AISAYA 54

54
Ìfẹ́ OLUWA sí Israẹli
1Máa kọrin! Ìwọ àgàn tí kò bímọ.#Gal 4:27
Máa kọrin sókè, ìwọ tí kò rọbí rí.
Nítorí ọmọ ẹni tí ọkọ ṣátì pọ̀,
ju ọmọ ẹni tí ń gbé ilé ọkọ lọ,
OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.
2Fẹ ààyè àgọ́ rẹ sẹ́yìn,
sì jẹ́ kí aṣọ tí ó ta sórí ibùgbé rẹ gbòòrò sí i, má ṣẹ́wọ́ kù.
Na okùn àgọ́ rẹ kí ó gùn,
kí o sì kan èèkàn rẹ̀ mọ́lẹ̀ kí ó lágbára.
3Nítorí o óo tàn kálẹ̀, sí apá ọ̀tún ati apá òsì,
àwọn ọmọ rẹ yóo gba ìtẹ́ àwọn orílẹ̀-èdè,
wọn óo sì máa gbé àwọn ìlú tí ó ti di ahoro.
4Má bẹ̀rù nítorí ojú kò ní tì ọ́,
má sì dààmú, nítorí a kì yóo dójú tì ọ́,
nítorí o óo gbàgbé ìtìjú ìgbà èwe rẹ,
o kò sì ní ranti ẹ̀sín ìgbà tí o jẹ́ opó mọ́.
5Nítorí Ẹlẹ́dàá rẹ ni ọkọ rẹ,
OLUWA àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀.
Ẹni Mímọ́ Israẹli ni Olùràpadà rẹ,
Ọlọrun gbogbo ayé ni à ń pè é.
6Nítorí OLUWA ti pè ọ́,
bí iyawo tí ọkọ rẹ̀ kọ̀ sílẹ̀, tí ọkàn rẹ̀ bàjẹ́,
àní, bí iyawo àárọ̀ ẹni, tí a kọ̀ sílẹ̀;
OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.
7Mo kọ̀ ọ́ sílẹ̀ fún ìgbà díẹ̀,
ṣugbọn n óo kó ọ jọ pẹlu ọpọlọpọ àánú.
8Mo fojú mi pamọ́ fún ọ,
fún ìgbà díẹ̀ nítorí inú mi ń ru sí ọ,
ṣugbọn nítorí ìfẹ́ àìlópin mi, n óo ṣàánú fún ọ.
Èmi OLUWA, Olùràpadà rẹ ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
9Bí ìgbà ayé Noa ni Ọ̀rọ̀ yìí rí sí mi:#Jẹn 9:8-17
mo búra nígbà náà, pé omi Noa kò ní bo ayé mọ́lẹ̀ mọ́.
Bẹ́ẹ̀ náà ni mo búra nisinsinyii,
pé n kò ní bínú sí ọ mọ́,
pé n kò ní bá ọ wí mọ́.
10Bí àwọn òkè ńlá tilẹ̀ ṣí kúrò,#Jud 16:15
tí a sì ṣí àwọn òkè kéékèèké nídìí,
ṣugbọn ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀, kò ní yẹ̀ lára rẹ,
majẹmu alaafia mi tí mo bá ọ dá kò ní yẹ̀.
Èmi OLUWA tí mo ṣàánú fún ọ ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
Ọjọ́ Iwájú Jerusalẹmu
11OLUWA ní:
“Jerusalẹmu, ìwọ ẹni tí a pọ́n lójú, tí hílàhílo bá,#Tob 13:16-17
tí a kò sì tù ninu,
òkúta tí a fi oríṣìíríṣìí ọ̀dà kùn ni n óo fi kọ́ ọ,
òkúta safire ni n óo sì fi ṣe ìpìlẹ̀ rẹ.
12Òkúta Agate ni n óo fi ṣe ṣóńṣó ilé rẹ,#Ifi 21:18-21
òkúta dídán ni n óo fi ṣe ẹnu ọ̀nà ibodè rẹ,
àwọn òkúta olówó iyebíye ni n óo fi mọ odi rẹ.
13“Gbogbo àwọn ọmọ rẹ ọkunrin, ni OLUWA yóo kọ́#Joh 6:45
wọn yóo sì ṣe ọpọlọpọ àṣeyọrí.
14A óo fìdí rẹ múlẹ̀, ninu òdodo,
o óo jìnnà sí ìnira, nítorí náà ẹ̀rù kò ní bà ọ́.
O óo jìnnà sí ìpayà, nítorí kò ní súnmọ́ ọ.
15Bí ẹnìkan bá dojú ìjà kọ ọ́, kìí ṣe èmi ni mo rán an,
ẹnikẹ́ni tó bá gbéjà kò ọ́, yóo ṣubú nítorí rẹ.”
16OLUWA ní,
“Wò ó! Èmi ni mo dá alágbẹ̀dẹ,
tí ó fi ẹwìrì fẹ́ná,
tí ó sì rọ àwọn ohun ìjà, fún ìlò rẹ̀,
èmi náà ni mo dá apanirun,
pé kí ó máa panirun.
17Kò sí ohun ìjà tí a ṣe láti fi bá ọ jà
tí yóo lágbára lórí rẹ.
Gbogbo ẹni tí ó bá bá ọ rojọ́ nílé ẹjọ́,
ni o óo jàre wọn.
Èyí ni ìpín àwọn iranṣẹ OLUWA,
ati ìdáláre wọn lọ́dọ̀ mi.
Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

AISAYA 54: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa