AISAYA 26:1-11

AISAYA 26:1-11 YCE

Ní àkókò náà, orin tí wọn óo máa kọ ní ilẹ̀ Juda ni pé: “A ní ìlú tí ó lágbára, ó fi ìgbàlà ṣe odi ati ibi ààbò. Ẹ ṣí ìlẹ̀kùn ibodè, kí orílẹ̀-èdè olódodo, tí ń ṣe òtítọ́ lè wọlé. O óo pa àwọn tí wọ́n gbé ọkàn wọn lé ọ mọ́ ní alaafia pípé, nítorí pé wọ́n gbẹ́kẹ̀lé ọ. Gbẹ́kẹ̀lé OLUWA títí lae, nítorí àpáta ayérayé ni OLUWA Ọlọrun. Ó sọ àwọn tí ń gbé orí òkè kalẹ̀, ó sọ ìlú tí ó wà ní orí òkè téńté di ilẹ̀, ó sọ ọ́ di ilẹ̀ patapata, ó fà á sọ sinu eruku. Wọ́n ń tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀, bí àwọn òtòṣì tí ń tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni àwọn aláìní ń tẹ̀ ẹ́.” Ọ̀nà títẹ́jú ni ọ̀nà àwọn olódodo ó mú kí ọ̀nà àwọn olódodo máa dán. Àwa dúró dè ọ́ ní ọ̀nà ìdájọ́ rẹ, OLUWA, orúkọ rẹ ati ìrántí rẹ ni ọkàn wa ń fẹ́. Ọkàn mi ń ṣe àfẹ́rí rẹ lálẹ́, mo sì ń fi tọkàntọkàn wá ọ nítorí nígbà tí ìlànà rẹ bá wà láyé ni àwọn ọmọ aráyé yóo kọ́ òdodo. Bí a bá ṣàánú ẹni ibi, kò ní kọ́ láti ṣe rere. Yóo máa ṣe ibi ní ilẹ̀ àwọn olódodo, kò sì ní rí ọlá ńlá OLUWA. OLUWA o ti gbé ọwọ́ rẹ sókè láti jẹ àwọn ọ̀tá níyà, ṣugbọn wọn kò rí i. Jẹ́ kí wọn rí i pé ọ̀rọ̀ àwọn eniyan rẹ jẹ ọ́ lógún, kí ojú sì tì wọ́n. Jẹ́ kí iná tí o dá fún àwọn ọ̀tá rẹ jó wọn run.