Isa 53:4-12
Isa 53:4-12 Yoruba Bible (YCE)
Nítòótọ́, ó ti gbé ìkáàánú wa lọ, ó sì ti ru ìbànújẹ́ wa; sibẹsibẹ a kà á sí ẹni tí a nà, tí a sì jẹ níyà láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun. Ṣugbọn wọ́n ṣá a lọ́gbẹ́ nítorí àìdára wa, wọ́n pa á lára nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa; ìyà tí wọ́n fi jẹ ẹ́ ni ó fún wa ní alaafia, nínà tí a nà án ni ó mú wa lára dá. Gbogbo wa ti ṣáko lọ bí aguntan, olukuluku wa yà sí ọ̀nà tirẹ̀, OLUWA sì ti kó ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo wa lé e lórí. Wọ́n ni í lára, wọ́n pọ́n ọn lójú, sibẹsibẹ kò lanu sọ̀rọ̀, wọ́n fà á lọ bí ọ̀dọ́ aguntan tí wọn ń lọ pa, ati bí aguntan tíí yadi níwájú àwọn tí ń rẹ́ irun rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò lanu sọ̀rọ̀. Wọ́n mú un lọ tipátipá, lẹ́yìn tí wọ́n ti dá a lẹ́jọ́, ta ni ninu ìran rẹ̀ tí ó ṣe akiyesi pé wọ́n ti pa á run lórí ilẹ̀ alààyè, ati pé nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan mi, ni wọ́n ṣe nà án? Wọ́n tẹ́ ẹ sí ibojì, pẹlu àwọn eniyan burúkú, wọ́n sì sin ín pẹlu ọlọ́rọ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò ṣe ẹnikẹ́ni níbi, kò sì sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn. Sibẹsibẹ, ó wu OLUWA láti pa á lára, ó sì fi í sinu ìbànújẹ́, nígbà tí ó fi ara rẹ̀ rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀; yóo fojú rí ọmọ rẹ̀, ọjọ́ rẹ̀ yóo sì gùn. Ìfẹ́ OLUWA yóo ṣẹ lọ́wọ́ rẹ̀. Yóo rí èrè àníyàn ọkàn rẹ̀, yóo sì tẹ́ ẹ lọ́rùn; nípa ìmọ̀ rẹ̀ ni iranṣẹ mi, olódodo, yóo dá ọpọlọpọ eniyan láre, yóo sì ru ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Nítorí náà, n óo fún un ní ìpín, láàrin àwọn eniyan ńlá, yóo sì bá àwọn alágbára pín ìkógun, nítorí pé ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún ikú, wọ́n sì kà á mọ́ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀. Sibẹsibẹ ó ru ẹ̀ṣẹ̀ ọpọlọpọ eniyan, ó sì bẹ̀bẹ̀ fún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.
Isa 53:4-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
Lõtọ o ti ru ibinujẹ wa, o si gbe ikãnu wa lọ; ṣugbọn awa kà a si bi ẹniti a nà, ti a lù lati ọdọ Ọlọrun, ti a si pọ́n loju. Ṣugbọn a ṣá a li ọgbẹ nitori irekọja wa, a pa a li ara nitori aiṣedede wa; ìna alafia wa wà lara rẹ̀, ati nipa ìna rẹ̀ li a fi mu wa lara da. Gbogbo wa ti ṣina kirikiri bi agutan, olukuluku wa tẹ̀le ọ̀na ara rẹ̀; Oluwa si ti mu aiṣedede wa gbogbo pade lara rẹ̀. A jẹ ẹ ni iyà, a si pọ́n ọ loju, ṣugbọn on kò yà ẹnu rẹ̀: a mu u wá bi ọdọ-agutan fun pipa, ati bi agutan ti o yadi niwaju olurẹ́run rẹ̀, bẹ̃ni kò yà ẹnu rẹ̀. A mu u jade lati ibi ihamọ on idajọ: tani o si sọ iran rẹ̀? nitori a ti ke e kuro ni ilẹ alãye: nitori irekọja awọn enia mi li a ṣe lù u. O si ṣe ibojì rẹ̀ pẹlu awọn enia buburu, ati pẹlu ọlọrọ̀ ni ikú rẹ̀; nitori kò hù iwà-ipa, bẹ̃ni kò si arekereke li ẹnu rẹ̀. Ṣugbọn o wu Oluwa lati pa a lara; o ti fi i sinu ibanujẹ; nigbati iwọ o fi ẹmi rẹ̀ ṣẹbọ fun ẹ̀ṣẹ: yio ri iru-ọmọ rẹ̀, yio mu ọjọ rẹ̀ gùn, ifẹ Oluwa yio ṣẹ li ọwọ́ rẹ̀. Yio ri ninu eso lãlã ọkàn rẹ̀, yio si tẹ́ ẹ li ọrùn: nipa imọ̀ rẹ̀ ni iranṣẹ mi olododo yio da ọ̀pọlọpọ lare; nitori yio rù aiṣedede wọn wọnni. Nitorina emi o fun u ni ipín pẹlu awọn ẹni-nla, yio si ba awọn alagbara pín ikogun, nitori o ti tú ẹmi rẹ̀ jade si ikú: a si kà a mọ awọn alarekọja, o si rù ẹ̀ṣẹ ọ̀pọlọpọ; o si nṣipẹ̀ fun awọn alarekọja.
Isa 53:4-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lóòtítọ́ ó ti ru àìlera wa lọ ó sì ti ru ìbànújẹ́ wa pẹ̀lú, síbẹ̀ a kà á sí ẹni tí Ọlọ́run lù, tí ó lù, tí a sì pọ́n lójú. Ṣùgbọ́n a sá a lọ́gbẹ́ nítorí àìṣedéédéé wa a pa á lára nítorí àìṣòdodo wa; ìjìyà tí ó mú àlàáfíà wá fún wa wà lórí i rẹ̀, àti nípa ọgbẹ́ rẹ̀ ni a fi mú wa láradá. Gbogbo wa bí àgùntàn, ti ṣìnà lọ, ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ti yà sí ọ̀nà ara rẹ̀; OLúWA sì ti gbé e ka orí ara rẹ̀ gbogbo àìṣedéédéé wa. A jẹ ẹ́ ní yà, a sì pọ́n ọn lójú, síbẹ̀ kò ya ẹnu rẹ̀; a mú un wá gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́-àgùntàn sọ́dọ̀ alápatà, àti gẹ́gẹ́ bí àgùntàn tí ó dákẹ́ níwájú olùrẹ́run rẹ̀, síbẹ̀ kò ya ẹnu rẹ̀. Pẹ̀lú ìpọ́nlójú àti ìdánilẹ́jọ́ ni a mú un jáde lọ, ta ni ó sì le sọ nípa ìrànlọ́wọ́ rẹ̀? Nítorí a ké e kúrò ní ilẹ̀ àwọn alààyè; nítorí àìṣedéédéé àwọn ènìyàn mi ni a ṣe lù ú. A fún un ní ibojì pẹ̀lú àwọn ìkà, àti pẹ̀lú àwọn ọlọ́rọ̀ ní ikú rẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò hùwà jàgídíjàgan kan, tàbí kí a rí ẹ̀tàn kan ní ẹnu rẹ̀. Síbẹ̀, ó wu OLúWA láti pa á lára àti láti mú kí ó jìyà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé OLúWA fi ayé rẹ̀ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, Òun yóò rí àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ àti ọjọ́ ayé rẹ̀ yóò pẹ́ títí, àti ète OLúWA ni yóò gbèrú ní ọwọ́ rẹ̀. Lẹ́yìn ìpọ́njú ẹ̀mí rẹ̀, òun yóò rí ìmọ́lẹ̀, ààyè yóò sì tẹ́ ẹ lọ́rùn; nípa ìmọ̀ rẹ̀ ìránṣẹ́ mi olódodo yóò dá ọ̀pọ̀lọpọ̀ láre, Òun ni yóò sì ru àìṣedéédéé wọn. Nítorí náà èmi yóò fún un ní ìpín pẹ̀lú àwọn ẹni ńlá òun yóò sì pín ìkógun pẹ̀lú àwọn alágbára, nítorí pé òun jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ fún ikú, tí a sì kà á mọ́ àwọn alárékọjá. Nítorí ó ru ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀, ó sì ṣe ìlàjà fún àwọn alárékọjá.