AISAYA 26

26
Orin Ìgbàlà
1Ní àkókò náà,
orin tí wọn óo máa kọ ní ilẹ̀ Juda ni pé:
“A ní ìlú tí ó lágbára,
ó fi ìgbàlà ṣe odi ati ibi ààbò.
2Ẹ ṣí ìlẹ̀kùn ibodè,
kí orílẹ̀-èdè olódodo, tí ń ṣe òtítọ́ lè wọlé.
3O óo pa àwọn tí wọ́n gbé ọkàn wọn lé ọ mọ́ ní alaafia pípé,
nítorí pé wọ́n gbẹ́kẹ̀lé ọ.
4Gbẹ́kẹ̀lé OLUWA títí lae,
nítorí àpáta ayérayé ni OLUWA Ọlọrun.
5Ó sọ àwọn tí ń gbé orí òkè kalẹ̀,
ó sọ ìlú tí ó wà ní orí òkè téńté di ilẹ̀,
ó sọ ọ́ di ilẹ̀ patapata,
ó fà á sọ sinu eruku.
6Wọ́n ń tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀,
bí àwọn òtòṣì tí ń tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀
bẹ́ẹ̀ ni àwọn aláìní ń tẹ̀ ẹ́.”
7Ọ̀nà títẹ́jú ni ọ̀nà àwọn olódodo
ó mú kí ọ̀nà àwọn olódodo máa dán.
8Àwa dúró dè ọ́ ní ọ̀nà ìdájọ́ rẹ, OLUWA,
orúkọ rẹ ati ìrántí rẹ ni ọkàn wa ń fẹ́.
9Ọkàn mi ń ṣe àfẹ́rí rẹ lálẹ́,
mo sì ń fi tọkàntọkàn wá ọ
nítorí nígbà tí ìlànà rẹ bá wà láyé
ni àwọn ọmọ aráyé yóo kọ́ òdodo.
10Bí a bá ṣàánú ẹni ibi,
kò ní kọ́ láti ṣe rere.
Yóo máa ṣe ibi ní ilẹ̀ àwọn olódodo,
kò sì ní rí ọlá ńlá OLUWA.
11OLUWA o ti gbé ọwọ́ rẹ sókè láti jẹ àwọn ọ̀tá níyà,#Heb 10:27
ṣugbọn wọn kò rí i.
Jẹ́ kí wọn rí i pé
ọ̀rọ̀ àwọn eniyan rẹ jẹ ọ́ lógún,
kí ojú sì tì wọ́n.
Jẹ́ kí iná tí o dá fún àwọn ọ̀tá rẹ jó wọn run.
12OLUWA ìwọ yóo fún wa ní alaafia,
nítorí pé ìwọ ni o ṣe gbogbo iṣẹ́ wa fún wa.
13OLUWA, Ọlọrun wa,
àwọn oluwa mìíràn ti jọba lórí wa
ṣugbọn orúkọ rẹ nìkan ni àwa mọ̀.
14Wọ́n ti kú, wọn kò ní wà láàyè mọ́,
ẹ̀mí wọn kò ní dìde mọ́ ní isà òkú.
Nítorí bẹ́ẹ̀ ni o ṣe jẹ wọ́n níyà,
o sì pa wọ́n run,
o sì ti sọ gbogbo ìrántí wọn di ohun ìgbàgbé.
15Ṣugbọn ìwọ OLUWA ti mú kí orílẹ̀-èdè náà pọ̀ sí i,
OLUWA, o ti bukun orílẹ̀-èdè náà,
gbogbo ààlà ilẹ̀ náà ni o ti bì sẹ́yìn,
o sì ti buyì kún ara rẹ.
16OLUWA nígbà tí wọ́n wà ninu ìpọ́njú, wọ́n wá ọ,
wọ́n fọkàn gbadura nígbà tí o jẹ wọ́n ní ìyà.
17Bí aboyún tí ó fẹ́ bímọ,
tí ó ń yí, tí ó sì ń ké ìrora,
nígbà tí àkókò àtibímọ rẹ̀ súnmọ́ tòsí
bẹ́ẹ̀ ni a rí nítorí rẹ, OLUWA.
18A wà ninu oyún, ara ń ro wá,
a ní kí a bí, òfo ló jáde.
A kò ṣẹgun ohunkohun láyé
bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí ń gbé ayé kò tíì ṣubú.
19Àwọn òkú wa yóo jí,
wọn óo dìde kúrò ninu ibojì.
Ẹ tají kí ẹ máa kọrin,
ẹ̀yin tí ó sùn ninu erùpẹ̀.
Nítorí pé ìrì ìmọ́lẹ̀ ni ìrì yín,
ẹ óo sì sẹ ìrì náà sì ilẹ̀ àwọn òkú.
Ìdájọ́ ati Ìmúpadàbọ̀sípò
20Ẹ gbéra nílẹ̀, ẹ̀yin eniyan mi,
ẹ wọ inú yàrá yín,
kí ẹ sì ti ìlẹ̀kùn mọ́rí;
ẹ farapamọ́ fún ìgbà díẹ̀,
títí tí ibinu OLUWA yóo fi kọjá.
21OLUWA óo yọ láti ibùgbé rẹ̀,
láti fi ìyà jẹ àwọn tí ń gbé inú ayé, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn,
ilẹ̀ yóo tú ẹ̀jẹ̀ àwọn tí wọ́n pa sórí rẹ̀ jáde,
kò sì ní bo àwọn tí a pa mọ́lẹ̀ mọ́.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

AISAYA 26: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀