JEREMAYA 15

15
Ìparun Yóo Dé Bá Àwọn Ọmọ Juda
1OLUWA bá tún sọ fún mi pé, “Mose ati Samuẹli ìbáà wá dúró níwájú mi, ọkàn mi kò lè yọ́ sí àwọn eniyan wọnyi. Lé wọn kúrò níwájú mi, kí wọ́n máa lọ!#a Eks 32:11-14; Nọm 14:13-19; b Ais 7:5-9 2Bí wọ́n bá bi ọ́ pé níbo ni kí àwọn ó lọ, sọ fún wọn pé èmi OLUWA ní,#Ifi 13:10
‘Àwọn tí wọn yóo kú ikú àjàkálẹ̀ àrùn,
kì àjàkálẹ̀ àrùn pa wọ́n;
àwọn tí wọn yóo kú ikú ogun,
kí ogun pa wọ́n.
Àwọn tí wọn yóo kú ikú ìyàn,
kí ìyàn pa wọ́n;
àwọn tí wọn yóo lọ sí ìgbèkùn,
kí ogun kó wọn lọ.’
3Oríṣìí ìparun mẹrin ni n óo jẹ́ kí ó dé bá wọn: idà óo pa wọ́n, ajá óo fà wọ́n ya, àwọn ẹyẹ ati àwọn ẹranko óo jẹ wọ́n ní àjẹrun. 4N óo sọ wọ́n di ohun tí ó bani lẹ́rù fún gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé, nítorí ohun tí Manase, ọmọ Hesekaya, ọba Juda, ṣe ní Jerusalẹmu.”#2A. Ọba 21:1-16; 2Kron 33:1-9
5OLUWA ní,
“Ẹ̀yin ará Jerusalẹmu, ta ni yóo ṣàánú yín?
Ta ni yóo dárò yín?
Ta ni yóo ya ọ̀dọ̀ yín, láti bèèrè alaafia yín?
6Ẹ ti kọ̀ mí sílẹ̀,
ẹ sì ń pada lẹ́yìn mi; èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
Nítorí náà ni mo ṣe na ọwọ́ ibinu mi si yín,
tí mo sì pa yín run.
Mo ti mú sùúrù, ó ti sú mi.
7Mo ti fẹ́ wọn bí ẹni fẹ́ ọkà ní ibi ìpakà,
ní ẹnubodè ilẹ̀ náà.
Mo ti kó ọ̀fọ̀ bá wọn;
mo ti pa àwọn eniyan mi run,
nítorí wọn kò yipada kúrò ní ọ̀nà wọn.
8Mo ti mú kí opó pọ̀ láàrin wọn ju iyanrìn inú òkun lọ.
Mo mú kí apanirun gbógun ti àwọn ìyá àwọn ọdọmọkunrin ní ọ̀sán gangan.
Mo mú kí ìbẹ̀rù ati ìwárìrì já lù wọ́n láìròtẹ́lẹ̀.
9Ẹni tí ó bí ọmọ meje ṣe àárẹ̀, ó sì dákú,
oòrùn rẹ̀ wọ̀ lọ́sàn-án gangan.
Ìtìjú ati àbùkù bá a.
N óo jẹ́ kí ọ̀tá fi idà pa àwọn tí wọ́n kù ninu wọn.
Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
Jeremaya Ráhùn sí OLUWA
10Mo gbé! Ìyá mi, kí ló dé tí o bí mi, èmi tí mo di oníjà ati alárìíyànjiyàn láàrin gbogbo ìlú! N kò yá ẹnikẹ́ni lówó, bẹ́ẹ̀ n kò yáwó lọ́wọ́ ẹnìkan, sibẹsibẹ gbogbo wọn ni wọ́n ń ṣépè lé mi. 11Kí èpè wọn mọ́ mi, OLUWA, bí n kò bá sọ ọ̀rọ̀ wọn ní rere níwájú rẹ, bí n kò bá gbadura fún àwọn ọ̀tá mi ní àkókò ìyọnu ati ìdààmú wọn. 12Ǹjẹ́ ẹnìkan lè ṣẹ́ irin, pàápàá, irin ilẹ̀ àríwá tí wọn fi idẹ lú?
13OLUWA bá dáhùn pé, “Nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ, n óo fi ọrọ̀ ati ohun ìṣúra rẹ fún àwọn tí ń kó ìkógun ní gbogbo agbègbè rẹ, láìgba owó lọ́wọ́ wọn. 14N óo mú kí o sin àwọn ọ̀tá rẹ ní ilẹ̀ tí o kò dé rí. Mo ti fi ibinu dá iná kan, ó ti ràn, yóo máa jó ọ, kò sì ní kú laelae.” 15Mo bá dáhùn pé, “OLUWA, ṣebí ìwọ náà mọ̀? Ranti mi, kí o sì ràn mí lọ́wọ́. Gbẹ̀san mi lára àwọn tí wọn ń ṣe inúnibíni sí mi. Má mú mi kúrò nítorí ojú àánú rẹ. Ranti pé nítorí rẹ ni wọ́n ṣé ń fi mí ṣẹ̀sín. 16Nígbà tí mo rí ọ̀rọ̀ rẹ, mo fi ṣe oúnjẹ jẹ. Nǹkan ayọ̀ ni ọ̀rọ̀ rẹ jẹ́ fún mi, ó sì jẹ́ ìdùnnú ọkàn mi. Nítorí orúkọ rẹ ni a fi ń pè mí, OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun. 17N kò jókòó láàrin àwọn alárìíyá, bẹ́ẹ̀ ni n kò yọ̀. Mo dá jókòó nítorí àṣẹ rẹ, nítorí o ti fi ìrúnú kún ọkàn mi. 18Kí ló dé tí ìrora mi kò dáwọ́ dúró, tí ọgbẹ́ mi jinlẹ̀, tí ó kọ̀, tí kò san? Ṣé o fẹ́ dá mi lọ́kàn le lásán ni; bí ẹlẹ́tàn odò tíí gbẹ nígbà ẹ̀ẹ̀rùn?”
19Nítorí náà OLUWA ní, “Bí o bá yipada, n óo mú ọ pada sípò rẹ, o óo sì tún máa ṣe iranṣẹ mi. Bí o bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ ọ̀rọ̀ gidi, tí o dákẹ́ ìsọkúsọ, o óo tún pada di òjíṣẹ́ mi. Àwọn ni yóo pada tọ̀ ọ́ wá, o kò ní tọ̀ wọ́n lọ. 20N óo sọ ọ́ di odi alágbára tí a fi idẹ mọ, lọ́dọ̀ àwọn eniyan wọnyi. Wọn yóo gbógun tì ọ́, ṣugbọn wọn kò ní ṣẹgun rẹ, nítorí pé mo wà pẹlu rẹ láti gbà ọ́, ati láti yọ ọ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. 21N óo gbà ọ́ lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú, n óo sì rà ọ́ pada lọ́wọ́ àwọn ìkà, aláìláàánú eniyan.”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

JEREMAYA 15: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀