JEREMAYA 19

19
Ìgò Amọ̀ Tí Ó Fọ́
1OLUWA ní kí n lọ ra ìgò amọ̀ kan, kí n mú díẹ̀ ninu àwọn àgbààgbà ìlú ati àwọn bíi mélòó kan ninu àwọn àgbà alufaa, 2kí n lọ sí ìsàlẹ̀ àfonífojì ọmọ Hinomu, lẹ́nu Ibodè Àpáàdì; kí n sì kéde ọ̀rọ̀ tí òun óo sọ fún mi níbẹ̀:#2A. Ọba 23:10; Jer 7:30-32; 32:34-35 3“Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA, ẹ̀yin ọba Juda ati ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Jerusalẹmu, OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní òun óo mú ibi kan wá sórí ilẹ̀ yìí, híhó ni etí gbogbo àwọn tí wọn bá gbọ́ nípa rẹ̀ yóo máa hó. 4Nítorí pé àwọn eniyan wọnyi ti kọ̀ mí sílẹ̀, wọ́n ti sọ ibí di aláìmọ́ pẹlu turari tí wọn ń sun sí àwọn oriṣa tí àwọn, ati àwọn baba wọn, ati àwọn ọba Juda kò mọ̀ rí. Wọ́n ti pa àwọn aláìṣẹ̀ sí gbogbo ibí yìí. 5Wọ́n kọ́ pẹpẹ oriṣa Baali, wọ́n sì ń fi àwọn ọmọkunrin wọn rú ẹbọ sísun sí i. N kò pàṣẹ fún wọn pé kí wọn máa ṣe bẹ́ẹ̀, n kò fún wọn ní irú ìlànà bẹ́ẹ̀; ohun tí ó jọ bẹ́ẹ̀ kò tilẹ̀ wá sí mi lọ́kàn.#Lef 18:12 6Nítorí náà, ọjọ́ ń bọ̀, tí a kò ní pe ibí yìí ní Tofeti tabi àfonífojì ọmọ Hinomu mọ́. Àfonífojì ìpànìyàn ni a óo máa pè é. 7N óo sọ ìmọ̀ àwọn ará Juda ati ti àwọn ará ìlú Jerusalẹmu di òfo, n óo jẹ́ kí àwọn ọ̀tá wọn ati àwọn tí wọn ń wá ẹ̀mí wọn fi idà pa wọ́n. N óo sì fi òkú wọn ṣe oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ati àwọn ẹranko. 8N óo sì sọ ìlú yìí di ohun ẹ̀rù ati àrípòṣé, ẹ̀rù ìlú náà yóo sì máa ba gbogbo ẹni tí ó bá kọjá níbẹ̀, wọn yóo máa pòṣé nítorí àjálù tí ó dé bá a. 9N óo mú kí wọn máa pa ọmọ wọn ọkunrin ati obinrin jẹ. Olukuluku yóo máa pa aládùúgbò rẹ̀ jẹ nítorí ìdààmú tí àwọn ọ̀tá wọn, ati àwọn tí ń wá ẹ̀mí wọn yóo kó bá wọn, nígbà tí ogun bá dótì wọ́n.”
10OLUWA ní lẹ́yìn náà kí n fọ́ ìgò amọ̀ náà ní ojú àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu mi, 11kí n sì sọ fún wọn pé, OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Bí ẹni fọ́ ìkòkò amọ̀ ni n óo ṣe fọ́ àwọn eniyan yìí ati ìlú yìí, kò sì ní ní àtúnṣe mọ́. Ní Tofeti ni wọn yóo máa sin òkú sí nígbà tí wọn kò bá rí ààyè sin òkú sí mọ́. 12Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe sí ìlú yìí ati àwọn tí wọn ń gbé ibẹ̀. Bíi Tofeti ni n óo ṣe ìlú náà; Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. 13Àwọn ilé Jerusalẹmu ati àwọn ààfin ọba Juda, gbogbo ilé tí wọn ń sun turari sí àwọn ogun ọ̀run lórí òrùlé wọn, tí wọn sì ti rú ẹbọ ohun mímu sí àwọn oriṣa mìíràn, gbogbo wọn ni yóo di aláìmọ́ bíi Tofeti.”
14Nígbà tí Jeremaya pada dé láti Tofeti, níbi tí OLUWA rán an lọ pé kí ó lọ sọ àsọtẹ́lẹ̀, ó dúró ní àgbàlá ilé OLUWA, ó sọ fún gbogbo àwọn tí wọ́n péjọ sibẹ pé, 15“OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, ‘N óo mú kí ibi tí mo ti kéde rẹ̀ dé bá ìlú yìí ati àwọn ìlú tí wọn yí i ká, nítorí wọ́n ti ṣe oríkunkun, wọn kò sì gbọ́ ọ̀rọ̀ mi.’ ”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

JEREMAYA 19: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀