Joh 13:13-34

Joh 13:13-34 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ẹnyin npè mi li Olukọni ati Oluwa: ẹnyin wi rere; bẹ̃ni mo jẹ. Njẹ bi emi ti iṣe Oluwa ati Olukọni nyin ba wẹ̀ ẹsẹ nyin, o tọ́ ki ẹnyin pẹlu si mã wẹ̀ ẹsẹ ara nyin. Nitori mo ti fi apẹ̃rẹ fun nyin, ki ẹnyin ki o le mã ṣe gẹgẹ bi mo ti ṣe si nyin. Lòtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ọmọ-ọdọ kò tobi jù oluwa rẹ̀ lọ; bẹ̃ni ẹniti a rán kò tobi jù ẹniti o rán a lọ. Bi ẹnyin ba mọ̀ nkan wọnyi, alabukun-fun ni nyin, bi ẹnyin ba nṣe wọn. Kì iṣe ti gbogbo nyin ni mo nsọ: emi mọ̀ awọn ti mo yàn: ṣugbọn ki iwe-mimọ́ ki o le ṣẹ, Ẹniti mba mi jẹun pọ̀ si gbé gigĩsẹ rẹ̀ si mi. Lati isisiyi lọ mo sọ fun nyin ki o to de, pe nigbati o ba de, ki ẹnyin ki o le gbagbọ́ pe emi ni. Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹniti o ba gbà ẹnikẹni ti mo rán, o gbà mi; ẹniti o ba si gbà mi o gbà ẹniti o rán mi. Nigbati Jesu ti wi nkan wọnyi tan, ọkàn rẹ̀ daru ninu rẹ̀, o si jẹri, o si wipe, Lõtọ lõtọ ni mo wi fun nyin pe, ọkan ninu nyin yio fi mi hàn. Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ nwò ara wọn loju, nwọn nṣiye-meji ti ẹniti o wi. Njẹ ẹnikan rọ̀gún si àiya Jesu, ọkan ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, ẹniti Jesu fẹràn. Nitorina ni Simoni Peteru ṣapẹrẹ si i, o si wi fun u pe, Wi fun wa ti ẹniti o nsọ. Ẹniti o nrọ̀gún li àiya Jesu wi fun u pe, Oluwa, tani iṣe? Nitorina Jesu dahùn pe, On na ni, ẹniti mo ba fi òkele fun nigbati mo ba fi run. Nigbati o si fi i run tan, o fifun Judasi Iskariotu ọmọ Simoni. Lẹhin òkele na ni Satani wọ̀ inu rẹ̀ lọ. Nitorina Jesu wi fun u pe, Ohun ti iwọ nṣe nì, yara ṣe e kánkan. Kò si si ẹnikan nibi tabili ti o mọ̀ idi ohun ti o ṣe sọ eyi fun u. Nitori awọn miran ninu wọn rò pe, nitori Judasi li o ni àpo, ni Jesu fi wi fun u pe, Rà nkan wọnni ti a kò le ṣe alaini fun ajọ na; tabi ki o le fi nkan fun awọn talakà. Nigbati o si ti gbà òkele na tan, o jade lojukanna: oru si ni. Nitorina nigbati o jade lọ tan, Jesu wipe, Nisisiyi li a yìn Ọmọ-enia logo, a si yìn Ọlọrun logo ninu rẹ̀. Bi a ba yìn Ọlọrun logo ninu rẹ̀, Ọlọrun yio si yìn i logo ninu on tikararẹ̀, yio si yìn i logo nisisiyi. Ẹnyin ọmọde, nigba diẹ si i li emi wà pẹlu nyin. Ẹnyin ó wá mi: ati gẹgẹ bi mo ti wi fun awọn Ju pe, Nibiti emi gbé nlọ, ẹnyin kì o le wá; bẹ̃ni mo si wi fun nyin nisisiyi. Ofin titun kan ni mo fifun nyin, Ki ẹnyin ki o fẹ ọmọnikeji nyin; gẹgẹ bi emi ti fẹran nyin, ki ẹnyin ki o si le fẹran ọmọnikeji nyin.

Joh 13:13-34 Yoruba Bible (YCE)

Ẹ̀ ń pè mí ní Olùkọ́ni ati Oluwa. Ó dára, nítorí bẹ́ẹ̀ ni mo jẹ́. Bí èmi Oluwa ati Olùkọ́ni yín bá fọ ẹsẹ̀ yín, ó yẹ kí ẹ máa fọ ẹsẹ̀ ẹnìkejì yín. Àpẹẹrẹ ni mo fi fun yín pé, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe si yín, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ máa ṣe. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé: ẹrú kò ju oluwa rẹ̀ lọ, iranṣẹ kò ju ẹni tí ó rán an níṣẹ́ lọ. Bí ẹ bá mọ nǹkan wọnyi, ẹ óo láyọ̀ bí ẹ bá ń ṣe wọ́n. “Gbogbo yín kọ́ ni ọ̀rọ̀ mi yìí kàn. Mo mọ àwọn tí mo yàn. Ṣugbọn Ìwé Mímọ́ níláti ṣẹ tí ó sọ pé, ‘Ẹni tí ó ń bá mi jẹun ni ó ń jìn mí lẹ́sẹ̀.’ Mo wí fun yín nisinsinyii kí ó tó ṣẹlẹ̀, kí ẹ lè mọ ẹni tí èmi í ṣe nígbà tí ó bá ti ṣẹlẹ̀ tán. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ẹni tí ó bá gba ẹnikẹ́ni tí mo rán níṣẹ́, èmi ni ó gbà. Ẹni tí ó bá gbà mí, ó gba ẹni tí ó rán mi níṣẹ́.” Nígbà tí Jesu sọ báyìí tán, ọkàn rẹ̀ dàrú. Ó bá wí tẹ̀dùntẹ̀dùn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ọ̀kan ninu yín ni yóo fi mí lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí wo ara wọn lójú; nítorí ohun tí Jesu sọ rú wọn lójú. Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu, ẹni tí ó fẹ́ràn, jókòó níbi oúnjẹ, ó súnmọ́ Jesu pẹ́kípẹ́kí. Simoni Peteru bá ṣẹ́jú sí i pé kí ó bèèrè pé ta ni ọ̀rọ̀ náà ń bá wí. Nígbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn náà túbọ̀ súnmọ́ Jesu sí i, ó bi í pé, “Oluwa, ta ni rí?” Jesu dáhùn pé, “Ẹni tí mo bá fún ní òkèlè lẹ́yìn tí mo bá ti fi run ọbẹ̀ tán ni ẹni náà.” Nígbà tí ó ti fi òkèlè run ọbẹ̀, ó mú un fún Judasi ọmọ Iskariotu. Lẹ́yìn tí Judasi ti gba òkèlè náà, Satani wọ inú rẹ̀. Jesu bá wí fún un pé, “Tètè ṣe ohun tí o níí ṣe.” Kò sí ẹnìkan ninu àwọn tí wọ́n jọ ń jẹun tí ó mọ ìdí tí Jesu fi sọ ọ̀rọ̀ yìí fún un. Nígbà tí ó jẹ́ pé Judasi ni akápò, àwọn mìíràn ń rò pé ohun tí Jesu sọ fún un ni pé, “Lọ ra àwọn ohun tí a óo lò fún Àjọ̀dún Ìrékọjá, tabi ohun tí a óo fún àwọn talaka.” Lẹsẹkẹsẹ tí Judasi ti gba òkèlè náà tán, ó jáde lọ. Ilẹ̀ ti ṣú nígbà náà. Nígbà tí Judasi jáde, Jesu wí pé, “Nisinsinyii ni ògo Ọmọ-Eniyan wá yọ. Ògo Ọlọrun pàápàá yọ lára Ọmọ-Eniyan. Bí ògo Ọlọrun bá wá yọ lára rẹ̀, Ọlọrun fúnrarẹ̀ yóo mú kí ògo Ọmọ-Eniyan yọ; lọ́gán ni yóo mú kí ògo rẹ̀ yọ. Ẹ̀yin ọmọ, àkókò díẹ̀ ni mo ní sí i pẹlu yín. Ẹ óo wá mi, ṣugbọn bí mo ti sọ fún àwọn Juu pé, ‘Níbi tí mò ń lọ, ẹ̀yin kò ní lè dé ibẹ̀,’ bẹ́ẹ̀ ni mo sọ fun yín nisinsinyii. Òfin titun ni mo fi fun yín, pé kí ẹ fẹ́ràn ara yín; gẹ́gẹ́ bí mo ti fẹ́ràn yín ni kí ẹ fẹ́ràn ara yín.

Joh 13:13-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ẹ̀yin ń pè mí ní ‘Olùkọ́’ àti ‘Olúwa,’ ẹ̀yin wí rere; bẹ́ẹ̀ ni mo jẹ́. Ǹjẹ́ bí èmi tí í ṣe Olúwa àti olùkọ́ yín bá wẹ ẹsẹ̀ yín, ó tọ́ kí ẹ̀yin pẹ̀lú sì máa wẹ ẹsẹ̀ ara yín. Nítorí mo fi àpẹẹrẹ fún yín, kí ẹ̀yin lè máa ṣe gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe sí yín. Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ọmọ ọ̀dọ̀ kò tóbi ju ọ̀gá rẹ̀ lọ, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí a rán kò tóbi ju ẹni tí ó rán an lọ. Bí ẹ̀yin bá mọ nǹkan wọ̀nyí, alábùkún fún ni yín, bí ẹ̀yin bá ń ṣe wọ́n! “Kì í ṣe ti gbogbo yín ni mo ń sọ: èmi mọ àwọn tí mo yàn: ṣùgbọ́n kí Ìwé mímọ́ bá à lè ṣẹ, ‘ẹni tí ń bá mi jẹun pọ̀ sì gbé gìgísẹ̀ rẹ̀ sí mi.’ “Láti ìsinsin yìí lọ ni mo wí fún un yín kí ó tó dé, pé nígbà tí ó bá dé, kí ẹ̀yin lè gbàgbọ́ pé èmi ni. Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, Ẹni tí ó bá gba ẹnikẹ́ni tí mo rán, ó gbà mí; ẹni tí ó bá sì gbà mí, ó gba ẹni tí ó rán mi.” Nígbà tí Jesu ti wí nǹkan wọ̀nyí tán, ọkàn rẹ̀ dàrú nínú rẹ̀, ó sì jẹ́rìí, ó sì wí pé, “Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún un yín pé, ọ̀kan nínú yín yóò dà mí.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń wò ara wọn lójú, wọ́n ń ṣiyèméjì ti ẹni tí ó wí. Ǹjẹ́ ẹnìkan rọ̀gbọ̀kú sí àyà Jesu, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ẹni tí Jesu fẹ́ràn. Nítorí náà ni Simoni Peteru ṣàpẹẹrẹ sí i, ó sì wí fún un pé, “Wí fún wa ti ẹni tí o ń sọ.” Ẹni tí ó ń rọ̀gún ní àyà Jesu wí fún un pé, “Olúwa, ta ni í ṣe?” Nítorí náà Jesu dáhùn pé, “Òun náà ni, ẹni tí mo bá fi àkàrà fún nígbà tí mo bá fi run àwo.” Nígbà tí ó sì fi run ún tan, ó fi fún Judasi Iskariotu ọmọ Simoni. Ní kété tí Judasi gba àkàrà náà ni Satani wọ inú rẹ̀ lọ. Nítorí náà Jesu wí fún un pé, “Ohun tí ìwọ ń ṣe nì, yára ṣe é kánkán.” Kò sì sí ẹnìkan níbi tábìlì tí ó mọ ìdí tí ó ṣe sọ èyí fún un. Nítorí àwọn mìíràn nínú wọn rò pé, nítorí Judasi ni ó ni àpò, ni Jesu fi wí fún un pé, ra nǹkan wọ̀n-ọn-nì tí a kò le ṣe aláìní fún àjọ náà; tàbí kí ó lè fi nǹkan fún àwọn tálákà. Nígbà tí ó sì ti gbà òkèlè náà tan, ó jáde lójúkan náà àkókò náà si jẹ òru. Nítorí náà nígbà tí ó jáde lọ tan, Jesu wí pé, “Nísinsin yìí ni a yin Ọmọ ènìyàn lógo, a sì yin Ọlọ́run lógo nínú rẹ̀. Bí a bá yin Ọlọ́run lógo nínú rẹ̀, Ọlọ́run yóò sì yìn ín lógo nínú òun tìkára rẹ̀, yóò sì yìn ín lógo nísinsin yìí. “Ẹ̀yin ọmọ mi, nígbà díẹ̀ sí i ni èmi wà pẹ̀lú yín. Ẹ̀yin yóò wá mi: àti gẹ́gẹ́ bí mo ti wí fún àwọn Júù pé, Níbi tí èmi gbé ń lọ, ẹ̀yin kì yóò le wà; bẹ́ẹ̀ ni mo sì wí fún yín nísinsin yìí. “Òfin tuntun kan ni mo fi fún yín, kí ẹ̀yin kí ó fẹ́ ọmọnìkejì yín; gẹ́gẹ́ bí èmi ti fẹ́ràn yín, kí ẹ̀yin kí ó sì fẹ́ràn ọmọnìkejì yín.

Joh 13:13-34

Joh 13:13-34 YBCVJoh 13:13-34 YBCV