JOṢUA 12
12
Àwọn Ọba Tí Mose Ṣẹgun
1Àwọn ọmọ Israẹli ṣẹgun àwọn ọba wọnyi, wọ́n sì gba gbogbo ilẹ̀ wọn tí ó wà ní apá ìlà oòrùn, ní òdìkejì odò Jọdani, láti àfonífojì Arinoni títí dé òkè Herimoni, pẹlu gbogbo agbègbè Araba ní apá ìlà oòrùn. 2Wọ́n ṣẹgun Sihoni, ọba àwọn ará Amori, tí ń gbé ìlú Heṣiboni. Ilẹ̀ ìjọba rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ láti Aroeri, tí ó wà ní etí àfonífojì Arinoni, ati láti agbede meji àfonífojì náà, títí dé odò Jaboku, tí í ṣe ààlà ilẹ̀ àwọn ará Amoni, ó jẹ́ ìdajì ilẹ̀ Gileadi; 3ati Araba, títí dé òkun Ṣinerotu ní apá ìlà oòrùn, ní ọ̀nà ìlú Beti Jeṣimotu, títí dé òkun Araba, (tí wọ́n tún ń pè ní Òkun Iyọ̀), títí lọ sí apá ìhà gúsù, títí dé ẹsẹ̀ òkè Pisiga.
4Wọ́n ṣẹgun Ogu, ọba Baṣani náà. Ogu yìí jẹ́ ọ̀kan ninu àwọn tí ó kù ninu ìran Refaimu tí ń gbé Aṣitarotu ati Edirei. 5Lára ilẹ̀ ìjọba rẹ̀ ni òkè Herimoni wà, ati ìlú Saleka, ati gbogbo Baṣani, títí dé ààlà ilẹ̀ àwọn ará Geṣuri, ati ti àwọn ará Maakati ati ìdajì Gileadi títí dé ààlà ọba Sihoni ti ìlú Heṣiboni.#Nọm 21:21-35; Diut 2:26–3:11
6Mose, iranṣẹ OLUWA ati àwọn ọmọ Israẹli ṣẹgun àwọn ọba mejeeji yìí, ó sì pín ilẹ̀ wọn fún ẹ̀yà Reubẹni, ẹ̀yà Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase, ilẹ̀ náà sì di tiwọn.#Nọm 32:33; Diut 3:12
Àwọn Ọba Tí Joṣua Ṣẹgun
7Joṣua ati àwọn ọmọ Israẹli ṣẹgun àwọn ọba wọnyi, ní apá ìwọ̀ oòrùn odò Jọdani, wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn, láti Baaligadi ní àfonífojì Lẹbanoni títí dé òkè Halaki, ní apá Seiri. Joṣua pín ilẹ̀ wọn fún àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìpín ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan. 8Ninu ilẹ̀ náà ni àwọn ìlú tí wọ́n wà lórí òkè wà, ati àwọn tí wọ́n wà ní ẹsẹ̀ òkè, ati àwọn tí wọ́n wà ní Araba, ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè, ní aṣálẹ̀, ati ní Nẹgẹbu. Àwọn tí wọ́n ni ilẹ̀ yìí tẹ́lẹ̀ rí ni àwọn ará Hiti ati àwọn ará Amori, àwọn ará Kenaani ati àwọn ará Perisi, àwọn ará Hifi, ati àwọn ará Jebusi. 9Àwọn ọmọ Israẹli ṣẹgun gbogbo ọba àwọn ìlú wọnyi: Jẹriko ati Ai, lẹ́bàá Bẹtẹli; 10Jerusalẹmu ati Heburoni, 11Jarimutu ati Lakiṣi; 12Egiloni ati Geseri, 13Debiri ati Gederi; 14Horima ati Aradi, 15Libina ati Adulamu; 16Makeda ati Bẹtẹli, 17Tapua ati Heferi; 18Afeki ati Laṣaroni, 19Madoni ati Hasori; 20Ṣimironi Meroni ati Akiṣafu, 21Taanaki ati Megido; 22Kedeṣi ati Jokineamu, ní Kamẹli; 23Dori, tí ó wà ní etí òkun; Goiimu, tí ó wà ní Galili, 24ati Tirisa. Gbogbo wọn jẹ́ ọba mọkanlelọgbọn.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
JOṢUA 12: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010