AISAYA 53

53
1Ta ló lè gba ìyìn tí a rò gbọ́?#Rom 10:16; Joh 12:38
Ta ni a ti fi agbára OLUWA hàn?
2Ó dàgbà níwájú rẹ̀ bí nǹkan ọ̀gbìn tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ rúwé
ati bíi gbòǹgbò láti inú ilẹ̀ gbígbẹ.
Ìrísí rẹ̀ kò dára,
ojú rẹ̀ kò fanimọ́ra,
bẹ́ẹ̀ ni kò ní ẹwà tí ìbá fi wu eniyan.
3Àwọn eniyan kẹ́gàn rẹ̀,
wọ́n sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀;
ẹni tí inú rẹ̀ bàjẹ́ tí ó sì mọ ìkáàánú ni.
Ó dàbí ẹni tí àwọn eniyan ń wò ní àwòpajúdà.
A kẹ́gàn rẹ̀, a kò sì kà á kún.
4Nítòótọ́, ó ti gbé ìkáàánú wa lọ,#Mat 8:17
ó sì ti ru ìbànújẹ́ wa;
sibẹsibẹ a kà á sí ẹni tí a nà,
tí a sì jẹ níyà láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun.
5Ṣugbọn wọ́n ṣá a lọ́gbẹ́ nítorí àìdára wa,#1 Pet 2:24
wọ́n pa á lára nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa;
ìyà tí wọ́n fi jẹ ẹ́ ni ó fún wa ní alaafia,
nínà tí a nà án ni ó mú wa lára dá.
6Gbogbo wa ti ṣáko lọ bí aguntan,#1 Pet 2:25
olukuluku wa yà sí ọ̀nà tirẹ̀,
OLUWA sì ti kó ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo wa lé e lórí.
7Wọ́n ni í lára, wọ́n pọ́n ọn lójú,#Ifi 5:6
sibẹsibẹ kò lanu sọ̀rọ̀,
wọ́n fà á lọ bí ọ̀dọ́ aguntan tí wọn ń lọ pa,
ati bí aguntan tíí yadi níwájú àwọn tí ń rẹ́ irun rẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni kò lanu sọ̀rọ̀.
8Wọ́n mú un lọ tipátipá,#A. Apo 8:32-33
lẹ́yìn tí wọ́n ti dá a lẹ́jọ́,
ta ni ninu ìran rẹ̀ tí ó ṣe akiyesi pé
wọ́n ti pa á run lórí ilẹ̀ alààyè,
ati pé nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan mi, ni wọ́n ṣe nà án?
9Wọ́n tẹ́ ẹ sí ibojì, pẹlu àwọn eniyan burúkú,#1 Pet 2:22
wọ́n sì sin ín pẹlu ọlọ́rọ̀,
bẹ́ẹ̀ ni kò ṣe ẹnikẹ́ni níbi,
kò sì sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.
10Sibẹsibẹ, ó wu OLUWA láti pa á lára,
ó sì fi í sinu ìbànújẹ́,
nígbà tí ó fi ara rẹ̀ rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;
yóo fojú rí ọmọ rẹ̀,
ọjọ́ rẹ̀ yóo sì gùn.
Ìfẹ́ OLUWA yóo ṣẹ lọ́wọ́ rẹ̀.
11Yóo rí èrè àníyàn ọkàn rẹ̀,
yóo sì tẹ́ ẹ lọ́rùn;
nípa ìmọ̀ rẹ̀ ni iranṣẹ mi, olódodo,
yóo dá ọpọlọpọ eniyan láre,
yóo sì ru ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
12Nítorí náà, n óo fún un ní ìpín,#Mak 15:28; Luk 22:37
láàrin àwọn eniyan ńlá,
yóo sì bá àwọn alágbára pín ìkógun,
nítorí pé ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún ikú,
wọ́n sì kà á mọ́ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.
Sibẹsibẹ ó ru ẹ̀ṣẹ̀ ọpọlọpọ eniyan,
ó sì bẹ̀bẹ̀ fún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

AISAYA 53: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀