JEREMAYA 20

20
Ìjà láàrin Jeremaya ati Paṣuri Alufaa
1Nígbà tí Paṣuri alufaa, ọmọ Imeri, tí ó jẹ́ olórí àwọn olùṣọ́ ilé OLUWA, gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Jeremaya ń sọ, 2ó ní kí wọn lu Jeremaya, kí wọn kàn ààbà mọ́ ọn lẹ́sẹ̀ ní ẹnu ọ̀nà Bẹnjamini ti òkè, ní ilé OLUWA. 3Ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, nígbà tí Paṣuri tú Jeremaya sílẹ̀ ninu ààbà, Jeremaya wí fún un pé, “Kì í ṣe Paṣuri#20:3 Ìtumọ̀ Paṣuri ni “Ire lọ́tùn-ún lósì.” ni OLUWA pe orúkọ rẹ, ìpayà lọ́tùn-ún ati lósì ni OLUWA pè ọ́. 4OLUWA ní, ‘N óo sọ ọ́ di ìpayà fún ara rẹ ati fún gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ràn rẹ. Àwọn ọ̀tá yóo fi idà pa wọ́n níṣojú rẹ, n óo fi gbogbo ilẹ̀ Juda lé ọba Babiloni lọ́wọ́. Yóo kó wọn ní ìgbèkùn lọ sí Babiloni, yóo sì fi idà pa wọ́n. 5Bákan náà, n óo da gbogbo ọrọ̀ ìlú yìí, ati gbogbo èrè iṣẹ́ tí wọ́n ṣe lé àwọn ará Babiloni lọ́wọ́, pẹlu gbogbo nǹkan olówó iyebíye wọn, ati gbogbo ìṣúra àwọn ọba Juda; gbogbo rẹ̀ ni àwọn ọ̀tá wọn, àwọn ará Babiloni yóo fogun kó, wọn yóo sì rù wọ́n lọ sí Babiloni. 6Ní ti ìwọ Paṣuri, ati gbogbo àwọn ará ilé rẹ, wọn óo ko yín ní ìgbèkùn lọ sí Babiloni. Ibẹ̀ ni ẹ óo kú sí, ibẹ̀ ni wọ́n óo sì sin yín sí; àtìwọ, ati gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tí ò ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ irọ́ fún.’ ”
Ìráhùn Jeremaya sí OLUWA
7OLUWA, o tàn mí jẹ, mo sì gba ẹ̀tàn;
o ní agbára jù mí lọ, o sì borí mi.
Mo di ẹni ẹ̀sín láti àárọ̀ títí di alẹ́,
gbogbo eniyan ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́.
8Gbogbo ìgbà tí mo bá ti sọ̀rọ̀, ni mò ń kígbe pé,
“Ogun ati ìparun dé!”
Nítorí náà, ọ̀rọ̀ OLUWA tí mò ń kéde sọ mí di ẹni yẹ̀yẹ́ tọ̀sán-tòru.
9Ṣugbọn nígbàkúùgbà tí mo bá wí pé n kò ní dárúkọ rẹ̀ mọ́,
bẹ́ẹ̀ ni n kò ní sọ̀rọ̀ ní orúkọ rẹ̀ mọ́,
ọ̀rọ̀ rẹ a máa jó mi ninu bí iná,
a sì máa ro mí ninu egungun.
Mo gbìyànjú títí pé kí n pa á mọ́ra,
ṣugbọn kò ṣeéṣe.
10Nítorí mò ń gbọ́ tí ọpọlọpọ ń sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ pé,
“Ìpayà wà lọ́tùn-ún lósì,
ẹ lọ fẹjọ́ rẹ̀ sùn.
Ẹ jẹ́ kí á fẹjọ́ rẹ̀ sùn.”
Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ mi ń wí,
tí wọn sì ń retí ìṣubú mi.
Wọ́n ń sọ pé,
“Bóyá yóo bọ́ sọ́wọ́ ẹlẹ́tàn,
ọwọ́ wa yóo sì tẹ̀ ẹ́;
a óo sì gbẹ̀san lára rẹ̀.”
11Ṣugbọn OLUWA wà pẹlu mi bíi jagunjagun tí ó bani lẹ́rù.
Nítorí náà àwọn tí wọn ń lépa mi yóo kọsẹ̀,
apá wọn kò ní ká mi.
Ojú yóo tì wọ́n lọpọlọpọ nítorí wọn kò ní lè borí mi.
Ẹ̀sín tí ẹnikẹ́ni kò ní gbàgbé yóo dé bá wọn títí lae.
12OLUWA àwọn ọmọ ogun, ìwọ tíí dán olódodo wò,
ìwọ tí o mọ ọkàn ati èrò eniyan.
Gbẹ̀san lára wọn kí n fojú rí i,
nítorí ìwọ ni mo fi ọ̀rọ̀ mi lé lọ́wọ́.
13Ẹ kọrin sí OLUWA,
ẹ yin OLUWA.
Nítorí pé ó gba ẹ̀mí aláìní sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn aṣebi.
14Ègún ni fún ọjọ́ tí a bí mi,
kí ọjọ́ tí ìyá mi bí mi má jẹ́ ọjọ́ ayọ̀.
15Ègún ni fún ẹni tí ó yọ̀ fún baba mi,
tí ó sọ fún un pé,
“Iyawo rẹ ti bí ọmọkunrin kan fún ọ,
tí ó mú inú rẹ̀ dùn.”
16Kí olúwarẹ̀ dàbí àwọn ìlú tí OLUWA parun láìṣàánú wọn.
Kí ó gbọ́ igbe lówùúrọ̀,
ati ariwo ìdágìrì lọ́sàn-án gangan.
17Nítorí pé kò pa mí ninu oyún,
kí inú ìyá mi lè jẹ́ isà òkú fún mi.
Kí n wà ninu oyún ninu ìyá mi títí ayé.
18Kí ló dé tí wọn bí mi sáyé?#Job 3:1-19
Ṣé kí n lè máa fojú rí ìṣẹ́ ati ìbànújẹ́ ni?
Kí gbogbo ọjọ́ ayé mi lè kún fún ìtìjú?

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

JEREMAYA 20: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀