Jer 20:8-9
Jer 20:8-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori lati igba ti mo ti sọ̀rọ, emi kigbe, mo ke, Iwa-agbara, ati iparun, nitori a sọ ọ̀rọ Oluwa di ohun ẹ̀gan ati itiju fun mi lojojumọ. Nitorina mo si wipe, emi kì yio mu ni ranti rẹ̀, emi kì yio si sọ ọ̀rọ li orukọ rẹ̀ mọ́. Ṣugbọn ọ̀rọ rẹ̀ mbẹ bi iná ti njó ninu mi ti a se mọ inu egungun mi, o si rẹ̀ mi lati pa a mọra, emi kò le ṣe e.
Jer 20:8-9 Yoruba Bible (YCE)
Gbogbo ìgbà tí mo bá ti sọ̀rọ̀, ni mò ń kígbe pé, “Ogun ati ìparun dé!” Nítorí náà, ọ̀rọ̀ OLUWA tí mò ń kéde sọ mí di ẹni yẹ̀yẹ́ tọ̀sán-tòru. Ṣugbọn nígbàkúùgbà tí mo bá wí pé n kò ní dárúkọ rẹ̀ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni n kò ní sọ̀rọ̀ ní orúkọ rẹ̀ mọ́, ọ̀rọ̀ rẹ a máa jó mi ninu bí iná, a sì máa ro mí ninu egungun. Mo gbìyànjú títí pé kí n pa á mọ́ra, ṣugbọn kò ṣeéṣe.
Jer 20:8-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbàkúgbà tí mo bá sọ̀rọ̀, èmi sì kígbe síta èmi á sọ nípa ipá àti ìparun. Nítorí náà, ọ̀rọ̀ OLúWA ti mú àbùkù àti ẹ̀gàn bá mi ni gbogbo ìgbà. Ṣùgbọ́n bí mo bá sọ pé, “Èmi kì yóò dárúkọ rẹ tàbí sọ nípa orúkọ rẹ̀ mọ́, ọ̀rọ̀ rẹ̀ ń bẹ bi iná tí ń jó nínú mi nínú egungun mi Agara dá mi ní inú mi nítòótọ́ èmi kò lè ṣe é.