JOHANU 13

13
Jesu Wẹ Ẹsẹ̀ Àwọn Ọmọ-ẹ̀yìn Rẹ̀
1Nígbà tí àkókò Àjọ̀dún Ìrékọjá ku ọjọ́ kan, Jesu mọ̀ pé àkókò tó, tí òun yóo kúrò láyé yìí lọ sọ́dọ̀ Baba. Fífẹ́ tí ó fẹ́ràn àwọn eniyan rẹ̀ tó wà láyé yìí, ó fẹ́ràn wọn dé òpin.
2Bí wọ́n ti ń jẹun, Èṣù ti fi sí Judasi ọmọ Simoni Iskariotu lọ́kàn láti fi Jesu lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́. 3Jesu mọ̀ pé Baba ti fi ohun gbogbo lé òun lọ́wọ́, ati pé ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni òun ti wá, ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni òun sì ń lọ. 4Ó bá dìde nídìí oúnjẹ, ó bọ́ agbádá rẹ̀ sílẹ̀, ó mú aṣọ ìnura, ó lọ́ ọ mọ́ ìbàdí, 5ó bu omi sinu àwokòtò kan, ó bẹ̀rẹ̀ sí fọ ẹsẹ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó ń fi aṣọ ìnura tí ó lọ́ mọ́ ìbàdí nù wọ́n lẹ́sẹ̀. 6Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ Simoni Peteru, Peteru bi í pé, “Oluwa, ìwọ ni o fẹ́ fọ ẹsẹ̀ mi?”
7Jesu dá a lóhùn pé, “O kò mọ ohun tí mò ń ṣe nisinsinyii; ṣugbọn yóo yé ọ tí ó bá yá.”
8Peteru dá a lóhùn pé, “O kò ní fọ ẹsẹ̀ mi laelae!”
Jesu wí fún un pé, “Bí n kò bá wẹ̀ ọ́, a jẹ́ pé ìwọ kò ní nǹkankan ṣe pẹlu mi.”
9Simoni Peteru bá sọ fún un pé, “Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, Oluwa, ẹsẹ̀ mi nìkan kọ́, ati ọwọ́ ati orí mi ni kí o fọ̀ pẹlu.”
10Jesu wí fún un pé, “Ẹni tí ó bá ti wẹ̀ nílé, tí ó bá jáde, kò sí ohun tí ó kù jù pé kí á fọ ẹsẹ̀ rẹ̀ lọ, gbogbo ara rẹ̀ á wá di mímọ́. Ẹ̀yin mọ́, ṣugbọn kì í ṣe gbogbo yín.” 11Ó ti mọ ẹni tí yóo fi òun lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́; nítorí náà ni ó ṣe sọ pé, “Kì í ṣe gbogbo yín ni ó mọ́.”
12Nígbà tí ó ti fọ ẹsẹ̀ wọn tán, ó wọ agbádá rẹ̀, ó bá tún jókòó. Ó wá bi wọ́n pé, “Ǹjẹ́ ẹ mọ ohun tí mo ṣe si yín? 13Ẹ̀ ń pè mí ní Olùkọ́ni ati Oluwa. Ó dára, nítorí bẹ́ẹ̀ ni mo jẹ́. 14Bí èmi Oluwa ati Olùkọ́ni yín bá fọ ẹsẹ̀ yín, ó yẹ kí ẹ máa fọ ẹsẹ̀ ẹnìkejì yín. 15Àpẹẹrẹ ni mo fi fun yín pé, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe si yín, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ máa ṣe.#Luk 22:27 16Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé: ẹrú kò ju oluwa rẹ̀ lọ, iranṣẹ kò ju ẹni tí ó rán an níṣẹ́ lọ.#Mat 10:24; Luk 6:40; Joh 15:20 17Bí ẹ bá mọ nǹkan wọnyi, ẹ óo láyọ̀ bí ẹ bá ń ṣe wọ́n.
18“Gbogbo yín kọ́ ni ọ̀rọ̀ mi yìí kàn. Mo mọ àwọn tí mo yàn. Ṣugbọn Ìwé Mímọ́ níláti ṣẹ tí ó sọ pé, ‘Ẹni tí ó ń bá mi jẹun ni ó ń jìn mí lẹ́sẹ̀.’#O. Daf 41:9 19Mo wí fun yín nisinsinyii kí ó tó ṣẹlẹ̀, kí ẹ lè mọ ẹni tí èmi í ṣe nígbà tí ó bá ti ṣẹlẹ̀ tán.#Mat 10:40; Mak 9:37; Luk 9:48; 10:16 20Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ẹni tí ó bá gba ẹnikẹ́ni tí mo rán níṣẹ́, èmi ni ó gbà. Ẹni tí ó bá gbà mí, ó gba ẹni tí ó rán mi níṣẹ́.”
Jesu Sọ Ẹni Tí Yóo fi Òun fún Àwọn Ọ̀tá
(Mat 26:20-25; Mak 14:17-21; Luk 22:21-23)
21Nígbà tí Jesu sọ báyìí tán, ọkàn rẹ̀ dàrú. Ó bá wí tẹ̀dùntẹ̀dùn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ọ̀kan ninu yín ni yóo fi mí lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́.”
22Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí wo ara wọn lójú; nítorí ohun tí Jesu sọ rú wọn lójú. 23Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu, ẹni tí ó fẹ́ràn, jókòó níbi oúnjẹ, ó súnmọ́ Jesu pẹ́kípẹ́kí. 24Simoni Peteru bá ṣẹ́jú sí i pé kí ó bèèrè pé ta ni ọ̀rọ̀ náà ń bá wí.
25Nígbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn náà túbọ̀ súnmọ́ Jesu sí i, ó bi í pé, “Oluwa, ta ni rí?”
26Jesu dáhùn pé, “Ẹni tí mo bá fún ní òkèlè lẹ́yìn tí mo bá ti fi run ọbẹ̀ tán ni ẹni náà.” Nígbà tí ó ti fi òkèlè run ọbẹ̀, ó mú un fún Judasi ọmọ Iskariotu. 27Lẹ́yìn tí Judasi ti gba òkèlè náà, Satani wọ inú rẹ̀. Jesu bá wí fún un pé, “Tètè ṣe ohun tí o níí ṣe.” 28Kò sí ẹnìkan ninu àwọn tí wọ́n jọ ń jẹun tí ó mọ ìdí tí Jesu fi sọ ọ̀rọ̀ yìí fún un. 29Nígbà tí ó jẹ́ pé Judasi ni akápò, àwọn mìíràn ń rò pé ohun tí Jesu sọ fún un ni pé, “Lọ ra àwọn ohun tí a óo lò fún Àjọ̀dún Ìrékọjá, tabi ohun tí a óo fún àwọn talaka.”
30Lẹsẹkẹsẹ tí Judasi ti gba òkèlè náà tán, ó jáde lọ. Ilẹ̀ ti ṣú nígbà náà.
Òfin Titun
31Nígbà tí Judasi jáde, Jesu wí pé, “Nisinsinyii ni ògo Ọmọ-Eniyan wá yọ. Ògo Ọlọrun pàápàá yọ lára Ọmọ-Eniyan. 32Bí ògo Ọlọrun bá wá yọ lára rẹ̀, Ọlọrun fúnrarẹ̀ yóo mú kí ògo Ọmọ-Eniyan yọ; lọ́gán ni yóo mú kí ògo rẹ̀ yọ. 33Ẹ̀yin ọmọ, àkókò díẹ̀ ni mo ní sí i pẹlu yín. Ẹ óo wá mi, ṣugbọn bí mo ti sọ fún àwọn Juu pé, ‘Níbi tí mò ń lọ, ẹ̀yin kò ní lè dé ibẹ̀,’ bẹ́ẹ̀ ni mo sọ fun yín nisinsinyii.#Joh 7:34 34Òfin titun ni mo fi fun yín, pé kí ẹ fẹ́ràn ara yín; gẹ́gẹ́ bí mo ti fẹ́ràn yín ni kí ẹ fẹ́ràn ara yín.#Joh 15:12, 17; 1 Joh 3:23; 2 Joh 5 35Èyí ni yóo jẹ́ kí gbogbo eniyan mọ̀ pé ọmọ-ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá fẹ́ràn ara yín.”
Jesu Sọtẹ́lẹ̀ pé Peteru yóo Sẹ́ Òun
(Mat 26:31-35; Mak 14:27-31; Luk 22:31-34)
36Simoni Peteru bi í pé, “Oluwa, níbo ni ò ń lọ?”
Jesu dá a lóhùn pé, “Níbi tí mò ń lọ, ìwọ kò lè tẹ̀lé mi nisinsinyii, ṣugbọn nígbà tí ó bá yá, ìwọ óo tẹ̀lé mi.”
37Peteru bi í pé, “Oluwa, kí ló dé tí n kò lè tẹ̀lé ọ nisinsinyii? Mo ṣetán láti kú nítorí rẹ.”
38Jesu dá a lóhùn pé, “O ṣetán láti kú nítorí mi? Mo fẹ́ kí o mọ̀ dájúdájú pé, kí àkùkọ tó kọ ìwọ óo sẹ́ mi lẹẹmẹta.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

JOHANU 13: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

Àwọn fídíò fún JOHANU 13