JEREMAYA 14

14
Ọ̀gbẹlẹ̀ Ńlá
1Ọ̀rọ̀ tí OLUWA sọ fún Jeremaya nípa ọ̀gbẹlẹ̀ nìyí:
2“Juda ń ṣọ̀fọ̀,
àwọn ẹnubodè ìlú rẹ̀ wà ninu ìnira.
Àwọn eniyan inú rẹ̀ ń sọkún ní ilẹ̀ẹ́lẹ̀,
igbe àwọn ará Jerusalẹmu sì ta sókè.
3Àwọn ọlọ́lá ní ìlú rán àwọn iranṣẹ wọn lọ pọn omi,
àwọn iranṣẹ dé odò, wọn kò rí omi.
Wọ́n gbé ìkòkò omi wọn pada lófìfo,
ojú tì wọ́n, ìdààmú dé bá wọn,
wọ́n káwọ́ lérí.
4Nítorí ilẹ̀ tí ó gbẹ,
nítorí òjò tí kò rọ̀ ní ilẹ̀ náà,
ojú ti àwọn àgbẹ̀, wọ́n káwọ́ lérí.
5Àgbọ̀nrín inú igbó pàápàá já ọmọ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bí sílẹ̀,
nítorí kò sí koríko.
6Àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó dúró lórí òkè,
wọ́n ń mí hẹlẹhẹlẹ bí ajáko.
Ojú wọn rẹ̀wẹ̀sì, nítorí kò sí koríko.
7Àwọn eniyan mi ké pè mí wí pé,
‘Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ wa ń jẹ́rìí lòdì sí wa,
sibẹsibẹ, nítorí orúkọ rẹ, gbà wá.
Ọpọlọpọ ìgbà ni a ti pada lẹ́yìn rẹ,
a ti ṣẹ̀ ọ́.
8Ìwọ ìrètí Israẹli,
olùgbàlà rẹ̀ ní ìgbà ìṣòro.
Kí ló dé tí o óo fi dàbí àlejò ní ilẹ̀ náà?
Àní, bí èrò ọ̀nà, tí ó yà láti sùn mọ́jú?
9Kí ló dé tí o fi dàbí ẹni tí ìdààmú bá;
bí alágbára tí kò lè gbani là?
Bẹ́ẹ̀ ni o wà láàrin wa, OLUWA,
a sì ń fi orúkọ rẹ pè wá,
má fi wá sílẹ̀.’ ”
10OLUWA sọ nípa àwọn eniyan náà pé,
“Ó wù wọ́n láti máa ṣáko kiri,
wọn kò ṣọ́ ìrìn ẹsẹ̀ wọn;
nítorí náà wọn kì í ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ OLUWA,
nisinsinyii OLUWA yóo ranti àìdára wọn,
yóo sì jẹ wọ́n níyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”
11OLUWA sọ fún mi pé, “Má gbadura pé kí àwọn eniyan wọnyi wà ní alaafia. 12Wọn ìbáà gbààwẹ̀, n kò ní gbọ́ igbe wọn. Wọn ìbáà rú ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ, n kò ní tẹ́wọ́ gbà wọ́n. Idà, ati ebi, ati àjàkálẹ̀ àrùn, ni n óo fi pa wọ́n run.”
13Mo bá dáhùn pé, “Háà! OLUWA Ọlọrun, wò ó! Àwọn wolii ń sọ fún wọn pé, wọn kò ní fojú kan ogun, tabi ìyàn, ati pé, alaafia tòótọ́ ni o óo fún wọn ní ibí yìí.”
14OLUWA bá sọ fún mi pé, “Àsọtẹ́lẹ̀ irọ́ ni àwọn wolii ń sọ ní orúkọ mi, n kò rán wọn níṣẹ́, n kò fún wọn láṣẹ, n kò tilẹ̀ bá wọn sọ̀rọ̀. Ìran èké ni wọ́n ń rí; iṣẹ́ asán ni wọ́n ń wò. Ohun tí ó wà lọ́kàn wọn ni wọ́n ń sọ. 15Nítorí náà, ohun tí èmi OLUWA sọ ni pé, àwọn wolii tí n kò rán níṣẹ́, tí wọn ń jíṣẹ́ orúkọ mi, tí wọn ní èmi sọ pé ogun ati ìyàn kò ní wọ ilẹ̀ yìí, ogun ati ìyàn ni yóo pa àwọn gan-an run. 16Wọn óo gbé àwọn eniyan tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún sọ síta ní òkú ní ìgboro Jerusalẹmu, nígbà tí ìyàn ati ogun bá pa wọ́n tán. Kò ní sí ẹni tí yóo sin òkú wọn, ati ti àwọn iyawo wọn, ati ti àwọn ọmọ wọn lọkunrin ati lobinrin. N óo da ibi tí wọ́n ṣe lé wọn lórí.”
17OLUWA wí fun mi pé, “Sọ fún wọn pé,
‘Kí omijé máa ṣàn lójú mi tọ̀sán-tòru,
kí ó má dáwọ́ dúró,
nítorí ọgbẹ́ ńlá tí a fi tagbára tagbára ṣá eniyan mi.
18Bí mo bá jáde lọ sí ìgbèríko,
àwọn tí wọ́n fi idà pa ni wọ́n kún bẹ̀!
Bí mo bá sì wọ ààrin ìlú,
àwọn tí ìyàn di àìsàn sí lára ni wọ́n kún bẹ̀.
Nítorí àwọn wolii ati àwọn alufaa ń lọ káàkiri gbogbo ilẹ̀ náà,
wọn kò sì mọ ohun tí wọn ń ṣe.’ ”
Àwọn Eniyan náà Bẹ OLUWA
19OLUWA, ṣé o ti kọ Juda sílẹ̀ patapata ni?
Àbí Sioni ti di ohun ìríra lọ́kàn rẹ?
Kí ló dé tí o fi lù wá,
tóbẹ́ẹ̀ tí ọ̀rọ̀ tiwa kọjá ìwòsàn?
À ń retí alaafia, ṣugbọn ire kankan kò dé.
À ń retí àkókò ìwòsàn, ṣugbọn ìpayà ni a rí.
20OLUWA, a mọ ìwà burúkú wa,
ati ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wa,
nítorí a ti ṣẹ̀ ọ́.
21Má ta wá nù nítorí orúkọ rẹ,
má sì fi àbùkù kan ìtẹ́ rẹ tí ó lógo.
Ranti majẹmu tí o bá wa dá,
ranti, má sì ṣe dà á.
22Ninu gbogbo àwọn ọlọrun èké tí àwọn orílẹ̀-èdè ń sìn,
ǹjẹ́ ọ̀kan wà tí ó lè mú kí òjò rọ̀?
Àbí ojú ọ̀run ní ń fúnrarẹ̀ rọ ọ̀wààrà òjò?
OLUWA Ọlọrun wa, ṣebí ìwọ ni?
Ìwọ ni a gbẹ́kẹ̀lé,
nítorí ìwọ ni o ṣe gbogbo nǹkan wọnyi.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

JEREMAYA 14: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀