1
JEREMAYA 19:15
Yoruba Bible
“OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, ‘N óo mú kí ibi tí mo ti kéde rẹ̀ dé bá ìlú yìí ati àwọn ìlú tí wọn yí i ká, nítorí wọ́n ti ṣe oríkunkun, wọn kò sì gbọ́ ọ̀rọ̀ mi.’ ”
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí JEREMAYA 19:15
2
JEREMAYA 19:5
Wọ́n kọ́ pẹpẹ oriṣa Baali, wọ́n sì ń fi àwọn ọmọkunrin wọn rú ẹbọ sísun sí i. N kò pàṣẹ fún wọn pé kí wọn máa ṣe bẹ́ẹ̀, n kò fún wọn ní irú ìlànà bẹ́ẹ̀; ohun tí ó jọ bẹ́ẹ̀ kò tilẹ̀ wá sí mi lọ́kàn.
Ṣàwárí JEREMAYA 19:5
3
JEREMAYA 19:4
Nítorí pé àwọn eniyan wọnyi ti kọ̀ mí sílẹ̀, wọ́n ti sọ ibí di aláìmọ́ pẹlu turari tí wọn ń sun sí àwọn oriṣa tí àwọn, ati àwọn baba wọn, ati àwọn ọba Juda kò mọ̀ rí. Wọ́n ti pa àwọn aláìṣẹ̀ sí gbogbo ibí yìí.
Ṣàwárí JEREMAYA 19:4
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò