Gbogbo ìgbà tí mo bá ti sọ̀rọ̀, ni mò ń kígbe pé,
“Ogun ati ìparun dé!”
Nítorí náà, ọ̀rọ̀ OLUWA tí mò ń kéde sọ mí di ẹni yẹ̀yẹ́ tọ̀sán-tòru.
Ṣugbọn nígbàkúùgbà tí mo bá wí pé n kò ní dárúkọ rẹ̀ mọ́,
bẹ́ẹ̀ ni n kò ní sọ̀rọ̀ ní orúkọ rẹ̀ mọ́,
ọ̀rọ̀ rẹ a máa jó mi ninu bí iná,
a sì máa ro mí ninu egungun.
Mo gbìyànjú títí pé kí n pa á mọ́ra,
ṣugbọn kò ṣeéṣe.