JOṢUA 14
14
Pípín Ilẹ̀ Tí Ó Wà Ní Apá Ìwọ̀ Oòrùn Odò Jọdani
1Àkọsílẹ̀ bí wọn ṣe pín ilẹ̀ Kenaani, tí ó wà ní apá ìwọ̀ oòrùn odò Jọdani fún àwọn ọmọ Israẹli nìyí. Eleasari alufaa, Joṣua, ọmọ Nuni, ati àwọn olórí láti inú ìdílé kọ̀ọ̀kan ninu ẹ̀yà àwọn ọmọ Israẹli ni wọ́n ṣe ètò pípín ilẹ̀ náà. 2Gègé ni wọ́n ṣẹ́, tí wọ́n fi pín in fún ẹ̀yà mẹsan-an ati ààbọ̀ ninu ẹ̀yà àwọn ọmọ Israẹli, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.#Nọm 26:52-56; 34:13 3Nítorí pé Mose ti fún àwọn ẹ̀yà meji ati ààbọ̀ ní ìpín tiwọn ní òdìkejì odò Jọdani, ṣugbọn kò pín ilẹ̀ fún àwọn ẹ̀yà Lefi. 4Meji ni wọ́n pín àwọn ẹ̀yà Josẹfu sí, àwọn ìpín mejeeji náà ni ẹ̀yà Manase ati ti Efuraimu. Àwọn ẹ̀yà Lefi kò ní ìpín kankan ninu ilẹ̀ náà, ṣugbọn wọ́n fún wọn ní àwọn ìlú láti máa gbé, ati pápá, ibi tí wọ́n ti lè máa da mààlúù wọn, ati gbogbo ẹran ọ̀sìn tí wọ́n ní. 5Bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose gan-an ni àwọn ọmọ Israẹli ṣe pín ilẹ̀ náà.#Nọm 32:33; 34:14-15; Diut 3:12-17
Wọ́n fún Kalebu ní Heburoni
6Ní ọjọ́ kan àwọn ẹ̀yà Juda wá sí ọ̀dọ̀ Joṣua ní Giligali. Ọkunrin kan ninu wọn tí ń jẹ́ Kalebu, ọmọ Jefune, ará Kenisi bá sọ fún un pé, “Ǹjẹ́ o mọ ohun tí OLUWA sọ fún Mose eniyan Ọlọrun ní Kadeṣi Banea nípa àwa mejeeji?#Nọm 14:30. 7Ẹni ogoji ọdún ni mí nígbà tí Mose iranṣẹ OLUWA rán mi láti Kadeṣi Banea láti ṣe amí ilẹ̀ náà. Bí ọkàn mi ti rí gan-an nígbà náà ni mo ṣe ròyìn fún un.#Nọm 13:1-30 8Ṣugbọn àwọn arakunrin mi tí a jọ lọ dáyàjá àwọn ọmọ Israẹli, ṣugbọn èmi fi tọkàntọkàn tẹ̀lé OLUWA Ọlọrun mi. 9Mose bá búra ní ọjọ́ náà pé, ‘Dájúdájú, gbogbo ibi tí ẹsẹ̀ rẹ ti tẹ̀ ni yóo jẹ́ ìpín fún ọ ati fún àwọn ọmọ rẹ títí lae, nítorí pé o ti fi tọkàntọkàn tẹ̀lé OLUWA Ọlọrun mi.’ 10OLUWA ti dá ẹ̀mí mi sí, gẹ́gẹ́ bí ó ti wí, láti nǹkan bí ọdún marunlelogoji tí OLUWA ti sọ ọ̀rọ̀ yìí fún Mose nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli ń rìn ninu aṣálẹ̀. Nisinsinyii, mo ti di ẹni ọdún marundinlaadọrun, 11bí agbára mi ṣe rí nígbà tí Mose rán wa jáde láti lọ ṣe amí, bẹ́ẹ̀ náà ni ó wà títí di òní olónìí, mo tún lágbára láti jagun ati láti wọlé ati láti jáde. 12Nítorí náà, fún mi ní òkè yìí, tí OLUWA sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ní ọjọ́ náà, nítorí pé ìwọ náà gbọ́ ní ọjọ́ náà pé, àwọn ọmọ Anakimu wà níbẹ̀. Ìlú wọn tóbi, wọ́n sì jẹ́ ìlú olódi, ó ṣeéṣe kí OLUWA wà pẹlu mi kí n sì lè lé wọn jáde, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti wí.”#Nọm 14:24
13Joṣua bá súre fún Kalebu ọmọ Jefune, ó sì fún un ní òkè Heburoni, bí ìpín tirẹ̀. 14Bẹ́ẹ̀ ni Heburoni di ilẹ̀ ìní Kalebu, ọmọ Jefune, ará Kenisi títí di òní olónìí, nítorí pé ó fi tọkàntọkàn tẹ̀lé OLUWA Ọlọrun Israẹli. 15Orúkọ Heburoni tẹ́lẹ̀ ni Kiriati Ariba; Ariba yìí ni ẹni tí ó jẹ́ alágbára jùlọ ninu àwọn òmìrán tí à ń pè ní Anakimu.
Àwọn eniyan náà sì sinmi ogun jíjà ní ilẹ̀ náà.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
JOṢUA 14: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010