọn ẹ̀yà Lefi, OLUWA Ọlọrun Israẹli ni ìpín tiwọn, gẹ́gẹ́ bí ó ti wí fún wọn.#Nọm 18:20; Diut 18:2

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

JOṢUA 13: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀