Nítòótọ́, ó ti gbé ìkáàánú wa lọ,
ó sì ti ru ìbànújẹ́ wa;
sibẹsibẹ a kà á sí ẹni tí a nà,
tí a sì jẹ níyà láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun.
Ṣugbọn wọ́n ṣá a lọ́gbẹ́ nítorí àìdára wa,
wọ́n pa á lára nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa;
ìyà tí wọ́n fi jẹ ẹ́ ni ó fún wa ní alaafia,
nínà tí a nà án ni ó mú wa lára dá.
Gbogbo wa ti ṣáko lọ bí aguntan,
olukuluku wa yà sí ọ̀nà tirẹ̀,
OLUWA sì ti kó ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo wa lé e lórí.
Wọ́n ni í lára, wọ́n pọ́n ọn lójú,
sibẹsibẹ kò lanu sọ̀rọ̀,
wọ́n fà á lọ bí ọ̀dọ́ aguntan tí wọn ń lọ pa,
ati bí aguntan tíí yadi níwájú àwọn tí ń rẹ́ irun rẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni kò lanu sọ̀rọ̀.
Wọ́n mú un lọ tipátipá,
lẹ́yìn tí wọ́n ti dá a lẹ́jọ́,
ta ni ninu ìran rẹ̀ tí ó ṣe akiyesi pé
wọ́n ti pa á run lórí ilẹ̀ alààyè,
ati pé nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan mi, ni wọ́n ṣe nà án?
Wọ́n tẹ́ ẹ sí ibojì, pẹlu àwọn eniyan burúkú,
wọ́n sì sin ín pẹlu ọlọ́rọ̀,
bẹ́ẹ̀ ni kò ṣe ẹnikẹ́ni níbi,
kò sì sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.
Sibẹsibẹ, ó wu OLUWA láti pa á lára,
ó sì fi í sinu ìbànújẹ́,
nígbà tí ó fi ara rẹ̀ rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;
yóo fojú rí ọmọ rẹ̀,
ọjọ́ rẹ̀ yóo sì gùn.
Ìfẹ́ OLUWA yóo ṣẹ lọ́wọ́ rẹ̀.
Yóo rí èrè àníyàn ọkàn rẹ̀,
yóo sì tẹ́ ẹ lọ́rùn;
nípa ìmọ̀ rẹ̀ ni iranṣẹ mi, olódodo,
yóo dá ọpọlọpọ eniyan láre,
yóo sì ru ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
Nítorí náà, n óo fún un ní ìpín,
láàrin àwọn eniyan ńlá,
yóo sì bá àwọn alágbára pín ìkógun,
nítorí pé ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún ikú,
wọ́n sì kà á mọ́ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.
Sibẹsibẹ ó ru ẹ̀ṣẹ̀ ọpọlọpọ eniyan,
ó sì bẹ̀bẹ̀ fún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.