JOHANU 13:13-34

JOHANU 13:13-34 YCE

Ẹ̀ ń pè mí ní Olùkọ́ni ati Oluwa. Ó dára, nítorí bẹ́ẹ̀ ni mo jẹ́. Bí èmi Oluwa ati Olùkọ́ni yín bá fọ ẹsẹ̀ yín, ó yẹ kí ẹ máa fọ ẹsẹ̀ ẹnìkejì yín. Àpẹẹrẹ ni mo fi fun yín pé, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe si yín, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ máa ṣe. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé: ẹrú kò ju oluwa rẹ̀ lọ, iranṣẹ kò ju ẹni tí ó rán an níṣẹ́ lọ. Bí ẹ bá mọ nǹkan wọnyi, ẹ óo láyọ̀ bí ẹ bá ń ṣe wọ́n. “Gbogbo yín kọ́ ni ọ̀rọ̀ mi yìí kàn. Mo mọ àwọn tí mo yàn. Ṣugbọn Ìwé Mímọ́ níláti ṣẹ tí ó sọ pé, ‘Ẹni tí ó ń bá mi jẹun ni ó ń jìn mí lẹ́sẹ̀.’ Mo wí fun yín nisinsinyii kí ó tó ṣẹlẹ̀, kí ẹ lè mọ ẹni tí èmi í ṣe nígbà tí ó bá ti ṣẹlẹ̀ tán. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ẹni tí ó bá gba ẹnikẹ́ni tí mo rán níṣẹ́, èmi ni ó gbà. Ẹni tí ó bá gbà mí, ó gba ẹni tí ó rán mi níṣẹ́.” Nígbà tí Jesu sọ báyìí tán, ọkàn rẹ̀ dàrú. Ó bá wí tẹ̀dùntẹ̀dùn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ọ̀kan ninu yín ni yóo fi mí lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí wo ara wọn lójú; nítorí ohun tí Jesu sọ rú wọn lójú. Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu, ẹni tí ó fẹ́ràn, jókòó níbi oúnjẹ, ó súnmọ́ Jesu pẹ́kípẹ́kí. Simoni Peteru bá ṣẹ́jú sí i pé kí ó bèèrè pé ta ni ọ̀rọ̀ náà ń bá wí. Nígbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn náà túbọ̀ súnmọ́ Jesu sí i, ó bi í pé, “Oluwa, ta ni rí?” Jesu dáhùn pé, “Ẹni tí mo bá fún ní òkèlè lẹ́yìn tí mo bá ti fi run ọbẹ̀ tán ni ẹni náà.” Nígbà tí ó ti fi òkèlè run ọbẹ̀, ó mú un fún Judasi ọmọ Iskariotu. Lẹ́yìn tí Judasi ti gba òkèlè náà, Satani wọ inú rẹ̀. Jesu bá wí fún un pé, “Tètè ṣe ohun tí o níí ṣe.” Kò sí ẹnìkan ninu àwọn tí wọ́n jọ ń jẹun tí ó mọ ìdí tí Jesu fi sọ ọ̀rọ̀ yìí fún un. Nígbà tí ó jẹ́ pé Judasi ni akápò, àwọn mìíràn ń rò pé ohun tí Jesu sọ fún un ni pé, “Lọ ra àwọn ohun tí a óo lò fún Àjọ̀dún Ìrékọjá, tabi ohun tí a óo fún àwọn talaka.” Lẹsẹkẹsẹ tí Judasi ti gba òkèlè náà tán, ó jáde lọ. Ilẹ̀ ti ṣú nígbà náà. Nígbà tí Judasi jáde, Jesu wí pé, “Nisinsinyii ni ògo Ọmọ-Eniyan wá yọ. Ògo Ọlọrun pàápàá yọ lára Ọmọ-Eniyan. Bí ògo Ọlọrun bá wá yọ lára rẹ̀, Ọlọrun fúnrarẹ̀ yóo mú kí ògo Ọmọ-Eniyan yọ; lọ́gán ni yóo mú kí ògo rẹ̀ yọ. Ẹ̀yin ọmọ, àkókò díẹ̀ ni mo ní sí i pẹlu yín. Ẹ óo wá mi, ṣugbọn bí mo ti sọ fún àwọn Juu pé, ‘Níbi tí mò ń lọ, ẹ̀yin kò ní lè dé ibẹ̀,’ bẹ́ẹ̀ ni mo sọ fun yín nisinsinyii. Òfin titun ni mo fi fun yín, pé kí ẹ fẹ́ràn ara yín; gẹ́gẹ́ bí mo ti fẹ́ràn yín ni kí ẹ fẹ́ràn ara yín.

Verse Images for JOHANU 13:13-34

JOHANU 13:13-34 - Ẹ̀ ń pè mí ní Olùkọ́ni ati Oluwa. Ó dára, nítorí bẹ́ẹ̀ ni mo jẹ́. Bí èmi Oluwa ati Olùkọ́ni yín bá fọ ẹsẹ̀ yín, ó yẹ kí ẹ máa fọ ẹsẹ̀ ẹnìkejì yín. Àpẹẹrẹ ni mo fi fun yín pé, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe si yín, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ máa ṣe. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé: ẹrú kò ju oluwa rẹ̀ lọ, iranṣẹ kò ju ẹni tí ó rán an níṣẹ́ lọ. Bí ẹ bá mọ nǹkan wọnyi, ẹ óo láyọ̀ bí ẹ bá ń ṣe wọ́n.
“Gbogbo yín kọ́ ni ọ̀rọ̀ mi yìí kàn. Mo mọ àwọn tí mo yàn. Ṣugbọn Ìwé Mímọ́ níláti ṣẹ tí ó sọ pé, ‘Ẹni tí ó ń bá mi jẹun ni ó ń jìn mí lẹ́sẹ̀.’ Mo wí fun yín nisinsinyii kí ó tó ṣẹlẹ̀, kí ẹ lè mọ ẹni tí èmi í ṣe nígbà tí ó bá ti ṣẹlẹ̀ tán. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ẹni tí ó bá gba ẹnikẹ́ni tí mo rán níṣẹ́, èmi ni ó gbà. Ẹni tí ó bá gbà mí, ó gba ẹni tí ó rán mi níṣẹ́.”

Nígbà tí Jesu sọ báyìí tán, ọkàn rẹ̀ dàrú. Ó bá wí tẹ̀dùntẹ̀dùn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ọ̀kan ninu yín ni yóo fi mí lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́.”
Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí wo ara wọn lójú; nítorí ohun tí Jesu sọ rú wọn lójú. Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu, ẹni tí ó fẹ́ràn, jókòó níbi oúnjẹ, ó súnmọ́ Jesu pẹ́kípẹ́kí. Simoni Peteru bá ṣẹ́jú sí i pé kí ó bèèrè pé ta ni ọ̀rọ̀ náà ń bá wí.
Nígbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn náà túbọ̀ súnmọ́ Jesu sí i, ó bi í pé, “Oluwa, ta ni rí?”
Jesu dáhùn pé, “Ẹni tí mo bá fún ní òkèlè lẹ́yìn tí mo bá ti fi run ọbẹ̀ tán ni ẹni náà.” Nígbà tí ó ti fi òkèlè run ọbẹ̀, ó mú un fún Judasi ọmọ Iskariotu. Lẹ́yìn tí Judasi ti gba òkèlè náà, Satani wọ inú rẹ̀. Jesu bá wí fún un pé, “Tètè ṣe ohun tí o níí ṣe.” Kò sí ẹnìkan ninu àwọn tí wọ́n jọ ń jẹun tí ó mọ ìdí tí Jesu fi sọ ọ̀rọ̀ yìí fún un. Nígbà tí ó jẹ́ pé Judasi ni akápò, àwọn mìíràn ń rò pé ohun tí Jesu sọ fún un ni pé, “Lọ ra àwọn ohun tí a óo lò fún Àjọ̀dún Ìrékọjá, tabi ohun tí a óo fún àwọn talaka.”
Lẹsẹkẹsẹ tí Judasi ti gba òkèlè náà tán, ó jáde lọ. Ilẹ̀ ti ṣú nígbà náà.

Nígbà tí Judasi jáde, Jesu wí pé, “Nisinsinyii ni ògo Ọmọ-Eniyan wá yọ. Ògo Ọlọrun pàápàá yọ lára Ọmọ-Eniyan. Bí ògo Ọlọrun bá wá yọ lára rẹ̀, Ọlọrun fúnrarẹ̀ yóo mú kí ògo Ọmọ-Eniyan yọ; lọ́gán ni yóo mú kí ògo rẹ̀ yọ. Ẹ̀yin ọmọ, àkókò díẹ̀ ni mo ní sí i pẹlu yín. Ẹ óo wá mi, ṣugbọn bí mo ti sọ fún àwọn Juu pé, ‘Níbi tí mò ń lọ, ẹ̀yin kò ní lè dé ibẹ̀,’ bẹ́ẹ̀ ni mo sọ fun yín nisinsinyii. Òfin titun ni mo fi fun yín, pé kí ẹ fẹ́ràn ara yín; gẹ́gẹ́ bí mo ti fẹ́ràn yín ni kí ẹ fẹ́ràn ara yín.JOHANU 13:13-34 - Ẹ̀ ń pè mí ní Olùkọ́ni ati Oluwa. Ó dára, nítorí bẹ́ẹ̀ ni mo jẹ́. Bí èmi Oluwa ati Olùkọ́ni yín bá fọ ẹsẹ̀ yín, ó yẹ kí ẹ máa fọ ẹsẹ̀ ẹnìkejì yín. Àpẹẹrẹ ni mo fi fun yín pé, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe si yín, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ máa ṣe. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé: ẹrú kò ju oluwa rẹ̀ lọ, iranṣẹ kò ju ẹni tí ó rán an níṣẹ́ lọ. Bí ẹ bá mọ nǹkan wọnyi, ẹ óo láyọ̀ bí ẹ bá ń ṣe wọ́n.
“Gbogbo yín kọ́ ni ọ̀rọ̀ mi yìí kàn. Mo mọ àwọn tí mo yàn. Ṣugbọn Ìwé Mímọ́ níláti ṣẹ tí ó sọ pé, ‘Ẹni tí ó ń bá mi jẹun ni ó ń jìn mí lẹ́sẹ̀.’ Mo wí fun yín nisinsinyii kí ó tó ṣẹlẹ̀, kí ẹ lè mọ ẹni tí èmi í ṣe nígbà tí ó bá ti ṣẹlẹ̀ tán. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ẹni tí ó bá gba ẹnikẹ́ni tí mo rán níṣẹ́, èmi ni ó gbà. Ẹni tí ó bá gbà mí, ó gba ẹni tí ó rán mi níṣẹ́.”

Nígbà tí Jesu sọ báyìí tán, ọkàn rẹ̀ dàrú. Ó bá wí tẹ̀dùntẹ̀dùn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ọ̀kan ninu yín ni yóo fi mí lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́.”
Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí wo ara wọn lójú; nítorí ohun tí Jesu sọ rú wọn lójú. Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu, ẹni tí ó fẹ́ràn, jókòó níbi oúnjẹ, ó súnmọ́ Jesu pẹ́kípẹ́kí. Simoni Peteru bá ṣẹ́jú sí i pé kí ó bèèrè pé ta ni ọ̀rọ̀ náà ń bá wí.
Nígbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn náà túbọ̀ súnmọ́ Jesu sí i, ó bi í pé, “Oluwa, ta ni rí?”
Jesu dáhùn pé, “Ẹni tí mo bá fún ní òkèlè lẹ́yìn tí mo bá ti fi run ọbẹ̀ tán ni ẹni náà.” Nígbà tí ó ti fi òkèlè run ọbẹ̀, ó mú un fún Judasi ọmọ Iskariotu. Lẹ́yìn tí Judasi ti gba òkèlè náà, Satani wọ inú rẹ̀. Jesu bá wí fún un pé, “Tètè ṣe ohun tí o níí ṣe.” Kò sí ẹnìkan ninu àwọn tí wọ́n jọ ń jẹun tí ó mọ ìdí tí Jesu fi sọ ọ̀rọ̀ yìí fún un. Nígbà tí ó jẹ́ pé Judasi ni akápò, àwọn mìíràn ń rò pé ohun tí Jesu sọ fún un ni pé, “Lọ ra àwọn ohun tí a óo lò fún Àjọ̀dún Ìrékọjá, tabi ohun tí a óo fún àwọn talaka.”
Lẹsẹkẹsẹ tí Judasi ti gba òkèlè náà tán, ó jáde lọ. Ilẹ̀ ti ṣú nígbà náà.

Nígbà tí Judasi jáde, Jesu wí pé, “Nisinsinyii ni ògo Ọmọ-Eniyan wá yọ. Ògo Ọlọrun pàápàá yọ lára Ọmọ-Eniyan. Bí ògo Ọlọrun bá wá yọ lára rẹ̀, Ọlọrun fúnrarẹ̀ yóo mú kí ògo Ọmọ-Eniyan yọ; lọ́gán ni yóo mú kí ògo rẹ̀ yọ. Ẹ̀yin ọmọ, àkókò díẹ̀ ni mo ní sí i pẹlu yín. Ẹ óo wá mi, ṣugbọn bí mo ti sọ fún àwọn Juu pé, ‘Níbi tí mò ń lọ, ẹ̀yin kò ní lè dé ibẹ̀,’ bẹ́ẹ̀ ni mo sọ fun yín nisinsinyii. Òfin titun ni mo fi fun yín, pé kí ẹ fẹ́ràn ara yín; gẹ́gẹ́ bí mo ti fẹ́ràn yín ni kí ẹ fẹ́ràn ara yín.